Wo ọ̀rọ̀ Iya Rainbow, Saheed Osupa, àwọn Alfa, àwọn òṣèré sí Pasuma bó ṣe ń sọkún ikú ìyà rẹ̀

Pasuma, Iya Rainbow, Saheed Osupa

Oríṣun àwòrán, OTHERS

“Lẹnu igba ti Ramadan bẹrẹ yii, ọpọ awọn Alfa ti gba Bournvita, Sugar, Milo, latọwọ mama.

Koda ẹni to gba owo gba owo, ẹni to gba ipe ori foonu naa gba ipe”.

Ṣe ni gbajugbaja olorin Fuji Alhaji Alabi Pasuma bu sẹkun ti ko lee paa mọra ninu ile rẹ̀ nigba ti iku iya rẹ, Alhaja Hadija Odetola ṣẹlẹ.

Koda Alfaa gan ni ki Pasuma sunkun daadaa tori gbogbo eeyan lo mọ bi o ṣe sun mọ iya rẹ pẹkipẹki to.

“Gbogbo ọjọ tẹẹ ti n pariwo iyawo Anọbi, lati ara yin gan ni awọn mii ti mọ pe Hadija ni orukọ mama.

Iya ti wa dakẹ lonii, ẹẹ lo imọni ni o, kii ṣe pe kẹẹ ma sunkun amọ, ẹẹ lo imọni ni”.

Alfa ati Pasuma

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Iru eeyan wo ni Iyawo Anọbi jẹ?

Awọn Alfa to wa tu Pasuma ninu jẹ ko di mimọ pe gbogbo ti ọmọ n ṣe fun iya ni Pasuma ṣe fun un nigba aye rẹ.

“Ọjọ ti iya yin fẹ kuro laye, Kurani lẹ fi sin wọn lọ, mama ti lọ ba Ọlọhun daadaa, ifẹ ti wọn ni si Al-Quaran, aṣiri lo tu yii, tori pe mama yi n kẹ eeyan nigba to wa laye”.

Alfa to n sọrọ naa sọ daadaa nipa iya Pasuma ati Pasuma gan funra rẹ.

O ni lẹnu ti aawẹ Ramadan ti awọn musulumi n gba bẹrẹ yii, ọpọlọpọ Alfa lo ti gba oniruuru ẹbun latọdọ oloogbe naa titi dori owo atawọn nnkan elo.

“Ko si ọdun naa ti aawẹ wa ti mama o ki n pe wa, abiyamọ tòótọ́ ni ìyà Pasuma Alabi”.

Gbogbo ẹbi ara ati ojulumọ to fi mọ awọn akẹgbẹ gbajugbaja olorin Fuji, Alabi Pasuma

Awọn Aafaa to fi waasi rọ Alhaji Alabi Pasuma tun sọ fun un pe, iya rẹ ti ni oun fi Kurani lee lọwọ, Kurani ọhun naa si ni ko maa tẹle.

Awọn Alfaa naa wa gbadura fun Pasuma pe gẹgẹ bi opo aye rẹ iyẹn to bi i ṣe ṣẹ, Ọlọrun ko ni jẹ ki oun funrarẹ ṣubu tabi wo lulẹ ati pe ki Ọlọrun jẹ ko jere gbogbo rere to ti ṣe fun iya naa nigba aye rẹ.

“Mo dúpẹ́ pé ọjọ́ ìbí ọmọ mi ṣojú mi, wọn kò gbé mi gbìn"

Pasuma ati iya rẹ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àdúrà tí ìyà Pasuma gbà fún un kó tó papòdà rèé.

Ninu fidio ayẹyẹ ọjọ ibi Alabi Pasuma ti iya rẹ ba wọn peju nibẹ ni Alhaja Hadija Odetola ti n dupẹ lọwọ Ọlọrun pe oun dupẹ pe oun wa laye lọjọ ibi ọmọ oun bo tilẹ jẹ pe mama ti dagba.

Iya naa wa kẹnu bọ adura fun ọmọ rẹ Pasuma: “Ki Ọlọrun eledumare ko ba mi lọra ẹmi rẹ, ko ṣe 60, 70, 80 ninu alafia pipe ni ki Ọlọrun si ba mi fẹran gbogbo awọn to ba fẹran Pasuma”.

Iya naa ni ki Pasuma tunbọ maa ṣe daadaa to n ṣe lọ tori pe ere wa ninu rẹ, ki ọlọrun si ṣaanu oun ko jẹ ki Pasuma ju bẹẹ lọ ko ṣe ọpọlọpọ ọjọ ibi laye ninu ilera pipe.

O gbadura pe ki ọlọrun nifẹ gbogbo awọn to ba nifẹ Paso ati pe ohun ti onikaluku ba ro sii ni ki Ọlọrun fi san wọn lẹsan.

Iya Rainbow nile Pasuma

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Lara awọn akẹgbẹ rẹ ati ololufẹ rẹ to ti kan sii ti awọn eeyan n mẹnu ba ni gbajugbaja olorin Fuji mii, Saheed Osupa, olorin Sulaimon Alao Adekunle ti ọpọ mọ si Malaika.

Bakan naa, agba oṣere fiimu Yoruba, idowu Phillips naa jẹ bii iya ninu agbo oṣere tabi idanilaraya fun Pasuma, o wa lara awọn to kọkọ lọ si ile Pasuma lati lọ ba a kẹdun.

Ẹwẹ, ọpọlọpọ awọn gbajumọ oṣere Yoruba ni iroyin iku iya Pasuma ya lẹnu bẹẹ si ni ọpọlọpọ wọn ti bọ si ori ayelujara lati ba a kẹdun.