Kwara State Suicide Attempt: Àìníṣẹ́ lọ́wọ́ ló mú mi pokùnso -Olayinka

Ẹni tó ń ronú

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ní àwọn ti dóòlà ẹ̀mí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olayinka Owolabi tó gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀.

Olayinka tó jẹ́ ọmọ bíbí ilé Alagbede, Aboto Oyan, ìjọba ìbílẹ̀ Odo-Otin ní ìpínlẹ̀ Osun ni ó gbèrò láti pokùnso ní agbègbè Airport ní ìlú Ilorin.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Kwara, Ajayi Okasanmi nígbà tó ń fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún BBC Yorùbá sọ pé ní nǹkan bí ago mẹ́fà ìrọ̀lẹ̀ ọjọ́bọ̀ ni ọkùnrin kan rí nǹkan tó ń mì jọlọjọlọ lórí igi ní agbègbè Checking Point.

Okasanmi ni ọkùnrin náà ló sáré lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá Budo Nuhu tó wà ní agbègbè náà láti lọ fi tó àwọn ọlọ́pàá létí.

Ó ní "nígbà tí àwọn ọlọ́pàá fi ma dé ibẹ̀, wọ́n bá ọkùnrin náà tó so okùn mọ́ ara rẹ̀ lọ́rún tó sì ń mì jọlọjọlọ."

"Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní àwọn ọlọ́pàá tú okùn náà ní ọrùn rẹ̀ tí wọ́n sì gbe lọ sí ilé ìwòsàn Tobi tó wà ní agbègbè Taiwo ní ìlú Ilorin."

"Àwọn dókìtà ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn, ara Olayinka Owolabi ti ń balẹ̀."

Okasanmi tẹ̀síwájú wí pé òfin Nàìjíríà kò fi àyè gba kí ènìyàn gba ẹ̀mí ara rẹ̀, èyí sì túmọ̀ sí wí pé ó ṣeéṣe kí Olayinka fojú ba ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tí ara rẹ̀ bá balẹ̀ tán.

Ó ní Olayinka yóò kojú ẹ̀sùn wí pé ó fẹ́ gba ẹ̀mí ara rẹ̀.

Àkọlé fídíò, Oru tí olóríibú máa ń di olóríire ni "Laylatul Qadr", tóo bá bẹ Ọlọ́hun, orú agbára gidi ni - Akeugbagold

Kí ló mú Olayinka gbèrò láti pokúnso?

Agbẹnusọ ọlọ́pàá Kwara ní nígbà tí àwọn fi ọ̀rọ̀ wá Olayinka lẹ́nu wò lórí ìdí tó fi gbèrò láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀, Olayinka ṣàlàyé wí pé ayé ti sú òun ni.

Olayinka ṣàlàyé wí pé iṣẹ́ ti bọ́ lọ́wọ́ òun, òun kò ní ìyá àti bàbá láyé mọ́, bẹ́ẹ̀ oúnjẹ tàárọ̀ kìí bá tọ̀sán fún òun ló mú òun pinu láti gbẹ̀mí lọ́rùn ara òun.

Ó fi kun pé gbogbo nǹkan le koko fún òun àti wí pé bí gbogbo nǹkan ṣe dẹnu kọlẹ̀ ní Nàìjíríà náà ṣe

Àkọlé fídíò, Wọ́n jí pè mi láàrọ̀ pé ọmọ mi bímọ, ó dákú àmọ́ bí mo ṣe débẹ̀, àt'òkú ọmọ mi, àt'òkú