Soun Ogbomoso: Ọkùnrin kan kọlu Ààfin Soun, ó ba dúkìá jẹ́

Ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Bukola Adediji, ti ọpọ mọ si Ajanlekoko ti ṣekọlu si aafin Soun ti ilu Ogbomoso, nibi to ti ba awọn dukia kan jẹ.
Iroyin ni okunrin naa, to ni arun ọpọlọ fi ẹṣẹ yọ eyin meji lẹnu ọkan lara awọn oloye to gbiyanju lati dẹkun rẹ lasiko ikọlu ọhun.
Akọwe aafin Ṣoun, Toyin Ajamu lo fidi iroyin naa mulẹ fun BBC Yoruba.
- Òkú obìnrin yìí kan ìlẹ̀kùn pósí gbà-gbà-gbà pé òun ò kú lọ́jọ́ ìsìnkú rẹ̀! Kàyéfì tuntun
- Ọkùnrin tó bá ọmọ ọdún 17 lòpọ́, tí ọmọ náà sì padà kú d'èrò àtìmọ́lé
- 'Ẹ yẹgi fún un'! Ọkùnrin ẹni ọdún 42 gba ìdájọ́ ikú lẹ́yìn tó pa Ọba aládé l'Ekiti
- Wo ǹkan 21 tó yẹ kí obìnrin mọ̀ nípa ojú abẹ́ rẹ̀, Vagina
- Kí ló fa gbas-gbos láàrín àwọn òṣèrébìnrin méjì, Laide Bakare àti Eniola Badmus?
- A kò mọ pásítọ̀ tó fẹ́ kó ọmọ ìjọ rẹ̀ lọ sí ọ̀run rí – CAN
- Ikú àwọn Sójà tọkọ-taya tí wọ́n gé lórí kò yẹ àwùjọ ọmọ ènìyàn rárá - Ààrẹ́ Buhari
- Ọmọ orílẹ̀èdè Lebanon tó gba 'One way' l'Eko fi ọkọ̀ fọ́ ẹsẹ̀ obìrin kan
- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ti sọ ìgbésẹ̀ tuntun tí wọ́n fẹ́ gbé nípa ẹ̀sùn àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ajá
Gẹgẹ bii ohun to sọ, kii ṣe igba akọkọ ree ri okunrin naa yoo kọlu aafin Soun.
O ni o ni kọkọ kọlu aafin naa lọdun to kọja ti wọn fi ṣikun ofin mu ki wọn to gbe lọ sile iwaosan awọn alarun ọpọlọ.
O ni "Igba ti wọn mu, awọn mọlẹbi rẹ wa, wọn si gbe lọ sile iwosan awọn alaarun ọpọlọ."
Nigba ti wọn ge de ibẹ ni a ṣawari pe o ni kaadi nibẹ, to n tumọ si pe kii ṣe ajoji nile iwosan ọhun."
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, Adediji, to n gbe ni apa iha Ariwa Naijiria tẹlẹ wa si Ogbomoso lẹyin ti o bẹrẹ si n ṣaarẹ ọpọlọ.
Ọgbẹni Ajamu sọ pe okunrin naa ko ji ade ọba lọ laafin gẹgẹ bii iroyin ti awọn eeyan kan n gbe kiri.
O fi kun pe okunrin ọhun kii ṣe mọlẹbi ọba, kii si si ṣe ọmọ ọba.
O ni "Ko wa lati ile ọba kankan."
"O ti kọkọ gbiyanju irufẹ nnkan bayii ri amọ wọn gbe kuro lafin lọ si ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun Bowen nitori o farapa lasiko naa."
"Ibẹ ni wọn ti ṣawari pe onibara wọn ni."
Lẹyin naa lo ni ki awọn araalu ma naani iroyin to ni okunrin naa ji ade ọba gbe lọ.















