Abacha loot: Wọ́n tún ṣàwárí ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó tí Abacha jí kó ní UK

Oríṣun àwòrán, others
Àjọ tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn ní orílẹ̀ èdè United Kingdom (NCA) ní àwọn tí ṣàwárí owó tabua tí ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́tàlélógún dọ́là tó jẹ́ lára owó tí olórí orílẹ̀ èdè yìí tẹ́lẹ̀ rí, Sani Abacha jí kó kúrò ní Nàìjíríà.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí àjọ náà fi léde lọ́jọ́bọ̀ ní owó náà wà lára owó tí ẹ̀ka ètò ìdájọ́ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tọ́ka sí wí pé Abacha àti àwọn mọ̀lẹ́bí jí kó gba oko ibòmíràn lọ.
NCA ṣàlàyé pé àwọn tí tarí owó náà sí oríkò àjọ náà láti lè fi ṣọwọ́ sí ẹ̀ka ètò ìdájọ́ Amẹ́ríkà.
Alákóso ẹ̀ka ohun ìní àjọ NCA, Billy Beattie sọ àrídájú rẹ̀ ipa tí àjọ náà ń kó láti dènà ṣíṣe owó kúmọkùmọ ní orílẹ̀ èdè UK.
Beattie ní NCA ní ìfarajìn sí ríri dájú pé àwọn ọ̀daràn kò máa sọ UK di ibi tí wọ́n yóò máa kó gbogbo ohun tí wọ́n bá jí kó ní orílẹ̀ èdè wọn sí, tó sì ní ṣiṣẹ́ àwárí àti gbígba àwọn dúkìá padà jẹ́ èròjà kan gbòógì láti ja ìjà náà.
Bákan náà ló fi kun pé àwọn ń ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ìjọba UK àti àwọn lájọlájọ ilẹ̀ òkèèrè láti gbógunti ìwà àjẹbánu èyí tó ń kó ìpalára bá àwọn mẹ̀kúnù.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí wọ́n yóò rí owó tí Abacha jí kó padà
Láti ọdún 1998 tí Abacha ti papòdà, orílẹ̀ èdè mẹ́rin gbòógì ni wọ́n ti ṣàwárí àwọn owó tó jí kó pamọ́ nígbà tó wà lórí oyè gẹ́gẹ́ bí olórí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Lára wọn ni Switzerland, Jersey Island ní United Kingdom, United States àti Liechtenstein.
Nígbà tí Abdulsalami Abubakar wà lórí oyè lọ́dún 1999 mílíọ̀nù 750 dọ́là ni wọ́n rí gbà.
Bákan náà ni wọ́n rí bílíọ̀nù kan lé ọwọ́ méjì dọ́là gbà padà ní ọdún 2002, mílíọ̀nù mọ́kàndínláàdọ́jọ ni ìjọba Nàìjíríà rí gbà ní Jersey Island, UK lọ́dún 2023 àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ nígbà ìṣèjọba Olusegun Obasanjo.
Nígbà ìjọba Goodluck Jonathan, owó tó lé ní bílíọ̀nù kan dọ́là ni ìjọba rí gbà lọ́dún 2012 àti 2015 láti Switzerland.













