Tinubu sọ̀rọ̀ lórí ìpàdé tí àwọn kan sọ pé ó wáyé láàrín òun àti adájọ́ àgbà Nàìjíríà

Aworan Tinubu ati onidajọ Ariwoọla

Oríṣun àwòrán, asiwaju bola tinubu/twitter/others

Igbimọ ipolongo fun aarẹ ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan, Bọla Ahmed Tinubu ti sọrọ sita pe iru gbuu ni iroyin to n lọ kiri pe oun ati adajọ agba orilẹede Naijiria, Onidajọ Olukayọde Ariwoọla jọ pade fun ipade idakọnkọ ni ilu London.

Igbimọ ipolongo fun aarẹ ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan, Bọla Ahmed Tinubu ni ara ọna ẹrọ tawọn alatako n gba lati wa oju ẹka iṣedajọ mọra lọna ati lee yi ibo to gbe e wọle danu leyii.

Ninu atẹjade kan to fi sita l’Ọjọbọ eyi ti adari ipolongo fun igbimọ to n ṣe kokari ipolongo fun idibo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, PCC, Bayọ Ọnanuga fi sita, O ni orilẹede France ni Tinubu wa lọwọ yii, ko si si bi o ṣe le wa ni ilu London lati ṣe ipade pẹlu ẹnikẹni.

“Ọrọ ahunjọ irọ ni eyi lati mu ki awọn eeyan maa ni igbẹkẹle ni ibo to gbe Bọla Tinubu wọle.

“A fẹ fi idi rẹ mulẹ pe ko si ipade kankan to waye laarin aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan pẹlu adajọ agba orilẹede Naijiria. Ahunjọ irọ lasan ni eyi, ko lẹsẹ nlẹ rara ni.”

Atẹjade naa ni awọn to n gbe iroyin naa kiri n sọ peadajọ agba Naijiria tẹ ọkọ leti lọ si oke okun ni ọjọ kọkanla oṣu kẹta lori kẹkẹ awọn alaarẹ wheelchair, bẹẹni ọjọ kọkanlelogun osu kẹta ni Tinubu ṣẹṣẹ gbera kuro lorilẹede Naijiria ni tirẹ lọ si orilẹede France.