Ìdí tí a ṣe pawọ́pọ̀ pẹ̀lú PDP láti gbé Makinde wọlé fún sáà kejì rèé - Accord

Oríṣun àwòrán, Collage
Olùdíje sípò sẹ́nétọ̀ ẹkùn Oyo North ní ìpínlẹ̀ Oyo lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Accord, Shina Abiola Peller ti ṣàlàyé ìdí tí ẹgbẹ́ wọn ṣe pawọ́pọ̀ láti gbárùkù gómìnà Seyi Makinde fún sáà èkejì.
Peller ṣàlàyé àwọn ìdí yìí níbi ìpàdé àwọn lẹ́nulọ́rọ̀ ẹgbẹ́ Accord kan tó wáyé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ní ìlú Ibadan, olú ìlú ìpínlẹ̀ Oyo.
Aṣòfin náà tó ń ṣojú ẹkùn Iseyin/Itesiwaju/Iwajowa/Kajola ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin lọ́wọ́lọ́wọ́ ní òun àti àwọn àgbà ẹgbẹ́ kan fẹnukò láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Makinde lẹ́yìn tí ẹgbẹ́ àwọn kò rí ọwọ́ mú rárá níbi ètò ìdìbò sípò Ààrẹ àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀.
Ó fi kun pé èyí ló jẹ́ kí òun sọ fún olùdíje sípò gómìnà ẹgbẹ́ àwọn, Adebayo Adelabu pé kò sí bí yóò ṣe jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò náà nígbà tí àwọn kò rí ìbò sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kankan.
Ó ṣàlàyé pé èyí ló jẹ́ kí òun àtàwọn àgbà ẹgbẹ́ mìíràn ṣe pawọ́pọ̀ láti ṣe àtìlẹyìn fún gómìnà Seyi Makinde ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Bákan náà ló fi kun pé àjọṣepọ̀ náà wáyé lẹ́yìn tí àwọn se ìpàdé pẹ̀lú àwọn lọ́balọ́ba ní Oke Ogun.
Ìdàgbàsókè ẹkùn wa ló jẹ́ ka fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Makinde
Peller ní ìdí tí òun fi pe ìpàdé náà ni láti jíròrò lórí bí ẹgbẹ́ ṣe má tẹ̀síwájú nítorí àwọn ènìyàn ìlú kò máa dìbò fún ẹgbẹ́ mọ́ bíkòṣe àwọn ènìyàn gan-an.
"Gómìnà gbogbo ìlú ni gómìnà, a nílò láti foríkorí láti wá ọ̀nà ìtẹ̀síwájú fún ẹkùn wá."
"Láti àádọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn ni a tí ń béèrè fún ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ní Oke Ogun, Makinde fún wa ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ LAUTECH ní Iseyin."
"Mo gbàgbọ́ pé a ò ní kó àbámọ̀ pé a ṣe àtìlẹyìn fún Seyi Makinde, ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣe ìjọba tí yóò kó tolórí tẹlẹ́mù pọ̀, a sì nílò láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ fún ìtẹ̀síwájú ẹkùn wa.















