A ò kí ń dárúkọ ìdí àti ọyàn nínú eré tíátà láyé àtijọ́, àmọ́ báyìí ayé ti di ayé ṣajẹ - Monsuru Fala

Àkọlé fídíò, Iṣẹ́ tíátà kọ́ ló sọ ọ̀pọ̀ di ìdàkudà, láti ilé ni wọ́n ti bàjẹ́ wá – Mosuru Fala
A ò kí ń dárúkọ ìdí àti ọyàn nínú eré tíátà láyé àtijọ́, àmọ́ báyìí ayé ti di ayé ṣajẹ - Monsuru Fala
Aworan

Mosuru Obadina Ayinla, ti ọpọ eeyan mọ si Monsuru Fala ti ba BBC Yoruba sọrọ lori iriri rẹ nidi iṣẹ tiata Yoruba.

Fala sọ fun BBC pe ọjọ ti pẹ ti oun ti bẹrẹ ere ori itage, koda oun ṣiṣẹ nileeṣẹ amohunmaworan ri.

Ni ti orukẹ inagije rẹ “Fala” Monsuru sọ pe asiko ti oun ṣi n ṣere ori itage ni orukọ naa waye.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, owo wa nidi iṣẹ tiata amọ o loju eeyan to le ṣe iṣẹ idari ere nitori ẹbun pataki lati ode ọrun ni.

O ni ọpọ eeyan lo ya sidi iṣẹ tiata lọna ati di gbajumọ, amọ to ba de idi iṣẹ naa tan ni yoo mọ ọna gaa ti Ọlọrun pe si ninu ẹka iṣẹ ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe agba ọjẹ oṣere ni Fala, o ni ẹbun ati ipe oun ni lati maa dari ere.

Ni ti iwa ibajẹ laarin awọn oṣere, Fala sọ pe irufẹ ẹkọ ti eeyan gba lati ile rẹ ni yoo sọ irufẹ oṣere ti yoo jẹ.

O pari ọrọ rẹ pe awọn kii darukọ eya ara bii idi tabi ọyan laye atijọ ninu ere amọ bayi nnkan ti yi pada.

Ẹkunrẹrẹ ohun ti Fala wa ninu fọran to wa lkoke yii.