INEC yóò ná ₦239.2 bílíọ̀nù fún ètò ìdìbò àpapọ̀ 2023

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ajọ eleto idibo ni Naijiria, INEC ti sọ faye gbọ pe biliọnu marunlelọọdunrun Naira (₦305bn) ni owo ti eto idibo ọdun 2023 yoo naa ajọ naa.
O ni oojilenigba o dikan biliọnu Naira, (₦239.2 billion) ninu owo yii ni yo wa fun rira awọn ohun elo idibo at'awọn ọkọ fun eto idibo apapọ naa lorilẹede Naijiria lọdun 2023.
Ajọ INEC sọ eyi di mimọ lasiko ti fi n gbe akanṣe ilana eto idibo apapọ f'ọdun 2023 to pe ni '2023 General Election Project Plan' jade nilu Abuja, olu ilu Naijiria.
O ni ojilenigba o dikan biliọnu Naira, (₦239.2 billion) jẹ ida mejidinlọgọrin apapọ owoona fun eto idibo naa, yoo si wa fun rira iwe idibo, apoti idibo, sisan owo awọn oṣiṣẹ idibo, titẹ iwe esi idibo, ohun elo fun ayẹwo orukọ oludibo lasiko idibo at'awọnohun miran to ṣe pataki fun aṣeyọri idibo apapọ naa.
Bakan naa ni ajọ INEC to n ṣakoso eto idibo lorilẹede Naijiria tun jẹ ko di mimọ pe awọn ṣi biliọn mẹtadinlọgbọn Naira (₦27.1bn) mọ owo naa lati na fun atundi ibo, aibaamọ ti ọrọ ba bẹyin yọ to si nilo atundi ibo lati yanju rẹ.
Ninu atupalẹ owo yii, biliọnu marunlelọgọrun Naira (₦105.2bn) ni won yoo na fun fun awọn ohun elo ayẹwo orukọ oludibo nikan.
Owo ti wọn ya s'ọtọ fun sisan owo oṣiṣẹ oludibo jẹ biliọnu mẹtalilogun (₦23.7bn) ti awọn eroja ati eto miran bi irinna awọn oṣiṣẹ ajọ naa, pinpin awọn oṣiṣẹ ati ohun elo idibo kaakiri, yoo ko bilionu metalelogun Naira (₦23bn) hanu.
Ẹwẹ, Ogun biliọnu Naira, (₦20.6bn) ni ajọ INEC yoo na lori titẹ iwe idibo, titẹ iwe esi idibo yoo gbe biliọnu mẹsan abọ Naira (₦9.5bn) hanu, apoti idibo yoo ko biliọnu mẹjọ Naira din diẹ (₦7.8bn), ki wọn to tun na biliọnu mẹrin din diẹ Naira, (₦3.9bn) fun rira ọkọ ti wọn yoo fi ṣiṣẹ lasiko idibo naa.
Alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ṣalaye pe lootọ biliọnu mọkandinlaadọwa Naira, (₦189bn) ni wọn naa fun eto idibo apapọ ọdun 2019 eleyi to kere pupọ si biliọnu marunlelọọdunrun Naira (₦305bn) ti wọn fẹ na lọdun 2023.
O ni lara awọn ohun to ṣokunfa eyi naa ni bi iye awọn oludibo to forukọsilẹ lati dibo ṣe ti fo fẹrẹ kuro ni miliọnu mẹrinlelọgọrin to wa lọdun 2019 si nnkan bii ọgọrun miliọnu lọdun 2023.
Ọjọgbọn Mahmood Yakubu tun fi kun un pe ibudo idibo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọgọfa, (119, 973) si ẹgbẹrun mẹtadinlọgọsan din diẹ, (176, 846) ti ọkọọkan oludibo yoo si naa dọla meje o le ($7.38) diẹ si dọla marun le ($5.39) lọdun 2023.
Ko s'ohun ti yoo di eto idibo 2023 lọna - INEC
Bakan naa, lajọ ọhun tun fohun silẹ pe ko si bi ọrọ abo ṣe dojuru to ni Naijiria, eto idibo apapọ ọdun 2023 yoo waye.
Ọpọ awọn eekan ati majẹkobajẹ lorilẹede Naijiria ni wọn ti n fi aibalẹ ọkan wọn han lẹnu lọwọlọwọ yii lori boya eto idibo ọdun 2023 yoo lee ṣeeṣe, ti wọn si n mu oniruuru aba jade gẹgẹ bi ọna abayọ.
Lara awọn ohun to si n kọ awọn agbaagba wọnyi lominu ni ọrọ abo to n mẹhẹ lorilẹede Naijiria, paapaajulọ lẹkun ila oorun gusu Naijiria ati iwọ oorun ariwa pẹlu awọn kudiẹkudiẹ to n jẹyọ labẹ iwe ofin Naijiria.
Amoṣa, alaga ajọ eleto idibo Naijiria, INEC ti jẹ ko di mimọ pe eto abo to mẹhẹ ko lee da eto idibo naa duro.
O ni kii ṣe pe ajọ naa ko mọ bi ọrọ ṣe n lọ lẹka yii, ṣugbọn ijiroro ti n lọ pẹlawọn ajọ ati ileeṣẹ eleto abo gbo ni Naijiria lọna ati rii pe ipenija abo ko di aṣeyọri eto idibo apapọ naa lọwọ biotiwulẹ ko mọ.
O ni nnkan bii miliọnu oṣiṣẹ ni wọn yoo da sita lasiko idibo naa kaakiri ibudo idibo ẹgbẹrun mẹtadinlọgọsan din diẹ, (176, 846) ni ẹgbẹrun mẹsan din diẹ wọọdu (8, 809) ati ọrinlelẹẹdẹgbẹrin o din mẹfa (774) ijọba ibilẹ, lorilẹede Naijiria.
Idibo apapọ lorilẹede Naijiria leto idibo ti idibo lati yan awọn oloṣelu si aga ẹgbẹrun kan din meje (993) lawọn ile igbimọ asofin ipinlẹ, Ipo aarẹ, aga mọkandinlaadọfa (109) nile aṣofin agba, ọtalelọọdunrun (360) aga aṣojuṣofin ati ipo gomina ipinlẹ mejidinlọgbọn ninu ipinlẹ mẹrẹẹrindinlogoji to wa lorilẹede Naijiria ti maa n waye.
















