Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ajínigbé méjì, àwọn tí wọ́n jí gbé gba òmìnira

Aworan

Oríṣun àwòrán, Ogun Police

Ọwọ ṣinkun ọlọpaa ti tẹ awọn afurasi ajinigbe meji ni ipinlẹ Ogun lẹyin ti wọn ji tọkọ-taya kan gbe lọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, ni awọn tun doola ẹmi awọn ti wọn jigbe naa lasiko ti wọn ri awọn afurasi ajinigbe naa mu.

Oyeyemi ni orukọ awọn afurasi ajinigbe naa ni Mohammed Bello ati Mohammed Bashiru.

O ni awọn ara adugbo ni wọn pe agọ ọlọpaa ni ipe pajawiri wipe awọn ajinigbe ti wa ṣọṣẹ ni abule Bisodun ni bii aago mẹjọ alẹ.

Ọkan lara ọdẹ ibilẹ to tẹle ọlọpaa fi ara gbọta, tó sì kú lasiko ti wọn lọ sigbo awọn ajinigbe

Awọn ajinigbe naa ji tọkọ taya ti wọn pe orukọ wọn ni Ojo gbe lọ, ti awọn ọlọpaa si bẹrẹ si iṣẹ lati doola ẹmi.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni wẹrẹ ti awọn de abule naa, ni awọn ba awọn ọdẹ ti wọn tu jade lọgọọrọ lati koju awọn ajinigbe naa.

Atẹjade naa ni awọn ọlọpaa ati awọn ọdẹ naa bẹ si inu igbo lati wa awọn ajinigbe naa ri.

O fikun pe ni kete ti awọn ajinigbe naa ri wọn, ni wọn doju ibọn kọ wọn, ti ẉọn si fi ija pẹẹta.

O ṣe ni laanu pe ọkan lara awọn ọdẹ naa fi ara gba ọta ibọn, ti wọn si gbe wọ lọ si ileewosan, amọ to gba ibẹ lọ.

Ọwọ tẹ ajinigbe meji lara awọn to salọ - Ọlọpaa

Ileesẹ ọlọpaa ni lasiko naa ni awọn ajinigbe yii sa asala fun ẹmi wọn, ti wọn si fi awọn mejeeji ti wọn jigbe silẹ.

O ni awọn si ti gbe awọn tọkọtaya naa lọ si ileewosan fun itọju.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ọdẹ ati ọlọpaa pada si ibẹ lẹyin ti awọn araalu ta wọn lolobo wi pe awọn ajinigbe naa si wa ninu igbo.

Ọwọ tẹ meji ninu wọn, ti awọn ti wọn jigbe naa si tọka si pe awọn mejeeji wa lara awọn ajinigbe naa.

Nibayii, agbẹnusọ ọlọpaa naa ni awọn ti gbe wọn lọ si ẹka to n risi ọrọ ọdaran fun iwadii lẹkunrẹrẹ.

Àkọlé fídíò, Goroso Ekiti: N kò kábàámọ̀ pé mo gbọ́ Ekiti, òhun ló gbé mi dé ọ̀dọ̀ gómìnà

'N kò fọwọ́ kan nǹkan ọkùnrin "Landlord" mi, ẹ̀jẹ̀ ríru ló ṣekúpa á'

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ifeoma Ossai, ọmọ ipinlẹ Delta ti wọn fẹsun kan pe o ṣekupa Lanlọọdu rẹ lasiko ija nipinlẹ Ogun, ti sọ pe oun ko fi ọwọ kan nnkan ọmọkunrin rẹ gẹgẹ bi iroyin ṣe gbe e sita ati pe, ẹjẹ riru lo sekupa Lanlọọdu naa.

Lọsẹ to kọja ni Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ni ọwọ ti tẹ obinrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan fun ẹsun ipaniyan.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn fi panpẹ ọba mu afurasi obinrin ayalegbe naa lẹyin ti wọn wa fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa to wa ni agbegbe Sango Ọta.

Arakunrin to wa fi ẹjọ naa sun, to jẹ aburo si oloogbe ṣalaye pe ija laarin ayalegbe ati onile lori sisan owo ile lo mu onile gba ibẹ lọ.

Wọn fi ẹsun kan Ossai pe nigba ti wọn bẹrẹ si ni ja, ni obinrin naa di nkan ọkunrin onile rẹ mu, to si daku gbọnran-gandan, ko to dipe o gba ibẹ lọ.

Ossai nigba to n ba ileeṣẹ iroyin abẹle kan sọrọ lati atimọle ileeṣẹ ọlọpaa ni isẹlẹ naa waye lọjọ Satide nigba ti awọn alabagba rẹ ni ki oun wa san owo ina ẹgbẹrun kan sugbọn oun lodi si owo naa nitori bawo ni awọn se ma lo ina ẹgbẹrun mejila laarin ọjọ marunun.

"Mo yari pe n ko ni san owo mọ nitori pe iyanjẹ ni fun mi lati san owo ti nko ba wọn jẹ..

"Bi Landlord mi ṣe gbọ pe n ko ni san owo ni o bẹrẹ si ni ma pariwo mọ mi, to si tun fọ mi lẹti pẹlu

"Iyawo rẹ naa fami lara ya pẹlu ekana loju ati ara mi.

"Aburo Landlord mi kilọ fun pe ko ma ba mi ja nitori ẹjẹ riru rẹ"

Ossai tẹsiwaju pe aburo Lanlọọdu oun, Daddy David kilọ fun fun Lanlọọdu oun pe ko jawọ ninu bo ṣe ba oun ja nitori ilera rẹ

"Daddy David ni ẹgbọn rẹ ni ailera ẹjẹ riri, ti ija si le da nnkan ti ko da silẹ. O kuro nibẹ sugbọn Iyawo rẹ si n pariwo mọ mi pẹlu gbogbo apa ti wọn ti fa simi lara lasiko ti wọn ba mi ja.

"Mo pada lọ ba iyawo, ti mo si da sẹrira to da fun, koda Daddy David fimisilẹ lati fi iya jẹ dada ko tẹmilọrun ko to la wa.

"Nigba ti mo pada wọ ile mi pe ki lọ mura lati lọ si agọ ileeṣẹ ọlọpaa ni mo n gbọ ariwo pe Landlord mi subu .

"Mo sare wọ ile wọn, ti mo si ri ibi to sun si pẹlu fonu lọwọ rẹ to fẹ fi pe awọn ti yoo wa gbe mi.

"A gbe digbadigba lọ ile wosan nibi to ti pada dakẹ si."

"Irọ to jina si otitọ ni iroyin pe mo kọlu nnkan ọmọkunrin rẹ"

Ossai ni oun duro ti Ọlọpaa fi de, ti wọn si sọ pe o ṣubu lẹyin ija ṣugbọn o ya oun lẹnu nigba to gbọ lọjọ keji pe wọn ni oun kọlu nnkan ọmọkunrin Landlord oun.

O ni irọ to jina si ootọ ni pe oun kọlu nnkan ọmọkunrin Lanlọọdu rẹ.

"Gbogbo wa ni a ri nkan to sẹlẹ, ti ko si nnkan to jẹ mọ wipe mo fi nnkan kọ lu wọn labẹ".

"Irọ to jina si otitọ ni iroyin naa."