Lionel Messi yóò darapọ́ mọ́ Inter Miami ni ṣáà tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, Reuters
Atamatase ọmọ orilẹede Argentina, Lionel Messi ti gba lati darapọ mọ ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Inter Miami lẹyin to ba kuro ninu ikọ Paries St Germain ni saa yii.
Agbawọwaju ikọ Barcelona tẹlẹ ọhun ni o kọyin si owo jaburata ti wọn fi lọ lati ikọ Al Hilal lati orilẹede Saudi Arabia.
Adehun to kọwọbọ ọhun lo ni ibasepọ pẹlu ileeṣẹ Addidas ati Apple.
Messi, ọmọ ọgbọn ọdun gba ife ẹyẹ agbabọọlu to da julọ lagbaye fun igba meje, ti igbagbọ si wa pe yoo tun gba ti saa yii lẹyin to gba idije ife ẹyẹ agbaye fun ikọ Argentina.
Eyi ni igba akọkọ ti Messi yoo gba bọọlu ni ita ilẹ Europu.
O wu Messi lati lo ọdun kan si ni ilẹ Europu sugbọn gbogbo ipe to gba lati ọdọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu europu ni ko tẹ lọrun, to si ni lati mu laarin ikọ Inter Miami ati Al Hilal.
Ọpọ lo ti ro pe Messi yoo darapọ mọ ikọ Al Hilai lorilẹede Saudi Arabia ni bi ti yoo ti ma fi ẹgbẹkẹgbẹ pẹlu Cristiano Ronaldo ati Karim Benzema ninu ligi ilẹ naa.
Sugbọn Messi pinnu lati lọ si ilẹ Amẹrika fun ọpọlọpọ idi paapa julọ igbe aye wọn nibẹ ati ọpọlọpọ anfani to ju ti ere bọọlu lọ.
Messi ti ni ilẹ tẹlẹ ni Miami, to fun awọn ayale gbe.
Messi mi awọn ni mẹtalelọgbọ ninu ifẹsẹwọnsẹ mejileaadọrin to gba fun ikọ PSG, to si tun pari saa yii pẹlu goolu mẹrindinlogun ati iranlọwọ mẹrindinlogun.















