Wọ́n fi sísọ́ọ̀sì gún akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Ondo lọ́rùn pa torí N1000

Fasiti Adekunle Ajasin

Akẹkọ kan nile ẹkọ fasiti Adekunle Ajasin nilu Akungba-Akoko loti di ero ọrun lẹyin ti ọmọ ilu naa kan ti kii ṣe akẹkọ gun-un lọrun pa lana.

Níbi ìgbìyànjú láti báàyàn san gbèsè ni ìròyìn ní wọ́n ti gbẹ̀mí Akíntọ́lá lẹ́yìn ìdánwò àṣekágbá rẹ̀ ní fásitì. Ọrọ ẹgbẹrun kan naira pere lo da ohun to mu ẹmi akẹkọọ yii lọ.

Akẹkọ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Akintola Temitayo Ayodeji, ẹni ọdun mejilelogun, lo ti pari idanwo aṣekagba rẹ to si n duro lati gbe iṣẹ akanṣe aṣekagba (project) silẹ.

Amọ eyi ni ko lee waye mọ lẹyin ti awọn kan ti ran an lọrun aremabọ.

Oloogbe Akintola

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Lẹyin ti awọn akẹkọ ẹgbẹ rẹ gbọ nipa iku rẹ ni wọn bẹrẹ iwọde ifẹhonuhan ni agbegbe to ti ṣẹlẹ.

Nibi ti wọn ti ṣe iwọde yii, wọn gbegi dina awọn opopona kan ti wọn si n dana sun taya ọkọ ati igi laarin ọna.

Ibi ni awọn kan ti gbẹyin lọ dana sun ile awọn afunrasi to gun akẹkọ naa pa.

Igbyanju awọn ọlọpaa ati awọn adari akẹkọ ni fasiti naa ni wọn fi pa ina ọhun ti wọn si gbiyanju lati jẹ ki alaafia jọba.

Ki lo bi iṣẹlẹ yii gan?

Gẹgẹ bi alukoro awọn akẹkọ nile ẹkọ fasiti naa, Simbọ Akinṣulurẹ ti wi lakoko to ba BBC Yoruba sọrọ, Akintola lọ da si aawọ to nii ṣe pẹlu ọrọ owo laarin awọn meji kan.

Akinsulure ni “ẹnikan jẹ ọmọ ilu kan ni ẹgbẹrun mẹrin naira to si fa ariyanjiyan laarin wọn.

“Ọrọ yii ni Akintola da si to si gba lati san igbese ọhun ki wọn ye ba ara wọn ja.

“O ti san ẹgbẹrun mẹta ninu owo naa, to si ku ẹgbẹrun kan.”

Akinsulure ṣalaye siwaju sii pe ẹgbẹrun kan to ku ni wọn wa sin Akintola ninu ile rẹ ti ọrọ fi bẹyin yọ.

Alukoro awọn akẹkọ naa fi kun un pe “nibi ti wọn ti n fa ọrọ ni ọkan lara awọn to wa sinwo naa ti fi sisọọsi gun-un lẹyin ọrun.

“Kete naa ni wọn gbe lọ si ile iwosan nibi to ti dagbere faye.”

"Ohun táa mọ̀ rèé"

Ami idanimọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria

Oríṣun àwòrán, Google

Alukoro ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya ni awọn ṣi n wa afunrasi ọdaran naa, Damilola Adejumo, ẹni ọdun mejilelogun, to sa lọ lẹyin iṣẹlẹ ọhun.

Omisanya ni “ohun taa gbọ ni pe ariyanjiyan lori ọrọ owo ni wọn n ṣe ti Damilola fi gun Akintola lọrun ti wọn si sare gbe e lọ si ile iwosan nibi to ti dakẹ.

Ẹwẹ, Ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn ko fi ọrọ naa to awọn leti rara.

“Igba ti ariwo gba igboro tawọn akẹkọ bẹrẹ ifẹhonuhan ni a jade lati mọ ohun to n ṣẹlẹ taa fi gbọ pe niṣe ni wọn gun akẹkọ kan pa.”

Omisanya fi kun un pe awọn n ṣa gbogbo ipa lati rii pe alaafia pada jọba nilu naa ati pe gbogbo ọna ni awọn yoo gba lati rii pe ọwọ tẹ afunrasi ọdaran naa ni kiakia.