Ilé ẹjọ́ UK kéde ọjọ́ tí yóò dájọ́ ìjìyà tó tọ́ sí Ekweremadu àti ìyàwó rẹ̀

Oríṣun àwòrán, MET POLICE
Ọmọ ti wọn gbe wa ile iwosan wa ko faramọ ki wọn yọ kindinrin rẹ - Dokita
Akọṣẹmọṣẹ ni ile iwosan Royal Free, dokita Peter Dupont jẹ ko di mimọ pe ọmọkunrin ti wọn fẹ yọ kindinrin rẹ ko fara mọ ohun ti wọn fẹ ṣe ọhun lẹyin to rii pe oun ko ni olugbaninimọran nipa awọn ewu to wa ninu ṣiṣe iṣẹ abẹ naa to si jẹ wipe ko ni ni owo itọju ara fun ilera ọlọjọ pipẹ ti yoo nilo lẹyin iṣẹ abẹ.
Ile ẹjọ tun gbọ wipe awọn Ekweremadu tun yi ọkan wọn pada lati lọ si orilẹede Turkey lati wa ẹlomiran ti yoo fun wọn ni kindinrin.
Nigba ti iwadii bẹrẹ ti awọn ọlọpaa fi ọrọ wa ọmọ naa lẹnu wo, o sọ fun wọn pe: “Dokita sọ fun mi mo ti kere ju ṣugbọn arakunrin agba naa sọ pe bi wọn o ba ṣee nibi, oun maa gbe mi pada si orilẹede Naijiria lati lọ ṣe e.”
Igboro Eko lo ti wa
Awọn adajọ gbọ wipe Sonia ọmọ awọn Ekweremadu n kọ ẹkọ onipele masters ni fasiti Newcastle nigba ti aarẹ de sii lara ninu oṣu kejila ọdun 2019.
Lọdun 2021, baba rẹ bere fun iranwọ aburo rẹ to jẹ onimọ iṣegun oyinbo, diwe Ekweremadu lati mọ ohun ti wọn lee ṣe ati lati wa ẹni to lee fun wọn ni kindinrin, ile ẹjọ gbọ eyi.
Diwe Ekweremadu to n gbe lorilẹede Naijiria lo ba ọmọ kilaasi rẹa tijọ sọrọ, Dokita Obeta to wa ni Southwark ni South London to ṣẹṣẹ ṣe pasiparọ kindinrin ni ile iwosan Royal Free pẹlu dokita ọmọ Naijiria kan.
Sonia ko lee pa a mọra, o bu sẹkun nile ẹjọ?

Sonia, ọmọ Ekweremadu to nilo kindinrin ko lee pa a mọra, o bu sẹkun ninu ile ẹjọ nigba ti wọn da a lare ti adajọ kede pe wọn ti yọ ọ kuro lara awọn to jẹbi ẹsun.
Bo ṣe bu sẹkun lo di mọ baba rẹ nigba ti wọn n gbe baba rẹ lọ si atimọle pẹlu awọn to ku ti wọn da lẹbi gbogbo ẹsun naa ṣaaju ọjọ karun, oṣu karun ti wọn yoo ṣe idajọ wọn gan.
Ile ẹjọ si ti sọ pe ijiya to ga ju to tọ fun ẹsun yiyọ ẹya ara eniyan fara pẹ eyi to nii ṣe pẹlu ẹmi tabi titi ayeraye.
Adajọ sọ oko ọrọ si Ekweremadu ati iyawo rẹ lori bi wọn ṣe fiya jẹ ọmọ naa
Lẹyin ti wọn kede pe awọn mẹta jẹbi ẹsun naa lootọ, adajọ agba Joanne Jakymec ṣapejuwe bi wọn ṣe gbimọ pọ lati yọ ẹya ara ẹlomii gẹgẹ bi “igbomọpọ to dẹru bani gidi gan”.
“Awọn olujẹjọ ko fihan pe wọn ni oju aanu fun itọju ọmọ naa rara, ilera rẹ ati igbe aye rẹ pẹlu ko jẹ wọ́n logun ti wọn si fẹ fi ọwọ ọla gba a loju ni gbogbo akoko rẹ ni UK.
“Ìdájọ́ mi rèé!”
Iroyin to n rẹ wa lọwọ ni yajoyajo ni pe ile ẹjọ ti da ẹjọ to nii ṣe pẹlu gbajugbaja oloṣelu ọmọ Naijiria kan, Sẹnetọ Ike Ekweremadu, iyawo rẹ ati dokita to jẹ agbodegba fun wọn lori sun ṣiṣe katakara ẹya ara eniyan.
Ẹsun yii ni ṣe pẹlu pe wọn mu ọdọ̀mọkunrin kan ẹni ọdun mọkanlelogun lọ si United Kingdom.
Sẹnetọ Ike Ekweremadu to jẹ ẹni ọdun ọgọta, iyawo rẹ Beatrice to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ati Dokita Obinna Obeta toun naa jẹ aadọta ọdun ni ile ẹjọ ilẹ United Kingdom ti da lẹbi pe lootọ wọn jẹbi gbigbimọ pọ lati yọ ẹya ara arakunrin kan ti wọn mu lọ London lati ipinlẹ Eko ni Naijiria.
Awọn agbẹjọro sọ fun adajọ ni Old Bailey wipe kindinrin ọmọ naa ni wọn fẹ yọ ki wọn si fun ọmọbinrin Ekweremadu iyẹn Sonia ẹni ọdun 25.

