Pastor Noah Abraham: Bí ọkọ́ mi tó jẹ́ igbákejì G.O wa ṣe kó Ọlọ́pàá wá mú wa tó ní ki ń máà padà bọ̀ nílé - Ọmọ ìjọ
'Inú mi dùn lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nígbà tí Ọlọ́run sọ̀rọ̀ jáde pé kí n bèrè N310,000 lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ ti Kaduna".
Lakọkọ, Pasitọ Abraham ni "were eniyan lo le sọ wipe ẹ wa maa sanwo ọkọ ti mo maa fi koo yin lọ sọrun".
Eyi ni Pasitọ naa kọkọ sọ fun wa to si ni oun rẹrin nigba ti oun kọkọ gbọ pe ọmọ ijọ kan fi ẹsun kan oun pe oun ni ki wọn san iye owo N310,000 ti oun yoo fi ko wọn lọ si ọrun to si jẹ pe ọpọ wọn o tilẹ ri owo jẹun.

Oríṣun àwòrán, Yetunde Olugbenga
BBC Yoruba lọ si ilu Omuo-Ekiti lati gbọ latẹnu Pasitọ Noah Abraham gangan funra rẹ.
O ṣalaye pe ijọ ti oun da silẹ wa ni ilu Kaduna tẹlẹ amọ ti oun ko wa si ipinlẹ Ekiti to jẹ ilu tirẹ to si ko ọpọlọpọ awọn ọmọ ijọ dani paapaa awọn ti o n ṣe bii baba fun ti wọn ko ni orule kankan lori.
O ni oun tun ko awọn ọmọ wọn si ileewe nilu Ekiti lai gba kọbọ lọwọ awọn ọmọ ijọ ọhun.
Irọ ni wọn pa o, mo kan fi owo naa dan wọn wo ni

Bo tilẹ jẹ pe Pasitọ Noah Abraham sọ pe lootọ ni Ọlọrun sọ fun oun nipa ọrọ N310,000 amọ o ṣalaye.
"Igba ti awọn ọmọ ijọ ti Kaduna gbọ pe a n ṣe isin nibi ni wọn wa nifẹ lati darapọ mọ wa, mi o si ṣe iru ẹ ri, mo wa sọ fun Ọlọrun, igba naa ni Ọlọrun sọ fun mi pe ki n fi dan igbagbọ wọn wo nipa sisọ fun wọn pe bi wọn ba fẹ wa ki wọn san ẹgbẹrun lọna ọọdurun o le mẹwa naira pe maa si ko wọn lọ si ọrun".
Arabinrin kan Folashade Orilede to ni ọkọ oun lo n dari ijọ ti Kaduna nigba ti Pasitọ kuro ṣalaye pe nigba to di ọjọ kan ni ọkọ oun dede ni ilu Kaduna ya to si ya oun lẹnu.
Koda o ni ọkọ lo wa ọna ati eto bi gbogbo awọn ṣe ba Pasitọ agba wa si ilu Ekiti nigba ti oun (ọkọ) n dari ijọ ti Kaduna.
O ni o yẹ ko wa darapọ mọ awọn ni ọjọ Ẹti gẹgẹ bi Pasitọ ṣe sọ fun ọkọ oun.
"Mo wa nibi pẹlu ọmọ mẹta ti a jọ wa, ọkọ mi wa ni ki bẹrẹ si ni pada wa si Kaduna pẹlu awọn ọmọ yẹn mi o dẹ mọ idi".
O ni ọkọ oun ko sọ idi kankan fun oun to fi ṣe bẹẹ afi to di bii ọjọ marun sẹyin ọjọ ti a baa sọrọ to ni ọkọ oun kan de "pẹlu awọn ọlọpaa lati wa ko wa lọ si agọ ọlọpaa pe wọn fẹ gbọ tẹnu wa".

Amọ iyawo ni oun sọ fun awọn ọlọpaa pe oun yoo lọ amọ lẹyin ipagọ ni.
Ọkan lara awọn ọmọ ijọ ti oun naa fẹ da bii ara awọn adari ijọ sọrọ nipa bi Pasitọ wọn ṣe n gbe gbogbo ọrọ lọ siwaju Ọlọrun ko to sọ fun awọn ọmọ ijọ.

'Ààfin ńlá yóò sọ̀kalẹ̀ látọ̀run sí Omuo-Ekiti tí gbogbo àgbáyé kódà America yóò wá láti wá forí balẹ̀'
O jẹri pe ilu nla nni kan wa ti gbogbo awọn ati gbogbo agbaye yoo pada wa eyi to wa ni Omuo Ekiti.
"Ọlọrun sọ fun mi pe gbogbo wọn kọ lo "serious" wọn a kan wa jẹ ẹru fun mi nibi ni, Ọlọrun wa ni ki n sọ fun

