Ẹ dáríjìn mí ọmọdé ló ń ṣe mí, mo kábàmọ́ ìwà tí mo wú - Akẹ́kọ̀ọ́ Chrisland Schools

Chrisland School

Oríṣun àwòrán, Chrisland School

Akẹkọọ Chrisland Schools ti wọn jawe lọ rọkun nile fun lẹyin ti fidio ibalopọ oun atawọn akẹgbẹ rẹ kan jade lori ayelujara ti yọ gbogbo fidio to fi lede ṣaaju loju opo rẹ to wa lori ikanni Likee.

Awọn eeyan wa oju opo naa, to ni awọn ololjufẹ bii 12,400 kan, lẹyin ti fidio ibalopọ ọmọ ọdun mẹwaa naa fa ori ayelujara ya.Ǹkan tí a mọ̀ rèé nípa ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ tó wáyé láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Chrisland

Ọmọ naa ti n fi oniruru fidio lede loju opo Likee rẹ ọhun ṣaaju ki fidio ibalopọ rẹ to jade loju opo Twitter.

Kini Iya ọmọ ti ọrọ kan sọ?

Iya rẹ, lasiko to n sọrọ fẹsun kan ile ẹkọ Chrisland pe wọn sẹ ayẹwo fun ọmọ oun lati mọ boya oyun ti wa lara rẹ lai bun oun gbọ, amọ ile ẹkọ naa ti sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ.

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni ijọba ipinlẹ Eko gbe ile ẹkọ naa ti pa, amọ wọn tun pada ṣi lopin ọsẹ to kọja.

bhadgirl4k

Oríṣun àwòrán, @bhadgirl4k

Àkọlé fídíò, Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe- Afusat Adeniyi tó ń tún 'Pumping Machine'

Iroyin ni ọmọ ọhun lọ soju opo Likee rẹ naa, lati tọrọ aforijin lori awọn fidio rẹ .

O ni "Mo ti ṣe aṣiṣe, mo si ti n gbe pẹlu ibanujẹ ọkan lori ohun ti mo ṣe, mo kabamọ iwa mi. Ẹ darijin mi."

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

Nigba ti awọn akọroyin ṣabẹwo si oju opo ọmọ naa lori ikanni Likee, o ti fa gbogbo fidio rẹ to wa nibẹ yọ.

Awọn fidio ọhun ko din ni 500.

Àkọlé fídíò, Female Carpenter: Fatia Garu ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí gbàgbọ́ pé obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ Káfíńtà

Yatọ si Likee, ọmọ naa tun lọ soju opo Tiktok rẹ nibi ti ni awọn eeyan to le ni ẹgbẹrun mejila ti wọn n tẹle, lati tọrọ aforijin.

bhadgirl4k

Oríṣun àwòrán, @Bhadgurl4k

O ni "Maṣe jẹ ki ohun ti o ṣẹlẹ sẹyin ṣapejuwe irufẹ ẹni ti o maa jẹ laye, amọ jẹ ko jẹ ẹkọ fun nitori ọjọ ọla rẹ.

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó