Bukunmi Oluwasina: Ẹ wo ọ̀pọ̀ ìgbà tí àwọn òṣèré fíìmù Yorùbá ti gbé àwọn olólùfẹ́ wọn ní ‘handiccap'

Oríṣun àwòrán, Bunkunmi/Chatta/Ademola
Ni ọjọ Isẹgun ni gbajumọ osere tiata, Bukunmi Oluwasina bọ si oju ayelujara toun tomije loju to si n sukun aro ninu fidio naa.
Ọpọ awọn ololufẹ rẹ ni omije rẹ gba omije loju wọn ti ọpọ si tun banujẹ gidigidi lori ero pe boya aida kan lo ṣẹlẹ sii.
Amoṣa lẹyin o rẹyin ni o han sita pe ko si laabi kankan to ṣe osere yii, o kan n yọ ayọ ori ayelujara lasan ni.
- Fayose kìí bá wọn jẹ ìjẹkújẹ, bí Aisha Buhari bá fẹ́ fún èèyàn l'Oúnjẹ ko wá aláìní lọ
- Ọwọ́ ọlọ́pàá Ogun tẹ ọkùnrin ọgbọ̀n ọdún tó fi ipá ba obìnrin lò nínú ṣọ́ọ̀ṣì
- Ikú Dagrin pé ọdún méjìlá, wo àwọn ǹkan mánigbàgbé nípa rẹ̀
- Wo àwọn ǹkan tí ẹ kò mọ̀ nípa gbajúgbajà olórin ẹ̀mí, Tope Alabi
- Mo tọrọ àforíjì lórí fídíò tí mo gbé jáde, tó ń mú àwọn èèyàn pè mí - Bukunmi Oluwashina
- Erin wóó! Ààrẹ Kenya tẹ́lẹ̀, Kibaki jáde láyé lẹ́ni ọdun 90
- Ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ yóò wà ní Nàìjíríà, àtàwọn orílẹ̀èdè míràn wọ ọdún 2023 - IMF
- Tí mo bá dí ààrẹ, gbogbo àwọn agbébọn yóò pòórá tí wọ́n bá gbọ́ orúkọ mi - Nyesom Wike
- Ẹ̀yà Igbo ni ipò Ààrẹ kàn, tá a ba fẹ́ àlàáfíà àti àìṣègbè - Adebanjo
Gẹgẹ bi iwadii BBC News Yoruba lori iṣẹlẹ yii, ohun elo igbana sara (Charger) ẹrọ ibanisọrọ rẹ lo sọnu.
Pupọ awọn ololufẹ rẹ to pada wa gbọ okodoro ọrọ naa ni inu wọn ko dun si ohun to ṣe naa ti wọn ko si fi ẹhonu wọn pamọ lori rẹ.
Lootọ Bukunmi ti pada wa tọrọ aforijin lọwọ awọn ololufẹ rẹ to ni Mo tọrọ àforíjì lórí fídíò tí mo gbé jáde, tó ń mú àwọn èèyàn pè mí - Bukunmi Oluwashina
Amoṣa, igba akọkọ kọ niyi ti awọn oṣere tabi ilumọọka yoo maa hu iru iwa bayii eleyi ti n ko ọkan awọn ololufe wọn soke.
Ibrahim Chattah, oṣu kejila ọdun 2021
Ni ọjọ kẹtadinlogun osu kejila ọdun 2021 ni ori ayelujara ni Naijiria daru lẹyin ti ilumọọka osere tiata, Ibrahim Chattah kede ninu fidio kan loju opo Instagram rẹ pe iporuru ọkan ti ba oun lori ohun kan to ṣe pataki si oun ti oun padanu.
Ọrọ yii milẹ pupọ nigba naa nitori asiko ti ọpọ iṣẹlẹ n ṣẹ nitori ipaya, iporuru ọkan to de ba awọn eeyan nigba naa ni.

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Chatta
Ṣe ni ọpọ awọn ololufẹ Chatta ati tiata Yoruba ko aya soke nigba naa ti wọn si n gbadura pe ibi ko ni ṣẹlẹ si gbajumọ osere yii.
Nigba to ya ni Ibrahim Chatta wa tun tọrọ aforijin lọwọ awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn maa binu si oun, kii ṣe ohun ti won ro lo ṣe oun.
O ni ẹṣin funfun oun kan lo ṣalaisi to faa kii ṣe nnkan miran.
Muyiwa Ademola, Oṣu kẹrin ọdun 2022
Muyiwa Ademola, ti ọpọ eeyan mọ si Muyi Authentic pẹlu ti figba kan ri da apara bẹẹ ninu eyi ti ti sọ loju opo ayelujara rẹ pe oun fẹ fi ere tiata ṣiṣe silẹ lọ gbe igba oselu lati dije dupo lọdun 2023.
Ninu ikede to kọkọ gbe jade lọjọ kinni, oṣu Kẹrin lo ti sọ pe oun ti bẹrẹ oṣelu, ati pe oun yoo du ipo sẹnatọ ninu idibo gbogbo gboo ti yoo waye lọdun 2023.

Oríṣun àwòrán, Instagram/authenticmuy
Eyi mu ki ọpọlọpọ ololufẹ rẹ ni Naijiria ati Oke okun pẹlu maa kan sii lati gbaa ni amọran, "bi awọn kan ṣe n ṣọ pe awọn wa lẹyin mi digbi bii ike, lawọn mii n sọ pe ki n ma ba wọn lọwọ si ọrọ oṣelu Naijiria fun idi kan tabi omiran."
Lẹyin ọjọ diẹ lo pada wa tọrọ aforijin lọwọ awọn ololufẹ rẹ to sọ pe, iṣẹ tiata ni iṣẹ ti ori ran oun ati pe oun ko nifẹ si oṣelu ṣiṣe.

















