Somalia Drought: Àìrọ̀ òjò fọ́dún márùn-ún fa ìyàn ńlá, ọ̀pọ̀ èèyàn, ẹranko àti irè oko kú
O ti to ọdun marun ti ojo ti kọ, ti ko rọ ni orilẹede Somalia.
Airọ ojo fun ọdun pipẹ yii si se okunfa iyan ati ọgbẹlẹ ni orilẹede naa.
Idi ree ti BBC fi gbe ikọ iwadii rẹ dide lati mọ ipa ti iyan ati ọgbẹlẹ naa n ni lori awọn orilẹede Somalia.
Iwadii BBC si se afihna pe ipo to ba ni lọkan jẹ ni awọn eeyan orilẹede naa wa bayii.
Koda, akọsilẹ ti fihan pe eeyan ẹgbẹrun mẹtalelogoji lo ti dagbere faye nitori iyan ati ọgbẹlẹ na.
Bakan naa ni ọpọ ohun ọsin ti ku, tawọn ire oko si ti jona mọlẹ eyi to n fa ọwọ gogo ebi ati iyan.
Baba kan to ba BBC sọrọ ni ebi lo pa iyawo ohun, ti oun si ko kuro ni agbegbe tawọn wa boya nnkan yoo tubọ sẹnu re amọ sibẹ, pabo lo n ja si.
O ni awọn ohun ọsin oun atawọn ire oko lo ti ku, ti awọn ko si mọ ohun ti awọn lee se mọ.
Ajọ isọkan orilẹede agbaye (United Nations) ni oun ti n gbe igbesẹ lati seto iranwọ fawọn eeyan orilẹede Somalia naa ti ebi ati iyan n ba finra.
Amọ o ni oun nilo owo to to biliọnu meji ati aabọ lati pese eto iranwọ naa.
Bakan naa ni ajọ UN kede pe ireti si wa pe awọn eeyan to to ẹgbẹrun lọna mẹrindinlogoji si tun seese ki wọn ba isẹlẹ iyan ati ọgbẹlẹ naa lọ lorilẹede Somalia.
Eyiun, bi ko ba si ipese iranlọwọ to yẹ fawọn eeyan orilẹede naa.