Ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo láti gbé Orílẹ̀èdè Nàìjíríà ni láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òkùnkùn - Yemi Solade

Oríṣun àwòrán, Realyemisolade/Instagram
Gbajugbaja osere tiata, Yemi Solade lo ṣe afihan pe ọna kan ṣoṣo to wa fun awọn ọmọ Orilẹede Naijiria lati gbe igbe aye to rọrun ni lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun.
Ọrọ ọhun lo ti fa ọpọlọpọ awuyewuye ti ọpọ si ti ke si Gbajugbaja osere naa lati mọ alaafia rẹ, ti awọn míì si n fun ni ọrọ iwuri.
Solade lo gbe ọrọ yii soju opo ayelujara Instagram rẹ, ti ọpọ awọn ololufẹ si n bẹrẹ lọwọ rẹ pe kini idi to fi gbe irufẹ ọrọ bọ síta.
O ni "Naijiria, lati gbe lorilẹede naa, eeyan gbọdọ darapọ mọ ẹgbẹ okunkun."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Bakan naa ni ọpọ awọn ololufẹ ati awọn akẹgbẹ oṣere tí bẹrẹ si ni ma parọ wa fun lati ma ṣe igbinyanju lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun kankan nitori ọjọ iwaju.
@tracydominic ni "Njẹ mọ pe ki agbalagba eeyan to le bọ síta sọrọ yii jade, arokan n ba ja nìyẹn
@iamnino ni "Ọlọrun nìkan ni kí eeyan salọ ba. Gbe bibeli rẹ, ko si bori wọn.
@Sunday_Igboho1 ni "ki egbo le jina, eeyan gbọdọ mu ọwọ kuro loju rẹ. Eyi to da n bọ laipẹ.















