Headline: Ooni dá sí àáwọ̀ àárín àwọn Mùsùlùmí àti Olórò, gbọ́ ohun tí Oonirisa sọ

Aworan Ooni ati Mosalasi

Ede aiyede ṣi n tẹsiwaju laarin awọn ẹlẹsin abalaye ati awọn musulumi ni ile ife pẹlu bi awọn musulumi se ṣe ikọlu si ojude orọ awon oloro.

Imaamu agba ti ile ife Abdulsami Abdulhameed ti rọ awọn ẹlẹsin mejeji lati jẹ ki alafia jọba.

Imamu naa ni olukuluku lo ni ominira labẹ ofin lati se ẹsin to wu u o si rọ awọn musulumi lati fọwọ wọnu ki alafia le jọba.

Bakan naa, Abdulsamii parọwa fun awọn ẹlesin ibilẹ lati kilọ fun awọn ọmọ wọn ti wọn ko loye tao ki wọn si dawọn lẹko lori bi wọn o ti maa huwa lawujọ.

Ẹwẹ, Obalufe ti ile Ife Ọba Idowu Adediwura to jẹ asoju Ooni ti Ile Ife ni, “Kabiyesi Ooni ile Ife jẹ lori gbogbo awọn ẹlẹsin to wa nile ife iyẹn ẹsin Kristẹni, Musulumi ati awọn Oniṣẹṣe.

Ọbalufe pe fun alafaia laarin awọn ẹlẹsin mejeji to ni aawọ, o si ni Kabiyesi Ooniriṣa ṣetan lati tun gbogbo oun to bajẹ lasiko ikọlu naa ṣe.

“Ẹ fọwọ wọnú! Bayii ni Ooni ṣe pàrọwà sí àwọn ọdọ Mùsùlùmí tó fariga nílé Ife, lẹ́yìn ti wọ́n lọ f’ina sojude Oro.

Asoju Ooni ni awọn ẹlẹsin mejeji ti wa ni irẹpo tẹlẹri fun igba pipẹ.

"Àlùwàlá là ń ṣé lọ́wọ́ táwọn Olórò fi yà wọ mọsalasi, ìná bárà ni wọ́n nà wà"

Aworan

Ọjọbọ ọsẹ yii ni awọn onisẹse kan yawọ inu Mosalasi ni Ilare nibi aago mẹrin ọsan, ti wọn si lu awọn ti wọn ba ninu Mọsalasi na lalu bami, nibiti ọpọ wọn ti farapa yanayana.

Idi ree tawọn musulumi nilu ile Ifẹ fi se iwọde lati fi aidunu wọn han si bi awọn oloro se se ikọlu si Mosalasi naa.

Awọn to n se iwọde naa salaye pe Imamu agba fun Mosalasi naa ati awọn marun miran ni wọn se ikọlu sii, ti wọn si tun gun wọn ni ọbẹ.

Ọkan lara awọn ti isẹlẹ naa soju rẹ ni ”a wa ninu Mosalasi lati gbadura, awọn kan n se aluwala lọwọ, ti awọn oloro fi wọnu Mosalasi.

“A mọ wi pe wọn n gbe oro lọwọ nilu Ile Ife sugbọn a ko fi tiwa di wọn lọwọ, ṣadede ni wọn pada wa sinu Mosalasi fun iṣẹ ibi ti wọn fẹ se.

Won ko jẹ ki Imamu wa sọrọ nigba ti wọn wọ inu Mosalasi wa, ti wọn fi bẹrẹ si ni na wa, ile iwosan to wa ni ile ife ni wọn gbe wa lọ fun itọju’.

aworan mosalisi

"Awọn Oloro se irufẹ ikọlu yii si wa ni osu kọkanla ọdun 2022"

Awọn oluwọdẹ naa ni awọn tun kansi Aafin Ooni Ife, lati fẹhonu han ti wọn o si ba nile.

Ọkan lara awọn to n se ifẹhonuhan ni awọn ti fi isẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti.

Wọn ni irufẹ ikọlu naa waye lọdun to kọja ninu osu kọkanla, ti wọn si n pe fun ijiya to tọọ fun awọn to n gbe igbesẹ naa.

Agbẹnusọ fun ile isẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba.

Opalola ni iwadii kikun ti bẹrẹ lori isẹlẹ naa lati mọ awọn idi ti ikọlu naa fi waye.