Ariwo sọ bí Foluke Daramola àti Yẹni Kuti, ọmọ Fela ṣe tahùn síra wọn

Oríṣun àwòrán, Instagram/Yeniakuti/FolukeDaramola
Saaju ọsẹ yii ni gbajugbaja oṣere tiata, Foluke Daramola bọ sori opo ayelujara rẹ lati se ikilọ fun awọn kan ti wọn kundun lati maa sọrọ odi si awọn agbalagba lori ayelujara nitori pe wọn kọ lati tẹle oloselu kan tabi omiran.
Folukẹ ni oun gẹgẹ bi ẹnikan, ko ni fi aye silẹ fun ọdọ kankan lati sọrọ odi si oun lori ayelujara.
O wa kesi awọn ọdọ naa lati yago fun sisọ ọrọ arifin lori opo ayelujara rẹ.
Bakan naa ni gbajumọ osere tiata yii tun tẹsiwaju pe sisọ ede abuku tako ise ati asa Yoruba eyi tawọn ọdọ naa gbọdọ yago fun tori o le se ọpọlọpọ akoba fun ọjọ ọla wọn.
Ọrọ ti Foluke Daramola sọ loju opo rẹ ree, ti ina ogun ọdun fi jo o lọwọ
"Ti a ko ba kiyesi, awọn ọdọ wọnyi yoo maa na awọn obi wọn.
"A ti sọ apọnle wa nu nitori awọn ọmọ ko fi ọwọ fun agba mọ nitori ọlaju.
"Anu awọn ọdọ yii se mi, tori pe a tẹlẹ oloselu tabi ẹlomiran, nibo ni apọnle wa wa, bawo ni a se de ibi ti wa yii?
"Mo bẹyin ni, ẹ ja ka pọn ara wa le o, n ko ni fi aye silẹ fun iwa radarada yẹn loju opo mi.
"Sugbọn mo n wa ẹnikan ti yoo wa soju opo mi lati wa wi radarada, ki n le fi jofin."
Ninu fidio isalẹ yii ni Foluke Daramola ti sọrọ loju opo Instagram rẹ, ẹ tẹ ẹ lati wo o.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Atubọtan lo ba Foluke Daramola, o ti bu emi asiwaju rẹ lọgbọn ọdun sẹyin - Yeni Kuti fèsì
Sugbọn gbogbo imọran ti Foluke Daramola gba awọn ọdọ naa ni ko dun mọ gbajugbaja Yeni Kuti, tii se ọmọ Fela Kut ninu.
Yeni wa sapejuwe abuku ti Foluke Daramola ni awọn ọdọ n fun oun lori ayelujara gẹgẹ bi ẹsan ati atubọtan.
Yeni Kuti, nigba to n kopa ninu ifọrọwerọ kan lori tẹlifisan, salaye pe, ni nnkan bii ọgbọn sẹyin, ni Foluke Daramola, ẹni ti oun gba ọpọlọpọ ọdun lọwọ rẹ, sọrọ odi si oun nitori oun ba awọn kan sisẹ.
"Mo wo oju opo ayelujara, Foluke jẹ ẹni ọdun marundinlaadọta, ti mo si jẹ ẹni ọdun mejilelọgọta.
"N ko ro pe boya o ranti sugbọn oun naa ti ri agba fin ri.
"A sisẹ kan bi ọgbọn ọdun sẹyin, n ko gba owo fun isẹ naa sugbọn ọrọ ti Foluke sọ si mi lọdun naa buru jai.
"Nnkan to ba se ,ni wa a gba, ni ọrọ to wa nilẹ yii."
Mo tí tọrọ aforijin lọwọ Anti Yeni, ẹ ma binu si mi - Foluke Daramola
Ọrọ ti Yeni Kuti sọ yii lo mu ki ariwo gba oju opo ayelujara, ti awọn eeyan si n gba ọrọ naa wo, bi ẹni gba igba ọti.
Lẹyin ọrọ Yeni Kuti yii, ni Foluke Daramola kede pe oun ti lọ tọrọ aforijin lọwọ obinrin naa lẹyin to fi ọrọ ransẹ si osere tiata pe o sọrọ odi ni bi ọgbọn ọdun sẹyin.
Folukẹ kede ọrọ naa lori opo ayelujara rẹ lọjọbọ oṣe yii.
O ni, "Mo wa sori ayelujara lati wa sọ ọrọ kekere kan nitori ọpọ eeyan lo ti ke si mi lori ọrọ ti Aunty Yenu sọ lori ẹrọ mohunmaworan pe mo sọrọ odi si wọn ni bii ọgbọn sẹyin.
"Mo n se eleyi nitori ita gbangba ni wọn ti fẹsun kan mi, ti mo si ti ba wọn sọrọ, tọrọ aforjin lọwọ wọn.
"Sisọrọ abuku si eeyan ni ko ki n se nnkan ti emi gan alara fara mọ, ni paapaa julọ, si awọn eeyan to ba ju mi lọ.
Aunty Yeni jẹ ẹnikan to ju mi lọ ni gbogbo ọna."















