PDP wọ́gilé àṣẹ tó ní kí Fayose, Ayim àtàwọn míì kúrò nínú ẹgbẹ́

Oríṣun àwòrán, thisdaylive
Igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọgile aṣẹ to ni ki awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan lọ rọkun nile na.
Lara awọn eeyan ti wọn yi idaduro wọn pada ninu ẹgbẹ naa ni awọn gomina nigba kan ri, Ayodele Fayose ati Ibrahim Shema.
Ọrọ naa tun kan Aarẹ ile igbimọ aṣofin tẹlẹ, Pius Anyim, to fi mọ awọn ọmọ ẹgbẹ mii bii Dennis Ityavyar ati Aslam Aliyu.
Alukoro ẹgbẹ ọhun, Debo Ologunagba, lo fi igbesẹ naa lede ninu atẹjade kan.
Ologunagba ni ẹgbẹ ọhun gbe igbesẹ naa lẹyin ijiroro kan lọjọbọ.
Atẹjade naa ni “Igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ yii mọ daju pe o ṣe pataki lati pari aawọ to ba waye larin awọn olori ẹgbẹ ki ẹgbẹ le maa tẹsiwaju.”
“Ẹgbẹ oṣelu PDP gbọdọ fimọ ṣọkan, a si gbọdọ ni afojusun lati gba ẹtọ wa ti awọn kan ja gba ninu eto idibo sipo Aarẹ to waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, nile ẹjọ.“
Igbesẹ yii lo waye lẹyin ọjọ meji ti adari ẹgbẹ naa kọwe fi ipo rẹ silẹ latari awọn họwuhọwu kan to waye ninu ẹgbẹ oṣelu ọhun.
Bawo ni ọrọ naa se bẹrẹ?
Ṣaaju ni idarudapọ ti kọkọ n waye ninu ẹgbe oṣelu naa ki eto idibo sipo Aarẹ to waye.
Lara awọn ipenija to koju ẹgbẹ naa ni ti awọn gomina “G5” ti wọn fẹsun kan pe wọn n ṣiṣẹ tako ẹgbẹ naa ninu idibo Aarẹ.
PDP fẹsun kan Fayose pe o kọ lati ṣatilẹyin Atiku Abubakar to dije du ipo Aarẹ ninu ẹgbẹ ọhun, to si ṣatilẹyin fun Bola Tinubu ti inu ẹgbẹ oṣelu APC.
Lẹyinorẹyin, Tinubu jawe olubori ninu eto idibo naa nigba ti Atiku lulẹ.
Ni Katsina, wọn fẹsun kan Shema pe o ṣiṣẹ lodi si ẹni to du ipo gomina ninu ẹgbẹ, eyii to jẹ ki oludije ninu ẹgbẹ oṣelu APC bori ninu ibo gomina nibẹ.
Nipinlẹ Ebonyi, wọn fẹsun kan Ayim pe o ṣatilẹyin fun ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo gomina kaka ko ṣegbe lẹyin ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ.
Wayi o, awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa ti wa ke si gbogbo ọmọ ẹgbẹ lati ṣe ara wọn ni oṣuṣu ọwọ fun ilọsiwaju ẹgbẹ naa.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
''Ìdí nìyíí tì Ayu gbọ́dọ̀ kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tipátipá''

Oríṣun àwòrán, PDP/Facebook
Ẹgbẹ oselu PDP ti ja iwe lọ gbe ile rẹ fun alaga apapọ ẹgbẹ oselu PDP, Iyorchia Ayu fun ẹsun wi pe oun siṣẹ lodi si ilosiwaju ẹgbẹ naa.
Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni ijoba ibilẹ Gboko, ni ipinlẹ Benue lo ko iwe naa si ẹni ti o jẹ alaga apapọ fun ẹgbẹ oṣelu rẹ.
Ninu iwe naa ni wọn ti ni awọn ko ni igbagbọ ninu Ayu mọ gẹgẹ bi adari wọn.
Nigba ti wọn ka awọn ẹsun rẹ, akọwe ẹgbẹ naa ni agbegbe ijọba ibilẹ Igyorov, Vanger Dooyum ni Ayu ati awọn amugbalẹgbẹ rẹ ti sisẹ tako ẹgbẹ oṣelu PDP.
Wọn ni eyi jẹ ki ẹgbẹ na fidirẹmi ninu eto idibo sipo asojusofin, ati idibo sipo gomina ipinlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Kashi Philip

Oríṣun àwòrán, Kashi Philip
Bakan naa ni wọn fi ẹsun kan an pe o kọ san owo to yẹ si apo ẹgbẹ oselu naa gẹgẹ bi ofin ẹgbẹ naa se lalẹ.
Awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa lati ẹkun mejila ninu mẹtadinlogun lo fọwọ si igbesẹ naa.
Wọn ni Ayu kọ lati dibo ninu eto idibo sipo gomina ati ile igbimo asofin ipinlẹ naa, ti awọn amugbalẹgbẹ Ayu si siṣẹ tako ẹgbẹ PDP, to si jẹ ki ẹgbẹ naa ri ijakulẹ ninu eto idibo naa.
Alaga ẹgbẹ oselu PDP ni Igyorov, Kashi Philip ati awọn alaga ẹgbẹ na ni agbegbe Igyorov lo fọwọ si iwe naa.
''Awọn alaga ẹgbẹ PDP lẹsẹ kuku ko ni agbara lati yọ mi'' - Ayu
Ninu esi rẹ, Iyorchi Ayu ni awọn to n gbiyanju lati yọ oun nipo jẹ aliloye ti wọn ko si mo ofin ati ilana ẹgbẹ oselu naa.
Simon Imobo Tswam to jẹ agbẹnusọ fun Ayu lo fi ọrọ naa lede.
Oni iwe ti wọn fi yo oun ni ẹgbẹ fihan wi pẹ awọn alaga wọọdu naa ko mo iwe kọ rara.
Ayu ni igbimo ajọ agba ẹgbẹ PDP nikan lo ni agbara lati yoo oun nipo.















