Àlàyé rèé lórí ikú ọmọ Yul Edochie, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà

Kambilichukwu ati baba rẹ, Yul Edochie

Oríṣun àwòrán, Yul Edochie

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ọmọ oṣere titata, Yul Edochie, ti jade laye.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, SP Benjamin Hundeyin, sạlaye fun BBC pe aarọ Ọjọbọ, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹta, ̣ọdun 2023 yii ni ọmọdekunrin naa, Kambilichukwu Yul-Edochie fi aye silẹ.

Hundeyin sọ pe oṣere naa ti lọ si agọ ọlọpaa to sunmọ agbegbe ibi to n gbe lati fi ohun silẹ pe lootọ ni ọmọ oun jẹ alaisi.

O fi kun pe ile ẹkọ ni ọmọ naa ku si, iwadii si ti bẹrẹ lori ohun to sọkunfa iku rẹ.

Ile ẹkọ ni ọmọ Yul Edochie ku si, a si se ayẹwo oku rẹ - Ọlọpaa Eko

Hundeyin fikun pe oni ọjọ Ẹti ni awọn yoo tari iwadii iku ọmọde ọhun lọ si ẹka SCID, fun iwadii ni kikun.

Ṣaaju lọjọbọ ni iroyin iku ọmọ naa kọkọ gba ori ayelujara, ti awọn eeyan si n ba ẹbi oloogbe naa kẹdun.

Bo tilẹ jẹ ẹbi oloogbe ọhun ko tii sọ ọrọ kankan nipa iṣẹlẹ naa, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko fidi rẹ mulẹ pe ile ẹkọ ni ọmọ naa ku.

O ni awọn yoo si ṣe ayẹwo oku rẹ lati mọ ohun to pa.

MAY EDOCHIE

Oríṣun àwòrán, MAY EDOCHIE/INSTAGRAM

Osu Kini ọdun yii ni Kambilichukwu, to jẹ akọbi Yul ati Edochie iyawo rẹ, May Edochie ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹrindinlogun rẹ.

Iku ọmọ ọdun mẹrindinlogun yii lo n waye lẹyin iku Whitney Adeniran, to jẹ ọmọ ọdun mejila ati akẹkọọ ile ẹkọ Christland Schools niluu Eko.

Iwadii fi han pe ina mọnamọna lo ṣekupa Whitney.

Ta ni Yul Edochie?

Oṣere tiata ni Yul Chibuike Daniel Edochie, o tun maa n dari ere, bẹẹ lo tun maa n kọ itan.

Ọjọ keje, oṣu Kini, ọdun 1982 ni wọn bi nipinlẹ Anambra, oun si ni ọmọ agba ọjẹ oṣere tiata, Pete Edochie.

Ọpọ ọdun sẹyin lo darapọ mọ iṣẹ tiata, o si ti kopa ninu ọpọlọpọ ere, lara wọn ni Idemili, Devil in Red, ati Show Down.

Yatọ si iṣẹ tiata, o tun jẹ oloṣelu.

Ẹni ọdun mejilelogun lo wa nigba to fẹ iyawo rẹ akọkọ, amọ lọdun to kọja, iroyin gbode pe o fun obinrin mii loyun, ti iyẹn si bi ọmọkunrin kan fun un.