Elon Musk: Twitter ti gbà láti ta ojú òpó nàá ní $44bn fún Elon Musk, ọkùnrin tó lówó jù ní ayé

Elon Musk

Oríṣun àwòrán, Reuters

Igbimọ alaṣẹ to ni ayelujara Twitter ti gba lati ta a fun Elon Musk.

Ọsẹ to kọja ni Ọgbẹni Musk kede pe o wu oun lati ra Twitter, nitori ọpọlọpọ anfaani to wa nibẹ.

Ṣaaju lo ti kọkọ kọwe si Twitter pe ki wọn mu adinku ba awọn ofin kan to de wọn to n lo o.

Ileeṣẹ Twitter ti kọkọ kọ ibeere Musk, ṣugbọn wọn pada gba lati ta a fun ni milinu mẹrinlelogoji Dọla, lẹyin ti awọn oludokowo dibo.

Elon Musk lo ni owo julọ ni agbaye.

Apapọ owo rẹ to $273.6 bilinu, ti ọpọ rẹ jẹ ipin idokowo nileeṣẹ to n ṣe ọkọ ayọkẹlẹ to n lo ina ẹlẹtiriki, Tesla, ati ileeṣẹ Space X to n ṣeto irinajo si inu ofurufu.

Ninu ọrọ to fi kede pe oun ti fẹ ra Twitter, Musk sọ pe "ominira lati sọ ero ọkan ẹni, jẹ ipilẹ fun iṣejọba awaarawa to poju owo, Twitter si ni gbagede ti awọn eeyan ti n korajọ lati jiroro lori awọn nkan to ni i ṣe pẹlu ọjọ iwaju ọmọniyan."

O ṣalaye pe oun fẹ gbakoso Twitter, lati le ṣe awọn atunṣe ti yoo mu ki gbogbo eeyan jẹ anfaani kan naa.

Iyatọ wo ni yoo ba Twitter ti Musk ba gbakoso?

Lara ayipada ti yoo ba Twitter nigba to ba gbakoso ni pe ipin idokowo Twitter ko ni i wa fun gbogbo eeyan mọ.

Musk ti kọkọ daba pe ki Twitter fi aaye gba ki awọn eeyan le kọ ọrọ to pọ, ki wọn si le ṣe atunṣe si lẹyin ti wọn kọ ọ.

Àkọlé fídíò, Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe- Afusat Adeniyi tó ń tún 'Pumping Machine'

Bakan naa ni ko ti i daju lori ẹni ti yoo jẹ oludari Twitter. Idi ni pe oṣu Kọkanla, ọdun to kọja ni oludasilẹ rẹ, Jack Dorsey, kọwe fi ipo naa silẹ.

Lẹyin naa ni Parag Agrawal gbakoso.

Amọ ninu iwe ti Musk fi kọwe lati ra Twitter, o ni oun ko ni igbagbọ ninu igbimọ oluṣakoso to wa nibẹ lọwọlọwọ.

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

Anfaani wo ni Naijiria n jẹ loju opo Twitter?

Ọpọlọpọ miliọnu ọmọ Naijiria lo n lo ayelujara Twitter fun ibadọrẹ, idokowo, ati lati jiroro lori eto osẹlu, amuludun, ere idaraya, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ko yọ awọn oloṣelu paapaa silẹ. Wọn n lo fun ipolongo ibo wọn laarin awọn ọdọ.

Àkọlé fídíò, Abisola Odebode: Ẹ wo àkàndá ẹ̀dá tó ń kọ́ àwọn àgùnbánirọ̀ l‘Osun ní ọ̀dà ṣíṣe lọ́fẹ̀ẹ́

Lara awọn asiko ti Twitter ti wulo ju ni iwọde ENDSARS to waye lọdun 2020. Ori ayelujara yii ni awọn oluwọde ti n fi ikede ranṣẹ si ara wọn, ti wọn si tun ṣe ikowojọ.

Yatọ si eyi, ọpọ igba ni awọn to wa ninu ewu ti lo oju opo naa lati kigbe fun iranlọwọ.