Ònkọ̀wé Chimamanda Adichie kọ lẹ́tà lòdí sí ìkíni Ààrẹ Joe Biden sí Tinubu, wo èsì àwọn ọmọ Naijiria

Aworan

Oríṣun àwòrán, Collage

Ọkan pataki lara awọn onkọwe ọmọ Naijiria to ti di ilumọọka lagbaye, Chimamanda Ngozi Adichie ti kọ lẹta ojutaye kan si aarẹ America, Joe Biden, nitori eto idibo to sẹ pari lorileede Naijiria.

Ọrọ yii di fanfa nitori ikini ti aare Biden fi ranṣẹ si Bola Tinubu, oludije egbe APC ti Naijiria dibo yan gẹgẹ bi aarẹ eyi to mu onkọwe naa fi ero re sọwọ si Biden.

Lẹta naa jade lori iwe iroyin Atlantic newspaper to si ṣafihan oniruuru kudie kudie to waye lasiko idibo aare Naijiria.

Lẹta ọhun mi ilu titi ni Naijiria to si mu ki awọn ọmọ Naijiria bọ sori ayelujara lati maa sọrọ nipa rẹ.

Nigba ti ilẹ America ki aarẹ ti Naijiria ṣẹṣẹ dibo yan, Bola Tinubu atawọn araalu ku oriire idibo ni ọrọ naa bẹrẹ.

“Idibo to ni ifigagbaga yii safihan igba tuntun fun oselu Naijiria ati ijọba awarawa. Atẹjade naa fikun ọrọ ikini ku oriire ọhun. Bakan naa lo tun tọka si awọn nkan to bi awọn ọmọ Naijiria ninu nipa idibo naa.

Ẹwẹ, onkọwe Chimamanda ninu lẹta to fi fesi sọ pe o ya oun lẹnu pẹlu aduru aiṣedede to waye ninu idibo naa pe aarẹ America le ki Tinubu ku oriire.

O ṣalaye pe ikini America yii n gbiyanju lati din wahala to ṣẹlẹ ku si isoro nipa imọ ẹrọ nikan, eyi ko si dara.

Onkowe yii ni pẹlu iru ọrọ ti America sọ yii, “o da bii pe America ti pinu pe ohunkohun to ba ṣẹlẹ ni ilẹ Afirika kii ṣe ọrọ ijọba awarawa bi ko ṣe baraku”.

“Ọgbọn ori America ko kere, bi wọn ba kan se iṣẹ iwadii ranpẹ, wọn o mọ ohun ti emi ati ọpọ eeyan mii n sọ: Ilana eto idibo to bajẹ ni kii ṣe pe isoro imọ erọ lasan lo ṣẹlẹ ṣugbọn ohun ti wọn mọọmọ ṣe alumọkọrọyi si ni”.

O ni kilode ti America to bọwọ fun idọgba labe ofin yoo gboriyin fun iru idibo to waye ni Naijiria?”

Aare Biden ti tabuku ifarajin America si ijọba awarawa, o yẹ ki US je ohun ti wọn pe ara wọn, ẹ ma gbe ogo isedaadaa fun aisedaada”.

Ki lawon koko ọrọ ti Chimamanda mẹnu ba ninu lẹta rẹ?

Idurodeede

Aworan

Oríṣun àwòrán, Collage

Onkọwe naa ni to ba jẹ tori isedeede ni UK ati US se sare ki Tinubu ku oriire, ki wọn tun un ro daadaa tori “ijoba to wọle lọna aitọ ni orileede to kun fun ọdọ ti bi nkan se n lọ ti su ko lee pese idurodede”.

O ni ikini ku oriire America ko ni ọwọ mimọ tori ko sipaya ipenija to wa ni Naijiria.

“Alakale idibo 2022 pese ireti tuntun”

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Adichie salaye pe titọwọ bọ iwe adehun fun idibo fun awon eeyan ni ireti nnkan yoo tubọ dara lasiko idibo Naijiria tori saaju idibo ọdun yii, ko si eto idibo Naijiria ti kii wọ. “O saba ma n pari pelu ikede eni ti awọn ọmọ Naijiria gbagbọ pe kii se eni ti awọn yan”.

O ni eyi naa lo tun ṣẹlẹ lọdun yii tori INEC ko mu ileri wọn ṣẹ nipa kiko gbogbo esi idibo sori ayelujara.

“Awọn osisẹ ajọ eleto idibo”

Adichie ni lodi si ileri ti INEC se, awọn oṣiṣẹ wọn tun pe lọ si awọn ibudo idibo. “Omii wọn kan san ọwọ lọ ibudo idibo lai ko gbogbo ohun elo to se koko dani”.

Bakan naa ni Adichie ni “isoro aabo farahan lawọn ibi kan ti wọn n yinbọn, ja apoti ibo gba, nibo miran, awọn oṣiṣẹ alaabo tun ba awọn jaduku ṣiṣẹ pọ lati dẹru ba awọn oludibo nigba tawọn mii kan n woran bi ija ẹlẹyamẹya ṣe n yọju.

Esi awọn ọmọ Naijiria ree

Adamu Garba fesi loju opo Twitter pe “Chimanmanda Ngozi Adichie, to jẹ onkọwe ti gbogbo agbaye mọ gẹgẹ bi akọtan tun ti n sọ itan mii bayii bii alọ to da lori awọn eeyan rẹ ti wọn lulẹ ninu eto idibo to ṣẹṣẹ pari yii”.

O ni aisan nla gbaa ni ṣiṣe ẹlẹyamẹya eyi to lee ran awọn teeyan ro pe ọlọgbọn niwọn.

Aworan

Bakan naa David Hundeyin ti ọpọ mọ lori ayelujara ni tirẹ dupẹ lọwọ Chimamanda pe o dide lati sọrọ sita.

“O ṣeun ti o dide duro ki wọn le ka ọ mọ awọn to ya sọtọ. O ṣeun too kọ lati gba “ami ẹyẹ” wọn eyi ti wọn gbero lati fi di ọ lẹnu. O ṣeun ti o duro si apa ibi to dara ninu itan!”

Aworan

Bayo Onanuga to jẹ oniroyin ri fesi bii ẹni kọ lẹta si aarẹ Joe Biden to si sọ fun un pe ko da lẹta ti Chimamanda kọ nipa idibo Naijiria nu ni kete to ba ti de ori tabili rẹ.

“Arosọ lasan lo kọ, eyi to wa latinu erongba akuna eyi to jẹ ara ilu rẹ, Peter Obi”.

Aworan

Reno Omokri ti ọpọ mọ gẹgẹ bi eeyan to maa n sọrọ ṣaa nipa gbogbo to ni ṣe pẹlu orilẹede Naijiria lori ayelujara to si ni ọpọ ololufẹ fi lede pe:

“Mo lero pe ẹ mọ wipe Chimamanda Ngozi Adichie ko kan kii ṣe ọmọ Naijiria kan ti ọrọ oṣelu ko ka lara tabi gbe lẹyin ẹnikan? O kede atilẹyin rẹ fun Peter Obi ṣaaju idibo to si tun pe e ni “aarẹ rẹ”.

Omokri ni Chimamanda n gbe sẹyin oludije kan tori naa ki aarẹ Biden ma wo ọrọ rẹ bi oun to ja mọ nkankan.

Aworan

Ni ti oludije gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party ni ipinlẹ Eko, Gbadebo Rhodes-Vivour, o gbosuba randẹ fun Chimamanda ni to si ni ọrọ arabinrin naa eeyan ko gbudọ wo kọja lai kii kare.

Aworan