Mo ti pé ọdún tí àwọn Dókítà ní màá kú àmọ́ mo ṣì gbàgbọ́ nínú iṣẹ́ ìyanu – Fikayomi Aaron

Oríṣun àwòrán, Fikayomi Aaron
Arabinrin ọmọ orilẹede Naijiria kan ti Dokita ti sọ fun pe ko ni ọpọlọpọ ọdun lati lo mọ nile aye nitori ilera rẹ ti sọ pe oun nigbagbọ ninu “iṣẹ iyanu”.
Arabinrin naa to n jẹ Fikayomi Aaron lo n ba aisan ti oloyinbo n pe ni Heterotopic Ossification eyi to jẹ aisan to ṣakoba fun iṣan ara rẹ to si ti mu ki egungun rẹ le.
Ṣe ni ikun rẹ n tobi sii tori o tun ni awn aisan kan to n jẹ Peritoneal Calcification, Gross Ascites ati Hepatomegaly to maa n mu ikun tobi.
Iroyin taa gbọ ni pe kii ṣe bi wọn ṣe bi Fikayomi ni aworan tẹ n wo, aisan naa bẹrẹ nigba to wa lọmọ ọdun mẹwaa, o kọkọ dabii iju nibi bebedi rẹ ko to di pe o wọ de ọwọ rẹ.
“Ko sohun to lee mu mi sẹ agbara to wa ninu iṣẹ ami ati iyanu nitori bi mo ṣe wa laye lonii gan, iyanu ni.” Fikayomi sọ bẹẹ.
Nibayii, arabinrin yii ti pe ẹni ọdun 30, Fikayomi sọ pe ọpọ igba loun ti sunmọ akoko iku ati gbigbe igbesẹ lati pa ara rẹ.
Aisan to n ba a finra yii ti koba igbe aye rẹ to bẹẹ to jẹ wipe ko le rin, ko si lee ṣe awọn nnkan funrarẹ
Iya rẹ lo maa n ba a ṣe gbogbo nnkan latori rinrin titi de wiwẹ koda ati lati gbe kuro lori ibusun.
Aisan naa kii jẹ ko lee lo ọmọ ika rẹ tabi bẹrẹ ẹsẹ rẹ.
“Mo ṣi nigbagbọ pe mo ni ọjọ iwaju”
Bo tilẹ jẹ pe o ni ipenija ilera, ẹni ọgbọ ọdun yii ti ri ọpọlọpọ afojusun rẹ gbe ṣe.
“Onkọwe ni mi, mo si maa n gbe iwe sori ayelujara,” o rẹrin musẹ sọrọ.
Bakan naa, Fikayo ni oun ribi ko gbogbo iriri yii jọ nipasẹ imọ ẹkọ ori ayelujara ti oun n kopa ninu wọn ati awọn eto idanilẹkọ toun maa n lọ fun.
“Bo tilẹ jẹ pe mo ni idiwọ ṣugbọn mo gbagbọ pe mo ni ọjọ iwaju”.
Iru ọjọ iwaju ti Fikayomi n ri fun ara rẹ yii si ni lati maa nawọ iranwọ si awọn ọdọ nipa riran wọn lọwọ lati mọ idi ti Eleduwa fi da wọn saye.
Ki ni itumọ aisan Heterotopic Ossification?
Aisan Heterotopic ossification (HO) tumọ si wipe egungun eeyan n dagba ninu tissu ẹya ara lapa ibi ti ko yẹ ko dagba si.
Iru awọn egungun yii maa jẹ ohun ti oloyinbo n pe “extraskeletal bone”.
Wọn saba maa n farahan nigba ti eeyan ba fi ara pa. Ṣugbọn o tun lee ṣẹlẹ lai ni idi kankan.
Iru ẹya aisan to n ṣe Fikayomi yii ni eyi ti wọn n pe ni “Nongenetic” eyi to maa n ṣe ẹnikẹni lai ka ọjọ ori wọn si.
Igba mii, o maa n jẹ nitori idamu ti eeyan n la kọja, o lee jẹ ifarapa tabi idamu latari iṣẹ abẹ.
Aisan yii maa n jẹ eyi to buru jai to si maa n ni ipa ti ko dara lagọ ara ẹni to n ṣe.















