Laide Bakare: Mo ra mọ́tò bọ̀gìnì, inú ń bí àwọn ọ̀tá mi, mo ní ìdáhùn yín lọ́wọ́ ńbí

Oṣere Laide Bakare ati Eniola Badmus

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Laipẹ yii ni gbajugbaja oṣere Nollywood, Laide Bakare ra ọkọ bọgini meji, iyẹn Toyota ati Lexus, lẹyin ọsẹ diẹ to ṣi ile nla awoṣifila kan.

Laide Bakare kọ ọ si ori ẹrọ Instagram rẹ pe, asiko ti to lati gbadun aye oun lẹyin iṣẹ karakara fun ọpọlọpọ ọdun.

Ninu akọjade naa ni Bakare ti ni pe oun ko ṣe eyi lati pẹgan awọn to ku, amọ lati mu iwuri ba awọn obinrin pe ko si ẹni ti ko lee ṣe oriire.

Àkọlé fídíò, 'Gbogbo àgbáyé kódà America ló ń bọ̀ wá sí Omuo-Ekiti láti wá forí balẹ̀ ní Ààfin ńlá tí yóò sọ̀kalẹ̀ látọ̀run'

Pẹlẹ ooo Iya Larinlọrdu - Eniola Badmus si Laide Bakare

Laide Bakare

Oríṣun àwòrán, Laide Bakare

Eyi ti Laide kọ ko tii balẹ tan ti ọkan lara awọn oṣerebinrin to jẹ akẹgbẹ rẹ, Eniola Badmus fesi loju opo naa to si kii ku oriire gẹgẹ bi iya onile.

Bi o tilẹ jẹ pe ọrọ naa ko ṣafihan boya inu rẹ dun si abi bẹẹ kọ, esi ti Laide Bakare daa pada lo jẹ ki awọn eniyan bẹrẹ si ni sọrọ nipa iṣẹlẹ ọhun lori ẹrọ ayelujara.

Eniola Badmus ni ''pẹlẹ ooo Iya Larinlọọdu.''

Amọ kete ni Laide Bakare ti fun Badmus lesi pada pe oun gangan ni olori awọn to n ṣe ilara oun, ti oun ko si raye fun awọn ọta.

Ninu esi ti Laide Bakare fun Eniola Badmus lo ti ni oun gan an ni olori awọn ọlọtẹ to n ditẹ mọ oun.

Laide Bakare

Oríṣun àwòrán, Laide Bakare

Bakan naa lo fikun un pe ibẹrẹ ohun rere niyii fun oun ati wipe esi ti oun yoo ma fun awọn ọta oun ni igbega ninu igbega.

Oṣerebinrin naa ni oun ko ni aye rara fun awọn ọta oun ati awọn onilara.

''Eniola Badmus, emi niyẹn o, aarẹ awọn ọlọtẹ. Iwọ lo sọ ero ọkan wọn. Oluwa lo ṣe eyi kii ṣe eniyan, ibẹrẹ ohun rere si ni yii fun mi ni aṣẹ Allah. Ṣebi ẹ n ṣe ilara mi ni, igbega ninu igbega ni esi mi fun yin. Emi o raye awọn ọta mi jare."

Àkọlé fídíò, Ó gbé owó fún mi, ó tún ra fóònù ńlá fún mi - Bàbá Onílù Ibadan sọ bó ṣe pàde Àgùnbánirọ̀ tó dáa lọ́lá

Amọ lẹyin eyi ni Eniola Badmus fesi pe ere lasan ni oun ṣe, ti ohun ko si ni ohunkohun lọkan tako Laide Bakare.

Badmus ni ati igba ti awọn ti wa ni ile ẹkọ giga fasiti ni oun ti fẹran rẹ, pe ko si ohun bẹẹ ni aarin wọn.

Lo ba kesi Laide Bakare lati ṣọra fun ere gele nitori oun ko ro ibi sii rara.

Oṣu meji sẹyin ni gbajugbaja oṣerebinrin Laide Bakare ṣi ile nla tuntun.