Òpin dé bá ìwọ́de awakọ̀ bí MC Oluomo ṣe gé owó táwọn agbèrò ń gbà l‘Eko

Mc Oluomo ati bọọsi

Oríṣun àwòrán, Collage

Alaga igbimọ to n sakoso gareji ọkọ (PMS) nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya, tọpọ eeyan mọ si MC Oluomo, ti ni aigbọraẹniye ati idunkooko to n waye laarin awọn awakọ ati awọn agbero ti lọ odo, lọ sinmi.

MC Oluomo wa fofin de igbesẹ gbigba owo lọwọ awọn ọlọkọ ero lawọn gareeji lọna eru nipinlẹ Eko.

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ni Ọjọru, lawọn awakọ danfo, Korope ati Molue se iyansẹlodi ati ifẹhonuhan lori bi awọn agbero ti n gba owo lọwọ, ti awọn ko si ri owo kankan mu lọ sile.

MC Oluomo ni oun ti ba awọn ọgalọga ninu awọn alaga gareji sọrọ, ti wọn si ni awọn ko ni fipa gba owo lọwọ awọn awakọ kankan mọ.

Wọn ni ni paapaa julọ, awọn to n gbe ero Oshodi lọ si Tollgate.

MC Oluomo ti mu idẹrun ba awa ọlọkọ ero l‘Eko - Awakọ

MC Oluomo ni tikẹti meji pere ni wọn o ma ja lojumọ, nigba ti wọn ba gbe ero.

O ni tikẹti kọọkan jẹ ẹgbẹrin naira, ti wọn ko si gba tikẹti naa ni inu gareji Oshodi tabi ni Tollgate.

Alaga igbimọ to n sakoso gareji ọkọ naa ni oun wọgile tikẹti ti wọn n ja ni Iyana Ipaja ati Agbado sugbọn wọn gba tikẹti feto aabo ni ẹẹdẹgbẹta naira.

MC Oluomo tun fi ofin de gbigba owo ori lọwọ awọn awakọ lọjọ Aiku ati ọjọ Abamẹta.

Nigba ti wọn n fi idunu wọn han lori igbesẹ naa, ẹnikan lara awọn awakọ naa ni MC Oluomo ti mu idẹrun ba awọn awakọ naa.

O ni gbogbo owo ti awọn yoo maa san bayi ko ju ẹgbẹrun meji le diẹ naira lọ lojumọ.

Àkọlé fídíò, Adedapo Tejuosho: Olóyè tó bá dán ìdánkúùdán wò lára òkú mi yóò gba Ọlọ́run lọ́gàá

"N10k sí N15k lowó gáréèjì tí agbèrò ń gbà lọ́wọ́ wá lójúmọ́, orí ń ta wá l‘Eko"

Aworan ifehonuhan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Awọn dirẹba awakọ “Molue”ni awọn apakan ipinlẹ Eko, ti bẹrẹ iyansẹlodi pẹlu iwọde lati fi aidunnu wọn han lori bi awọn Agbero ti n gba obitibiti owo lọwọ wọn lojumọ.

Awọn awakọ naa ni wọn di opopona Eko si Abeokuta, ti wọn si se akoba fun lilọ bibọ ọkọ lagbegbe naa.

Awọn awakọ ke sita pe ni igbakigba tawọn ba ti de iloro Tollgate to wa laarin ipinlẹ Ogun ati Eko, owo nla ni awọn agbero ma n gba lọwọ awọn gẹgẹ bi owo tikẹẹti.

Lara ohun ti wọn kọ sara patako ti wọn gbe lọwọ ni “Awọn agbero ti su wa’’, A ko le tẹsiwaju lati ma sisẹ fun awọn agbero”.

Aworan mcOluomoo

Oríṣun àwòrán, mcOluomo/facebook

"Owo gọbọi tawọn agbero n gba lọwọ wa ko jẹ ka ko ire oko dele"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Sule Sani, ọkan lara awọn to se ifẹhonuhan ni awọn maa n san ẹgbẹrun mẹwa si ẹgbẹrun marundinlogun lojojumọ.

O ni awọn agbero to wa labẹ isakoso Musuliu Akinsaya ti ọpọ eeyan mo si MC Oluomo, lo maa n gba owo naa lọwọ awọn.

Sule ni ko si bi awọn se fe ko ere oko dele nitori ọpọ owo ni awọn agbero n gba lọwọ awọn, ti ko si ṣe anfani kankan fun ẹgbẹ onimoto.

Awọn onisowo ti isẹlẹ naa soju wọn ni iyansẹlodi naa dakun isoro awọn eeyan to lo ọna Eko si ipinlẹ Ogun.

Yemi Ajegunle tii se onisowo ni agbegbe Oshodi salaye pe wakati meji ni oun fi duro ni gareji, ti oun ko si ri moto wọ pada si Eko lati Ipinlẹ Ogun.

Ajegunlẹ ni iwaju ko se lọ, bẹẹ ẹyin ko se pada si fun awọn to ni ẹru to wuwo lati gbe.

Bimbo Apata, tii se osisẹ nile iwosan ijọba ipinlẹ Eko ni ẹsẹ ni oun fi rin lati ipinlẹ Ogun fun bii ọgbọn isẹju lẹyin to wa ni gareji fun wakati meji, ti ko si ọkọ ti yoo gbe.

Awọn ọlọkọ naa ni wọn seleri lati tẹsiwaju ninu iwode wọn titi ti ayipada yoo fi waye.