Peter Obi gbé ìgbésẹ̀ lórí bí ẹgbẹ́ LP ṣe sọ owó fọ́ọ̀mù gómìnà di N25 láti N15m

Aworan Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Peter Obi

Oludije aarẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party ni idibo to kọja lorilẹede Naijiria, Peter Obi ti kan sara si ẹgbẹ oṣelu rẹ fun bi wọn ṣe kede adikun sowo gbigba fọọmu awọn oludije gomina.

Ọwọ fọọmu ọhun lo ti dikun lati milọnu marundinlogun si milọnu mẹẹdogun naira saaju eto idibo nipinlẹ Kogi, Bayelsa ati Imo

Obi ni oun gba ẹgbẹ oṣelu naa ni imọran lati se adikun si owo naa ko le dọgba pẹlu owo fọọmu ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC.

Obi kan saara si ẹgbẹ oselu Labour to da N15m pada fun ẹbi oludije to ku

Bakan naa lo dupẹ lọwọ ẹgbẹ oṣelu Labour fun bi wọn se gba lati da owo fọọmu pada fun mọlẹbi ọkan lara awọn oludije to padanu ẹmi rẹ lẹyin to gba fọọmu.

Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja lẹyin to se ipade pọ pẹlu Alaga ẹgbẹ, Julius Abure ati awọn ọmọ ile gbimọ aṣoju sofin lo kede bẹẹ.

Obi ni ẹgbẹ oṣelu Labour ti gba lati da miliọnu marundinlogun pada fun awọn mọlẹbi oloogbe naa.

"Mo kan sara si alaga ẹgbẹ oṣelu wa, Barr Julius Abure, fun bi wọn se gba ẹbẹ mi, ti wọn din owo fọọmu ku fun awọn oludije si milọnu mẹdogun.

"Bakan naa ni mo kan sara fun bi wọn se gba lati da owo fọọmu oloogbe Humphrey Amumudu pada, ọkan lara awọn oludije sipo gomina nipinlẹ Imo fun awọn mọlẹbi rẹ lẹyin to di oloogbe ."

Àkọlé fídíò, Goroso Ekiti: N kò kábàámọ̀ pé mo gbọ́ Ekiti, òhun ló gbé mi dé ọ̀dọ̀ gómìnà

Afenifere, Ohaneze Ndigbo sọ̀rọ̀ lórí ohun tí Iwuanyanwu sọ nípa Yorùbá nínú fídíò kan

Aworan Emmanuel Iwuanyanwu

Oríṣun àwòrán, Emmanuel Iwuanyanwu

Ni opin ọsẹ to kọja ni fidio kan ti gba ori ayelujara kan ninu eyi to se afihan olori igbimọ agbaagba ẹya Igbo, Ohaneze Ndigbo, Oloye Immanuel Nwuanyawu.

Ninu fidio naa ni Iwuanyawu ti sọrọ nipa ibo to kọja nipinlẹ Eko ati bo se ni wọn se awọn ẹya Igbo kan lese.

Iwuanyawu ni wọn lo sọrọ naa lasiko ayẹyẹ ọdun kan ti Gomina Chukwuma Soludo ti n dari ipinlẹ Anambra eyi to waye niluu Awka.

Gẹgẹ bi fido naa ti wi, Nwuanyawu ni “ iwa oselu janduku lawọn ẹya Yoruba n hu, a si gbe igbesẹ lati koju wọn laipẹ.

Ko si ẹni to lẹtọ lati maa gbẹmi ẹya Igbo ti ko sẹ, ẹni to ba si gbe igbesẹ yii ni gbogbo ẹya Igbo yoo ba ja.

Ko si ija laarin ẹya Yoruba ati Igbo to wa nilu Eko amọ awọn Yoruba kan n se oselu ọmọ ita ni.”

Bẹẹ ba gbagbe, awuyewuye kan waye lasiko idibo gomina nipinlẹ Eko, nibi ti awọn eeyan kan to jẹ ẹya Igbo to n se atilẹyin fun ẹgbẹ oselu Labour ti kede pe awọn janduku kan se awọn lese.

Ki ni Afenifere sọ nipa ọrọ Nwuanyawu naa?

Igbimọ apapọ ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Afenifere ti bu ẹnu atẹlu ọrọ kan to n kaakiri lori ayelujara pe Emmanuel Iwuanyawu sọ pe oniwa jagidijagan nidi oselu ni awọn Yoruba.

Afenifere, ninu atẹjade tí akọwe ẹgbẹ naa, Apagun Omololu buwọlu lọjọ Aiku, gbena wo oju ọrọ ti Iwaunyawu sọ, to si kesi awọn olori Ohanaeze Ndigbo lati ba ọmọ wọn wí.

"A ti wo fọnran naa, ti a si n kesi Ohanaeze Ndigbo lati wa wí tẹnu wọn lori ọrọ ti Oloye Iwuanyawu sọ si Yoruba.

"Bakan naa ni a n kesi Ohanaeze lati kilọ fun awọn oloye rẹ lati dẹkun sísọ ọrọ ti ko da si Yoruba.

"Orilẹede to ko eeyan mọra ni wa, wọn ko gbọdọ fi igi gun wa loju rara.

"A rọ awọn Yoruba lati ma ṣe awọn ọmọ iya wọn lati ile igbo gẹgẹ bii ọta nítorí pe gbogbo agbaye lo mọ pe iran Yoruba jẹ iran alaafia, to fẹ ilọsiwaju Orilẹede Naijiria."

Iroyin ofege ni iroyin to ni Iwuanyanwu sọrọ odi si Yoruba - Ohanaeze fesi

Ẹgbẹ igbimọ Ohanaeze Ndigbo ti wa fesi pada pe iroyin ofege ni iroyin to sapejuwe pe olori Iwuanyawu sọrọ odi si Yoruba

Ninu atẹjade tí akọwe ẹgbẹ, Chiedozie Ogbonnia fi ransẹ si awọn akọroyin ni awọn eeyan kan lo fẹ da ija ẹlẹyamẹya silẹ laarin ẹẹya mejeeji.

Ogbonnia ni ti Iwuanyawu sọ ní pe ki awọn ẹẹya ibo to wa ninu Eko ma ṣe foya nítorí ko si laburu laarin ẹẹya mejeeji.

"Wọn ti pe akiyesi wa si iroyin ofege kan pe Olori igbimọ agbagba Ohanaeze, Oloye Emmanuel Iwuanyawu sọrọ odi si Yoruba

"Irọ to jina sì otitọ ni eleyi, tí awọn kan fẹran lati da ija ẹlẹyamẹya silẹ laarin ẹẹya mejeeji ni.

"Bí wọn se se fun ẹẹya Igbo niluu Eko ni ko sẹyin awọn eeyan kan ti ko fẹran alafia rara sugbọn a mọ pe awọn eeyan gidi to jẹ ọmọ Yoruba si wa."