Ìgbẹ́jọ́ Donald Trump bẹ̀rẹ̀ ní Tuesday àmọ́ wọn kò ní fi ṣẹkẹ́-ṣẹkẹ̀ sọ́wọ́ rẹ̀ - Amòfin

Trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

Igbẹjọ aarẹ ana nilẹ Amẹrika, Donald Trump, yoo bẹrẹ lọsan ọjọ Isẹgun,

Donald Trump nireti wa wi pe yoo de silu Florida lọ́jọ́ Aje, ninu ọkọ ofurufu aladani rẹ, ti yoo si fa ara rẹ le awon ọlọpaa lọwọ.

Wọn ti fẹsun kan Donald Trump wi pe o san ẹgbẹrun marunlelọgọrun Dọla ($105,000) fun olowo nabi kan, stormy Daniels.

Igbẹjo Donald Trump lo seese ki ọpọ awọn osiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ni Amẹrika jẹri si.

igbejọ naa ni yoo bẹrẹ laago meji kọja isẹju mẹẹdogun ọsan, ti wọn ko si ni fi sẹkẹ-sẹkẹ si ọwọ mejeeji aarẹ tẹlẹri naa lasiko igbẹjọ naa.

A di ọna to wọ yara igbẹjọ tori o seese kawọn eeyan kan fẹ kọlu Trump lasiko igbẹjọ - Awọn agbofinro

Agbẹjọrọ Donald Trump, Joe Tacopina ni awọn to fẹsun kan onibara oun fẹ fi se ẹlẹya ni gbangba ni.

Sugbon o ni awọn osisẹ ajọ alaabo ti fi da oun loju wi pe awọn yoo di awọn ọna to dari si yara igbẹjọ naa nitori o seeṣe ki awọn kan fẹ se ikolu si Donald Trump lasiko igbẹjọ rẹ.

Awọn ẹsọ alabo lo ti wa ni ayika ibiti igbẹjọ naa yo ti bẹrẹ lati ọjọ eti ni igbari fun ikọlu to seṣe ko waye.

Aarẹ tẹlẹri naa lo yẹ ki o ti jọwọ ara rẹ fun ile isẹ ọlọpaa lati ọjọ ẹti,sugbọn nitori aisi eto aabo to daju wọn sun si ọjọ ajẹ ọsẹ to n bọ.

Donald Trump lo ti ni oun ko jẹbi ẹsun yti wọn fi kan oun,nitori wi pe titi di isin kọ ti si atri daju iye ẹsun ti wọn ka si Donald Trump lẹsẹ.

Aarẹ tẹlẹri na ni ounti bu ẹnuatẹ lu awọn adajọ ti o fẹ gba ẹjọ daa ti agbẹnusọ ile asoju sofin Kevin McCarthy ni idun koko naa ko sẹyin ilakaka wọn lati da Donald Trump lọwọkọ lati dije dupo aarẹ Amẹrika.

Oloselu kan Marjorie lo ti jẹjẹ lati wa nibi igbẹjọ naa to si pe awọn ololufẹ Donald Trump lati se iwọde tako ẹsun ti wọn fi kan aarẹ tẹlẹ oun.

Agbẹjọrọ agba fun agbegbe Manhattan Alvin Bragg ni irọ ni wi pe wọn fẹ fi ọna ofin di aarẹ Donald Trump lati mase dije dupo aarẹ,nitori awọn ara ilu lo fẹsun kan Donald Trump awọn si gbọdọ se idajọ to tọ.

Kí ló pa Donald Trump àti Aṣẹ́wó pọ, tó fi di ọ̀rọ̀ iléẹjọ́?

Aworan Donald Trump ati Stormy Dainels

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Amẹrika, Donald Trump ni wọn ti fẹsun kan lori bi o ṣe fi owo bo asẹwo kan, Stormy Daniels lẹnu.

Arabinrin Daniels fẹsun kan Trump pe awọn mejeeji jọ ni ibalopọ, to si gba owo toto ẹgbẹrun lọna aadoje owo dọla lati ọwọ agbẹjọro Trump tẹlẹ, saaju eto idibo ọdun 2016 lati fi ẹnu mẹnu lori ajọsepọ wọn.

Agbẹjọro naa, Micheal Cohen, lo pada lọ si ẹwọn lori orisirisi ẹsun ti wọn fi kan.

Bakan, Trump ti ni irọ to jinna si ootọ ni iroyin naa pe oun ni ibalopọ kankan pẹlu Daniels lati igba ti ọrọ naa ti jade lọdun 2018.

Stormy Daniels pariwo sita lori ibalopọ pẹlu Trump

Arabinrin Daniels, ẹni ti orukọ rẹ n jẹ Stephanie Clifford, sọ ninu awọn ifọrọwerọ to se pe oun pade Trump ni bi idije ere idaraya Golf lọdun 2006.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, o ni awọn ni ibalopọ ni ile itura Trump ni Lake Tahoe, to wa ni agbegbe kan Calfornia ati Nevada.

