Abacha: Ohun mẹ́fà tí Abacha fi tún ìwé ìtàn Nàìjíríà kọ

Ọ̀gágun àgbà Sani Abacha

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Aisan ọkan ni wọn sọ pe, o pa Ọ̀gágun àgbà Sani Abacha

O pe ogún ọdun loni ti olori ijọba ologun lorilẹ-ede Naijiria nigbakan ri, Ọgagun agba Sani Abacha jade laye

Laifọtape, eniyan ko fẹrẹ jayopa lati sọ pe Ọgagun agba Sani Abacha fẹrẹ jẹ olori ijọba Naijiria ti agbaye sọrọ rẹ julọ.

Lẹyin wahala ibo ọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun 1993 ni Ọgagun agba Sani Abacha, wọle nigba to yẹ aga mọ ijọba fidihẹ Oloye Earnest Ṣonẹkan nidi ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 1993.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Laarin ọdun 1993 si ọdun 1998 ti Ọgagun agba Sani Abacha fi wa lori aga iṣejọba orilẹ-ede Naijiria, ọpọlọpọ nnkan lo ṣẹlẹ to jẹ ki awọn onwoye sọ pe o ni ipa lara eto iṣelu orilẹ-ede Naijiria.

Atupalẹ diẹ lara awọn igbesẹ Ọgagun agba Sani Abacha ati ipa wọn lori eto iṣelu orilẹ-ede Naijiria.

Ipade apero lori iwe ilana ofin (Sovereign Constitutional Conference)

Sani Abacha n ki Poopu ijọ aguda kaabọ silu Abuja

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Laarin asiko ti Sani Abacha fi wa lori oye, ọpọlọpọ nnkan lo ṣẹlẹ eleyii ti awọn onwoye sọ pe o ni ipa lara eto iṣelu orilẹ-ede Naijiria.

Irinwo awọn aṣoju ti wọn yan kaakiri ibu ati oro orilẹ-ede Naijiria ni wọn kopa ninu ipade apero yii laarin ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 1994 si ọdun 1995 eyi to wa fun agbekalẹ iwe ofin tuntun fun orilẹ-ede Naijiria nigba naa.

Ọpọ awọn onwoye ọrọ oṣelu ni wọn foju wo ipade apero yii gẹgẹ bii eyi to dara pupọ kani wọn ṣe amulo awọn abajade rẹ kan ni.

Fifi MKO Abiọla si ahamọ

MKO Abiọla

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ahamọ Abacha ni MKO Abiọla wa titi to fi jade laye ni ọdun 1998

Ijọba ologun, labẹ Ọgagun agba Sani Abacha lo fi MKO Abiọla si atimọle ni ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹfa, ọdun 1994 nigba ti Abiọla kede ara rẹ gẹgẹ bii aarẹ orilẹ-ede Naijiria ni ọjọ kọkanla, oṣu kejila, ọdun 1994.

Ìjọba ologun labe Ibrahim Babangida wọgile esi idibo oṣu kẹfa ọdun 1993 ninu eyi ti MKO Abiọla ti ko pa gẹgẹ bii oludije ipo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu SDP.

Ahamọ yii ni MKO Abiọla wa titi to fi jade laye ni ọjọ keje, koṣu keje, ọdun 1998.

Yiyẹgi fun Ken Saro Wiwa atawọn ajafẹtọ agbegbe ogoni mẹjọ

Awọn oluwọde lori iku Ken saro Wiwa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Bọla Ige ṣe akawe awọn ẹgbẹ oṣelu ti Abacha da silẹ gẹgẹ bii, 'ọmọ ika marun ọwọ adẹtẹ.'

Ni ọjọ kẹwa, oṣu kọkanla, ọdun 1995 ni wọn yẹgi fun gbajugbaja onkọwe ati ajafẹtọ ọrọ ayika lẹkun Niger-Delta, Ken Saro Wiwa, atawọn akẹgbẹ rẹ mẹjọ ti wọn ja fun atunṣe agbegbe ogoni nibi ti iṣẹ epo rọbi wiwa ti da wahala alailẹgbẹ si igbaye-gbadun awọn olugbe ibẹ.

Eleyi fa ọpọlọpọ ariwo kaakiri agbaye, eyi to fa oniruuru igbesẹ inira lati awujọ agbaye gbogbo.

Idasilẹ ẹgbẹ oṣelu marun ati ipinnu lati di oludije kan ṣoṣo fun wọn

Olori awọn ẹṣọ Sani Abacha, Almustapha pẹlu ọkan lara awọn ẹṣọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ipinlẹ Ebonyi, Ekiti, Bayelsa, Nasarawa, Zamfara ati Gombe ni Sani Abacha da silẹ

Ni ọgbọn ọjọ, oṣu kẹsan, ọdun 1996 ni ajọ eleto idibo igba naa NECON fi orukọ ẹgbẹ oṣelu marun silẹ.

Awọn ẹgbẹ oṣelu marun yii gba lati yan Ọgagun agba Sani Abacha gẹgẹ bii oludije fun ipo aarẹ labẹ aṣia wọn.

Igba yii gan an ni oloogbe Bọla Ige ṣe akawe wọn gẹgẹ bii, 'ọmọ ika marun ọwọ adẹtẹ.'

Ṣiṣigun le awọn ẹgbẹ alatako

Ọjọgbọn Wọle Soyinka ati amofin Fẹmi Falana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ni ọgbọn ọjọ, oṣu kẹsan, ọdun 1996 ni ajọ eleto idibo igba naa, NECON, fi orukọ ẹgbẹ oṣelu marun silẹ

Lasiko iṣejọba Ọgagun agba Sani Abacha, ọpọ awọn ẹgbẹ alatako lo fara kaaṣa ibinu ati ikọlu rẹ.

Awọn ẹgbẹ bii NADECO ati ẹgbẹ oṣiṣẹ ni ijọba ologun ṣigun lu bẹẹni ọta ibọn ati ado oloro awọn agbenipa ṣọṣẹ lara Abraham Adesanya, Kudirat Abiọla, Alex Ibru, Shọla Omatṣọla ati bẹẹbẹẹ lọ.

Abraham Adesanya ati Alex Ibru ye ikọlu ti wọn ṣugbọn Kudirat Abiọla ati Ọmatsọla ko yee.

Idasilẹ ipinlẹ mẹfa

Lasiko ọdun bii marun to lo lori aga aarẹ lorilẹ-ede Naijiria, Ọgagun agba Sani Abacha ṣe idasilẹ awọn ipinlẹ mẹfa tuntun kan ojọ kinni, oṣu kẹwaa, ọdun 1996.

Awọn ipinlẹ naa ni Ebonyi, Ekiti, Bayelsa, Nasarawa, Zamfara ati Gombe.