Oríṣun àwòrán, Ekweremadu/Facebook
Ki ni adehun ti ẹbi Ekweremadu ba ọmọ igboro Eko naa ṣe?

Oríṣun àwòrán, PA Media
Ile ẹjọ ni wọn ṣeleri lati fun ọmọkunrin naa ti iroyin ko lee forukọ rẹ sita ni ẹgbẹrun meje pọun owo UK (£7,000) ti wọn si tun ṣeleri fun un lati ba a wa iṣẹ ni UK nitoripe o ran awọn lọwọ.
Ẹwẹ, ile ẹjọ sọ pe ọmọkunrin ri iyalẹnu nigba to pade awọn dokita ti wọn fẹ yọ kindinrin rẹ ni ile iwosan.
Wọn fẹsun kan wipe awọn olujẹjọ ti gbiyanju titi lati wi fun awọn dokita pe ibatan ni mọkunrin naa jẹ si awọn eyi ti oloyinbo n pe ni “cousin”, nigba to jẹ wipe wọn o tilẹ tan rara.
Ṣe Sonia, ọmọ Ekweremadu naa jẹbi? – Adajọ sọrọ
Ẹwẹ, ile ẹjọ da ẹjọ wipe Sonia ọmọ Ekweremadu ni tirẹ ko jẹbi ẹsun naa.
Ọmọkunrin ti wọn gbe lọ si London naa jẹ ẹni to maa n ta ja loju popo ni ipinlẹ Eko.
Ekweremadu atawọn ẹmẹwa rẹ gbe ọmọ naa lọ si UK ni ọdun to kọja lati jẹ ko pese ẹya ara kindinrin rẹ ti wọn si fẹ san iye owo £80,000 fun ṣiṣe pasiparọ naa ni ile iwosan.
Ile iwosan Royal Free Hospital ni London ni wọn ti fẹ ṣe pasiparọ kindinrin ọmọ naa fun ọmọ tiwọn.
Bi Ileeṣẹ ọlọpaa MET ṣe mu Ekweremadu ati Iyawo rẹ Beatrice
Ọwọ tẹ Ekweremada ati iyawo rẹ lẹyin iwadii ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ UK.
Ileeṣẹ ọlọpaa MET ninu atẹjade kan ti wọn fi lede ṣalaye bi iwadi wọn ṣe ṣawari tọkọtaya naa.
"Beatrice Nwanneka Ekweremadu, ẹni ọdun marundinlọgọta, ọmọ orilẹede Naijiria ni a fi ẹsun kan pe o lẹdipọ pẹlu ọkọ rẹ ati dokita kan lati gbe eeyan wọ ilẹ UK lati lo awọn eya ara ara rẹ.
Awọn afurasi mejeeji wa ni atimọlẹ ileeṣẹ ọlọpaa MET.
Wọn bẹrẹ iwadii lẹyin ti awọn agbofinro fi to wọn leti pe iwa awọn tọkọtaya naa lodi si ofin.
Ileeṣẹ ọlọpaa MET ni awọn ti gba ọmọ naa silẹ, ti wọn si n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn alabase lati pese iranwọ.
Ike Ekweremadu ni o jẹ igbakeji aarẹ ilẹ igbimọ asofin Naijiria tẹlẹ ri.
“Kii ṣe ẹṣẹ si ofin lati fun eeyan ni kindinrin amọ ...”
Bo tilẹ jẹ wipe ati fun eeyan ni kindinrin kii ṣe ohun to lodi si ofin amọ nnkan ti yoo sọ ọ di iwa ọdaran ni to ba ti ni ọrọ owo fifuni ninu tabi anfani nnkan mii.
Nigba ti o hande pe kindinrin ọmọkunrin naa ko ba ti ẹni ti wọn fẹ yọ ọ fun mu, ile ẹjọ gbọ pe awọn Ekweremadu yi ọkan wọn si lilọ si Turkey lati lọ wa oluranlọwọ miran.
Bi itọpinpin ṣe bẹrẹ ni pe ọmọ kunrin naa sa kuro ni ilu London to si n sun kaakiri fun ọpọlọpọ ọjọ ko to di pe o rin wọ inu agọ ọlọpaa kan ni agbegbe Staine ni Surreal ti wọn rii to n ke to si fihan pe o ti rẹ ẹ.