Ọpọ igba ni agbẹjọrọ Trump ni irọ to jina sootọ ni ẹsun ti wọn fi kan Trump.

"Ko se bi ẹni pe ọrọ naa ta ba a rara, agidi rẹ ti pọju."

Daniels sọ eleyi nigba ti akọroyin n bi leere pe boya ni Trump sọ fun pe ko dakẹ lori ọrọ ibalopọ to waye laarin wọn.

Iyawo Trump, Melania Trump, ko si nibi idije naa ati pe o sẹsẹ bi ọmọ lasiko naa ni.

Idunkoko ati sisan owo gba ko dakẹ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọdun 2016 saaju eto idibo aarẹ orilẹede Amẹrika, Arabinrin Dainels ni agbẹjọro Trump, Micheal Cohen san owo toto ẹgbẹrun lọna aadoje owo dọla fun ati dakẹ lori ibasepọ to wa laarin oun ati Trump.

O ni oun gba owo naa nitori aba awọn mọlẹbi rẹ.

Arabinrin Dainels ni wọn dunkoko mọ oun ni ti ara ati ofin pe a fi ki oun dakẹ.

Lọdun 2011, lẹyin to gba lati sọrọ ninu iwe iroyin, Touch Magazine lori ibasepọ naa, O ni ọkunrin kan ti oun ko mọ wa ba oun ati ọmọ rẹ obinrin ni Las Vegas , to si sọ fun pe ki oun fi Trump silẹ

"Ọmọbinrin arẹwa kekere yẹn. Ohun itiju lo jẹ ti nnkan ba sẹlẹ si iya rẹ." O ni oun ranti esi ti oun fọ si ọmọkunrin naa.

Ifọrọwerọ naa ni Touch ko gbe jade tan di ọdun 2018.

Saaju ti ifọrọwerọ ọgọta isẹju naa to jade, ileeṣẹ shell kan to dabi pr Cohen no ni dunkoko mọ Arabinrin Dainels lati pe lẹjọ lori pẹlu owow toto ogun milọnu dọla, nitori pe o ti tapa si iwe ahehun to buwọlu pe ko ni wi ohunkoko sita.

Arabinrin Dainels sọ fun CBS pe ẹru n ba oun pe wọn le pe oun lẹjọ lori bi o ṣe sọrọ sita lori tẹfisan sugbọn "o ṣe koko fun mi lati le da bobo ara mi".

Àkọlé fídíò, Stormy Daniels: 'I was threatened'

N jẹ o tọna lati san owo gba ko dakẹ?

Ko si nnkan to buru pe ki eeyan san gbo ko dakẹ fun eeyan.

Sugbọn bi o ti jẹ pe wọn san owo naa ni oku oṣu kan si eto idibo, awọn alatako Trump ni owo naa tapa si ofin iponlogo eto idibo.

Ninu oṣu kẹjọ ni ọdun 2018, Cohen jẹ bi ẹsun pe ko san owo ori eyi to ni ibasepọ pẹlu owo to san fun Arabinrin Dainels ati ẹlomiiran lara awọn ololufẹ Trump.

Cohen ti kọkọ ni Trump ko ni nnkan se pẹlu sisan awọn owo naa sugbọn o pada jade sọrọ pe Trump lo fun oun lasẹ lati san owo gba ko dakẹ aadoje milọnu dọla saaju eto idibo lọdun 1026.

Bakan naa ni Trump naa ni oun ni oun pa asẹ naa sugbọn oun ko ni ibasepọ kan pẹlu obinrin kankan ati sisẹ sofin ipolongo ibo.

Cohen ri ẹwọn he lẹyin ti ileẹjọ ni o jẹbi ẹsun pe o tapa sofin lasiko eto idibo aarẹ lọdun 2016.

Ki lo de ti ọrọ fi kan Trump?

Saaju lọdun 2023, ileeṣẹ ajafẹtọ New York District Attorney ti Alvin Bragg gbe igbimọ kan kalẹ lati se iwadi boya ọpọlọpọ ẹri wa lati fi pẹ aarẹ tẹlẹ naa lẹjọ lori owo to san fun Arabinrin Dainels.

Lọjọbọ, Igbimọ naa dibo pe ki wọn gbe awọn ẹsun ti wọn kian Trump jade, eyi lo sọ Trump di aarẹ Amẹrika akọkọ ti yoo koju wọn.

Lori ẹrọ ayelujara Trump, o pe iwadi naa ni igbimọ awọn oloselu to jẹ ajẹ ti wọn fẹ fi fa walẹ.