Alaafin Palace Lamidi Adeyemi: Wo àwọn obìnrin mẹ́wàá tí ipa wọn kò ṣe fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ní ààfin Oyo

Alaafin atawọn ayaba nidi igba titi

Oríṣun àwòrán, Alaafin oyo

Ní ilẹ̀ Adúláwọ̀, àwọn kan gbàgbọ́ wí pé àwọn obìnrin kò ní ojúṣe kan gbòógì tí wọ́n dì mú nínú àwùjọ yàtọ̀ sí jíjẹ́ ìyàwó ilé lásán, dáná àti títọ́jú ọmọ.

Ṣé báyìí ni ọ̀rọ̀ ṣe rí ní àwùjọ Yorùbá nítorí àwọn àṣamọ̀ kan pé ìyàrá ìdànà ni gbogbo ẹ̀kọ́ tí ọmọ obìnrin bá ní máa ń parí sí.

Ní Oyo Aláàfin òjò pa ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ọmọ Àtìbà, àwọn obìnrin mẹ́wàá ló ní ojúṣe pàtàkì tí wọ́n ń kó nínú ààfin.

Àwọn obìnrin náà nìyí:

Iyamode: Ẹnikẹ́ni tó bá wà ní ipò yìí nìkan ni àṣà Yorùbá fi àyè gbà pé kí Aláàfin ìlú Oyo kúnlẹ̀ fún. Ipò náà jẹ́ èyí tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún púpọ̀ ní ìlú Oyo tó fi jẹ́ pé Bàba ni Aláàfin máa ń pè é.

Tí Aláàfin bá ti ń lọlẹ̀ láti kúnlẹ̀ fún Aláàfin náà ni obìnrin yìí náà ni òun náà yóò fi ìkúnlẹ̀ pàdé Aláàfin tí ìyá yìí kò sì fi ọwọ́ rẹ̀ lélẹ̀ nítorí èyí jẹ́ àmì bí àwọn obìnrin ṣe máa ń bọ̀wọ̀ fún ẹni tí ó bá jùwọ́n lọ.

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua

Ní kété tí obìnrin bá ti jẹ Iyamode, kò gbọdọ̀ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin kankan mọ́ títí yóò fi jáde láyé, òun sì ni àgbà fún gbogbo àwọn obìnrin tó bá wà láàfin tí wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ní ìbálòpọ̀.

Bákan náà ló jẹ́ ọ̀kan lára àgbà àwọn obìnrin tó jẹ́ aláwo nínú ààfin Oyo.

Àkọlé fídíò, Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji

Ọbaguntẹ: Òun ni ó máa ń ṣojú Aláàfin níbi ètò àwọn Ògbóni. Obìrin tó bá wà ní ipò yìí ní ẹ̀tọ́ sí gbogbo ètò tí àwọn Ológbàni bá ń ṣe tó sì lè wọ yẹ̀wù wọn nígbàkúgbà.

Ẹni Ọja: Òun ni olórí àwọn tó ń bọ Èṣù, òun sì ló wà ní ìkápá ọjà Ọba.

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere

Iya Naso: Aláàfin Oyo ni ìgbàgbọ́ wà pé ó jẹ́ aṣojú Sango ní ilẹ̀ Yorùbá. Ní ààfin Oyo, ibì kan wà tó jẹ́ pé Aláàfin máa ń bọ Sango níbẹ̀, Iya Naso ló wà ní àkóso yàrá yìí.

Bákan náà ló wà ní ìdí àmójútó gbogbo ohun tó ní ṣe pẹ̀lú bíbọ Sango àti ètò rẹ̀ gbogbo.

Iya Kere: Ìyá Kere ló máa ń gbé adé sí orí Aláàfin ní ọjọ́ tí wọ́n bá ń ṣe ìwúyè. Òun ló wà nídìí àkóso gbogbo àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ìlú Oyo tó fi mọ́ àwọn adé.

Iya Kere ni olórí gbogbo àwọn Ilari inú ààfin, tó sì tún ní agbára lórí àwọn ìlú tó wà ní abẹ́ Oyo bíi Aseyin, Oluwo àti Soun ti ìlú Ogbomoso.

Ẹnikẹ́ni tó bá ti jẹ Iya Kere kìí súnmọ́ ọkùnrin mọ́ títí láé.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

Iya Ọba: Ẹni tó bá bí Ọba ló máa ń wà ní ipò yìí àmọ́ tí Ọba kò bá ní ìyá mọ́ láyé, wọ́n á yan ẹnìkan nínú àwọn àgbà obìnrin ilé láti gba ipò náà.

Ìyá Ọba ló máa ń ṣe ẹnì kẹta Aláàfin àti Basorun nínú yàrá nígbà tí wọ́n bá ń ṣọdún Orun nínú oṣù Kẹsàn-án ọdọọdún. Iya Ọba ni olórí fún Basorun.

Àkọlé fídíò, Babalawo, Ọ̀pẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fi ń yan Ọba fún wa, kí ló dé tẹ́ẹ fẹ́ wo owó yan Soun fún wa? - Ọmọ ìdílé òyè l'Ogbomoso

Iya Monari: Iṣẹ́ Iya Monari ni láti yí ẹni tó bá ń bọ Sango tí wọ́n wá dájọ́ ikú fún lọ́rùn pa nítorí wọ́n kìí fi idà pa ẹni tí Sango bá dájọ́ ikú fún.

Bákan náà ló jẹ́ igbákejì Iya Naso.

Iya-Fin-Iku: Ìṣe àwọn Oníṣàǹgó ni láti máa fi ẹnìkan jìn sí bíbọ Sango, ipa yìí sì ni Iya-Fin-Iku máa ń kó fún Aláàfin.

Òun náà ló wà ní àkóso àgbò tí wọ́n fi ń bọ Sango.

Àkọlé fídíò, Adewole Quyum: Ọdún10 ni mo ti ń kọ́ 'welder' mo ti ṣe ọ̀kadà tó ń lo 'generator'

Iya Lagbo: Ẹni tó bá jẹ ìyá Àrẹ̀mọ ló máa ń wà ní ipò yìí ṣùgbọ́n tí ìyá Àrẹ̀mọ bá ti papòdà, obìnrin olorì mìíràn yóò gba ipò náà.

Iya Lagbo máa ń ṣàkóso apá kan ní ààfin tó sì máa ń wà ní ìṣàkóso gbogbo àgbo àti àgúnmu gbogbo àwọn ènìyàn tó wà ní ààfin tó fi mọ́ Aláàfin.

Àkọlé fídíò, Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe- Afusat Adeniyi tó ń tún 'Pumping Machine'

Aarẹ Oriitẹ: Òun ló jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì sí Aláàfi, tó máa ń ṣe àkóso gbogbo oúnjẹ àti ibùsùn Aláàfin. Ṣe ìtọ́jú gbogbo àyíká, tó sì máa ń gbé agbòrùn lórí àwọn aláàfin tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ.

Gbogbo àwọn obìnrin mẹ́wẹ́ẹ̀wá yìí ló máa ń rọgba ká Aláàfin láti ri pé kò ṣi ẹsẹ̀ gbé.