Àwọn aráàlú àti olórí wọn lé òbìnrin tí wọ́n fẹ̀sùn gbígba ọkọ ọlọ́kọ kàn jáde nílùú, Gómìnà dá sí ọ̀rọ̀

Aworan Orileede Burundi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gomina ẹkun ilu kan ni iha Ila Oorun-Ariwa orilẹede Burundi ti da si ọrọ to ṣẹlẹ bi olootu ilu kan ṣe gbe igbesẹ lati le obinrin kan to n gbe ni ilu naa jade kuro ni agbegbe wọn.

Awọn araalu lo fi ẹsun kan arabinrin naa pe o n gba ọkọ awọn.

Ninu lẹta kan ti olootu agbegbe Butihinda, Mayor Gilbert Ndikumasabo fọwọ si ni wọn ti fun obinrin naa ni gbedeke wakati mẹrinlelogun lati fi agbegbe wọn silẹ.

Lẹta yii gba gbogbo ori ayelujara kan ti awọn eeyan si bẹrẹ si ni sọrọ nipa rẹ.

“Fun iru iwa yii eyi to lee da igbeyawo ru, arabinrin naa gbudọ kuro ni agbegbe Butihinda lati ọjọ Keje oṣu kẹrin”, bo ṣe wa ninu lẹta olootu naa ree.

Awọn eeyan kan lori ayelujara ti bu ẹnu atẹ lu ipinu olootu yii nigba ti awọn mii kan sara sii gẹgẹ bo ṣe jẹ wipe aiṣootọ ati iyapa laarin lọkọlaya n wọpọ sii lọwọlọwọ laarin awọn eeyan Burundi.

Ẹwẹ, obinrin ti wọn n tọka si ninu lẹta yii ko ti sọrọ kankan gẹgẹ bi esi ni gbangba.

Wakati diẹ lẹyin ti lẹta naa bọ soju opo ayelujara ni Gomina ipinlẹ ti ẹkun Butihindi wa kede loju opo Twitter rẹ pe oun fagile ipinu olootu naa tori pe “ko tẹle ofin”.

Laipẹ yii, iyawo aarẹ orilẹede Burundi bu ẹnu atẹlu aiṣootọ ninu igbeyawo to si n tọka si awọn obinrin fun bi wọn ṣe n da igbeyawo ru.