“Mi ò fìgbà kankan di ẹrù ìdílé mi ru Ijoba Lande, ó wù ú ló fẹ́ mi pẹ̀lú ọmọ méjì”

Aworan ijobalande ati iyawo re

Oríṣun àwòrán, Others

Iyawo oṣere tiata to tun jẹ adẹrinpooṣonu, Ganiyu Kehinde, ti ọpọ eeyan mo si Ijoba Lande lo ti ni oun ko figba kankan wu iwa buruku si ọkọ oun.

Ṣaaju ni obinrin ọhun ke gbajare sita lori ayelujara pe ọkọ oun ti di awati, ti ko si mu fọnu rẹ kuro nile.

Nigba ti oun sọrọ lori awuyewuye to n lọ lori bi o ti ko ọmọ mẹta wa sile ọkọ rẹ, iyawo adẹrinpooṣonu naa ni irọ ni ahesọ ọrọ naa.

Oni ṣaaju igbeyawo ni Ijọba Lamde ti mọ wi pe oun ni ọmọ meji tẹlẹri.

Yatọ si mẹta ti awọn iwe iroyin kan gbe jade, o tesiwaju lati sọpe oun ko fi gbakankan di ẹru idile oun ru ọkọ oun, Ijọba Lande.

O ni “ọmọ meji pere ni mo bi ṣaaju ki emi ati Ijọba Lamde to ṣe igbeyawo.”

“Ọkọ mi si mọ awọn ọmọ mejeji ti mo bi tẹleri ti wọn wa lọdọ iya mi, ko si eyi ti o ba emi ati ọkọ mi gbe, mi o figba kankan fi di ajaga awọn ọmọ mi ru ọkọ mi ri.”

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Àsọtẹ́lẹ̀ kan ní máà jẹ gbèsè tí yóò gbẹ̀mí mi àmọ́ ń kò gbàgbọ́ - Ijoba Lande

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Adẹrinpoṣonu ati oṣere, Ganiyu Kehinde, ti ọpọ mọ si Ijoba Lande ti sọ fun BBC lẹkunrẹrẹ idi ti oun fi gbe igbeṣẹ lati gbẹmi ara oun.

Ọjọ marun un ni wọn fi n wa Lande kiri lai mọ ibi to wa, ko to dipe wọn ri ni lọjọbọ.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, Ijoba Lande ni owo ti oun ya naa ni gbogbo igbiyanju oun lati san owo naa pada, ja si pabo.

Ijoba Lande ni titi di asiko yii, ni oun ṣi n san gbese naa, ti ko si si ọna abayọ miran lati san owo naa pada.

‘’Bii oṣu kẹwaa, ọdun 2022 ni iṣoro gbese naa ti bẹrẹ’’

Ninu ifọrọwerọ rẹ naa, Lande tẹsiwaju pe "Isoro akọkọ to ba mi ni pe Facebook to ma n san owo fun mi tẹlẹ, ti mo ba ti fi fidio lede, kọ lati san owo fun mi mọ.’’

Ọna ti owo n gba wọle fun mi bẹrẹ si ni di, eleyii to fa ibi ti iṣoro ti bẹrẹ si mi.

Bakan naa ni mọto ayọkẹlẹ mi bẹrẹ si ni yọnu, ti o si di agbana fun mi.

Amọ ṣaaju ni awọn pasitọ ti sọ fun awọn eniyan to sun mọ mi pe gbese nbọ lọrun mi, ti yoo si fẹrẹ gbẹmi mi

Mo ni pe rara, kii ṣe emi ni iru rẹ yoo ṣẹlẹ si amọ iyalẹnu lo jẹ nigba ti mo bẹrẹ si ni jẹ gbese.’’

‘’Awada ori ayelujara ni mo fi owo ‘Gbọ́múléláńtà’ se, amọ Editor kọ lati gbe fidio mi jade’’

Lande tẹsiwaju pe "nigba ti oun ya owoya naa, oun fi ya fidio ti oun fẹ maa fi si oju opo Youtube oun ni, ki wọn ba le maa ṣan owo fun oun.

