Alaafin's burial rite: Òrumọ́jú ní ara Oba Lamidi Adeyemi III wọ káà ilẹ̀ lọ bí ìṣe ìran Yorùbá ṣe làá kalẹ̀

Alaafin

Oríṣun àwòrán, @Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awaye e lọ ko si.

Gbogbo ẹ̀dá lo dagbada iku bẹẹ̀l ko si ẹni to ri ti iku se niagb ti ọlọ́jọ́ bá ti de.

Ojọ Abameta, ọjọ́ ketalelogun, osu kerin, ọdun 2022 ni Oba Atanda Lamidi Adeyemi kẹta dagbere faye pe o digbose.Kéte ti Baba dákẹ́ ni àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ti bẹ̀rẹ̀ l'Áàfin - Ẹ wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Aafin Oyo

Lati igba naa si ni eto isinku ipapoda kabiesi ti bẹrẹ ni ilu Oyo nipinle Oyo ni guusu iwo oorun Naijiria.Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀

Bawo ni eto isinku Kabiesi se lọ?

Nígbà tí BBC Yorùbá ṣe àbẹ̀wò sí ààfin ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, iwájú ààfin kún fún ọ̀bítíbitì àwọn ènìyàn tí wọ́n wá kẹ́dùn àti láti fìdí òtítọ́ múlẹ̀ lórí ìròyìn wí pé Aláàfin gbésẹ̀.

Awon Aafa kirun si ara Alaafin Lamidi Adeyemi

Lara awọn ọrẹ timọtimọ Iku Baba Yeye to duro ṣoju ti wọn tun duro ṣẹyin ni Bisoobu agba Ayo Ladigbolu ati awọn mii.

To je olusọ agutan agba pẹlu ijọ Eleto, Methodist Church Nigeria.

Àkọlé fídíò, Alaafin Oyo's burial: Oba Lamidi Adeymi darapọ̀ mọ́ àwọn àgbà ìṣáájú, ọ̀pọ̀ ń dárò Kábíèsí

Ni kete ti awọn Alaafa kirun ikẹyin si ara Iku Baba Yeye tan ni irọlẹ naa ni wọn ti bẹrẹ eto to ku.

Bawo ni wọn se pari eto isinku Oba Lamidi Adeyemi?

Lẹyin ti wọn kirun naa tan ni wọn gbe ara Oba Atanda Adeyemi pada sinu aafin.

Nibẹ ni won ti dagbere fun gbogbo akoroyin pe eto isinku ti o le hande si ojutaye ti pari.

Wọn salaye pe Baràa, agbegbe to to irirn iseju marun un si aafin Alaafin Oyo ni wọn yoo ti pari gbogbo eto to ku.

Skip Facebook post, 1

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 1

Ìtọ̀sẹ̀ ló ní Oyo....

Yoruba lo ni asa ati ise.

Asoju awọn ọmọọba Adeyemi ati awọn alawo ati awọn agbaagbaa majẹkobajẹ lo lọ yanju eto Orò ati awọn Etutu to ku to yẹ ni sise ki ara Oba Adeyemi to le wọ kaa ilẹ lọ.

Skip Facebook post, 2

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 2

Nkan bii agogo mẹjọ alẹ ọjọ Abameta, ọjọ ketalelogun, osu kerin, ọdun 2022 ni wọn si bẹrẹ awon etutu naa ki iroyin to fi ye wa pe orumọju ni gbogbo eto naa si pari.

Won ko gba ajoji tabi alejo kanakan laaye lati ba wọn peju sibi etutu naa.

Skip Facebook post, 3

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 3

Koda, wọn fi ofin de lilo kamẹra, foonu tabi ẹrọ igbohunsilẹ rara lasiko naa.

Bayii Oba Atanda Lamidi Adeyemi kẹta ti darapọ mọ́ awọn alaseku ilẹ̀ Yoruba tí ọ̀pọ̀ n gbadura sí pe ki wọn tubọ maa satileyin fun iran Yoruba.