Erling Haaland ni agbábọ́ọ̀lù tó ta lẹ́nu jùlọ, tí ọjọ́ orí rẹ̀ tún kéré jù ní Premier League

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbabọọlu Manchester City, Erling Haaland, ti di agbabọọlu akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ agbabọọlu to ta lẹnu ju, ti ọjọ ori rẹ tun kere ni idije Premier League.
Ẹni ọdun mejilelogun naa sọ goolu mẹrindinlogoji sinu awọn ninu saa bọọlu kan, eyii to jẹ akọkọ iru rẹ ni idije Premier League.
Lapapọ, o ti sọ goolu mejilelaadọta sinu awọn.
Nigba to n sọrọ lori ami ẹyẹ naa, o ni “Inu mi dun lati jẹ agbabọọlu akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ mejeji ni saa kan ṣoṣo.”
“Ọpẹ mi pataki lọwọ gbogbo ẹyin ti ẹ dibo fun mi.”
Awọn araalu, to fi mọ igbimọ alaṣẹ Premier League lo dibo fun Haaland to fi gba ami ẹyẹ ọhun.
Ọdun to kọja ni agbabọọlu naa darapọ mọ Machester City lati ikọ agbabọọlu Borussia Dortmund, o si ti ran City lọwọ lati gba ife ẹyẹ mẹta ọtọtọ.
Yatọ si ami ẹyẹ yii, ẹgbẹ awọn akọroyin nipa ere idaraya, Football Writers' Association (FWA), tun ti kede rẹ bii agbabọọlu to dangajia julọ ninu ọdun yii.
O ni “Saa yii jẹ saa to yẹ wa ni Premier League, inu si dun gidi lati gbe ife ẹyẹ saa yii dani niwaju awọn ololufẹ wa ni papa iṣere Ethiad.”
Wayi o, City yoo koju Manchester United lọjọ kẹta, oṣu Kẹfa nibi aṣekagba idije FA cup.
Nigba ti yoo koju Inter Milan lọjọ kẹwaa, oṣu kan naa ni aṣegba idije Champions League.