‘’Amọ fidio Editor n fi oni da oni, ọla da ọla ni, ti ko si fun mi’’

‘’Owoya naa si n le si, ti mi o si fẹ ki wọn maa kede orukọ mi lori ẹrọ ayelujara.’’

‘’Ki eyi maa ba waye, mo bẹrẹ ni ta awọn nkan ini mi, to fi mọ ọkọ mi, mo bẹrẹ si ni ya owo lọwọ iyawo mi, amọ gbese ọhun ko tan.’’

‘’Ara ogun ti wọn n sọ naa niyẹn, ohun ti mo ti fi owo se ko yọri si rere, mo wa bẹrẹ si ni ta gbogbo nkan, to fi mọ mọto mi.’’

Ijoba Lande ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Ijoba Lande/Instagram

‘’Kii se iyawo mi to gbe ọmọ meji wa fẹ mi, lo fa isoro fun mi’’

nigba to n sẹ lori ọrọ kan to n ja ranin kiri ori ayelujara pe iyawo rẹ lo n di ọpọ bukata le lori, ti ko fi ri se, Lande ni irọ to jinna sootọ ni ọrọ naa.

Lande ni ko jẹ tuntun si oun pe iyawo oun ni ọmọ meji nitori oun mọ nipa wọn ki oun to fẹ ẹ.

Bakan naa lo ni oun naa bi ọmọ kan sita, ti iyawo oun ko si fun oun ni wahala.

‘’Emi ati iyawo mi ko ja, lootọ ni mo mọ pe iyawo mi ti bi ọmọ meji ko to fẹ mi, ti emi naa si ti bi ọmọ kan.

‘’Wọn ma n wa si ọdọ mi ni opin osẹ, wọn a si pada si ile wọn ni ọdọ iya rẹ, to fi mọ igba isinmi naa.’’

‘’Ipinnu mi lọjọ ti mo kuro ni ile ni lati lọ bẹ si odo, ki n pa ara mi nitori aye ti sun mi’’

Ijoba Lande tun salaye idi to se kuro nile fun BBC Yoruba ati ohun ti oju rẹ ri lasiko to di awati naa.

‘’Mo kuro nile lalẹ Sunday, mo fẹ bẹ sinu odo ni agbegbe Igando ti mo lọ amọ n ko le se bẹẹ tori awọn eniyan mọ mi ni agbegbe naa ni.’’

‘’Igba ti mo lọ si ibi omi naa, awọn eniyan wa nibẹ, ti mo si fi ara pamọ.’’

‘’Mo bẹ sinu omi ni, amọ mi o mọ bi wọn ṣe doola ẹmi mi.’’

‘’Awọn OPC ni awọn ni awọn ri mi, bi mo se bọ si omi, o dabi ẹni pe enikan wa ni ihoho to gbe mi kuro ninu omi, ti mo si fa awọtẹlẹ rẹ.’’

‘’Ibanujẹ to ba mi ni pe ibi ti mo ti wọ mọto de, mo tun wa n fi ẹṣẹ rin lọ si ibẹ.’’

Ijoba Lande wa n dupe lọwọ Ọlọrun pe o da ẹmi rẹ si, ti ko si ba isẹlẹ naa lọ

‘’Mi o mọ pe ọjọ marun un ni mo ti lo lai wa si ile.’’

Bakan naa lo fikun un pe oun ti lọ gba itọju, ti wọn eniyan si ti ṣaajo oun naa.

‘’Ọlọrun mọ pe mo si ni nkan ti mo fẹ ṣe ni aye, lo ṣe da mi si, mo dupẹ pe mo wa laaye.’’

‘’Ibanujẹ to ba mi ni pe ibi ti mo ti wọ mọto de, mo tun wa n fi ẹṣẹ rin lọ si ibẹ.’’

‘’Ọna ti awọn eniyan ba ni ki wọn fi ran mi lọwọ, paapaa ninu adura.’’