Ohun tí a mọ̀ nípa gbas gbos tó ń wáyé láàárín Sẹ́nétọ̀ Kola Balogun àti ọmọ Olubadan rèé

Aworan Olubadan, Aremo Olubadan ati Kola Balogun

Oríṣun àwòrán, Senator Kola Balogun

Sẹnẹtọ Kola Balogun ti Aremo Olubadan, Femi Balogun fi ẹsun oriṣiriiṣi kan pe ko jẹ ki awọn ọmọ Olubadan ti ilẹ Ibadan, Oba Lekan Balogun, Alli Okunmade Keji, mọ ohunkohun nipa owo, ọrọ ati dukia baba wọn ti sọ fun BBC Yoruba pe irọ funfun balau ni gbogbo ẹsun naa.

Ṣaaju ni Olubadan fun ra rẹ ti fi atẹjade kan sita inu eyi to ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu gbogbo ẹsun ti Aremo Femi Balogun fi kan aburo oun.

Koda, niṣe ni Olubadan fun ra rẹ rawọ ẹbẹ si Sẹnẹtọ Balogun pe ki o fiye denu ki o si darijin Ọmọba Femi pẹlu awọn ẹsun to fi kan an.

Olubadan sọ ninu atẹjade to buwọlu fun ra rẹ pe ibanilorukọjẹ lasan ni gbogbo ẹsun ti Aremo Olubadan ati awọn ọmọ Olubadan mii fi kan aburo oun.

''Ipa ribiribi ni aburo mi yii ti ko ninu igbesi aye mi.

"Oun nikan lo wa pẹlu mi nigba ti nnkan ko fara rọ ati ni gbogbo igba.

Mo le fi gbogbo ẹnu sọ wi pe ipa ti o n ko ninu aye mi ju ipa tawọn ọmọbibi inu mi gan an n ko lọ.

Mo wa fi asiko yii bẹ aburo mi pe ki o ma binu tori ọmọde lo n ṣe Arẹmọ Femi Balogun.

Gbogbo ẹbi lo maa n ni ede aiyede, ṣugbọn ko gbọdọ debi ibanilorukọ jẹ eleyii ti mo korira.

Koda n o kọ lati kọ ọmọbibi inu mi to ba hu iru iwa bẹẹ lọmọ,'' Olubadan lo sọrọ yii ninu atẹjade ti o buwọlu.

Aworan atẹjade Olubadan

Oríṣun àwòrán, Oladele Ogunsola

Ko si otitọ kankan ninu ẹsun ti Aremo Femi Balogun kan mi - Sẹnẹtọ Kola Balogun

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Sẹnẹtọ Kola Balogun ṣalaye fun BBC Yoruba pe ''arifin gbaa ni gbogbo ọrọ ti Arẹmọ Femi Balogun n gbe kaakiri.

O ni ọrọ ẹbi ni ọrọ to wa nilẹ yii ati pe Kabiyesi Olubadan gan an ti sọrọ lori rẹ.

Sẹnetọ Kola Balogu ṣalaye pe Femi kan fẹ da wahala silẹ ninu ẹbi ni nitori ko ni ẹri kankan to daju lati fi gbe ẹsun rẹ lẹsẹ amọ to ba da loju ko lọ fi ẹjọ sun ajọ to n gbogunti iwa ajẹbanu iyẹn EFCC atawọn ọlọpaa.

O fi kun ọrọ rẹ pe ninu ọmọ mẹrinla ti Olubadan bi, awọn mẹta- Femi, Yinka ati Bukola lo da yatọ to maa n fun ẹbi ni wahala ati pe ohun ko ni iṣorọ kankan pẹlu awọn mọkanla toku ninu gbogbo ọmọ Olubadan.

"Mi o ti ẹ fẹ sọrọ gan an fun ileeṣẹ iroyin kankan tori Kabiyesi, Olubadan gan an ti sọrọ funra wọn.

"Kabiyesi ti pe mi lori ago, wọn si ti bẹ mi lori ọrọ yii.

"Iwa agbojulogun ni Femi, Yinka ati Bukola n hu kaakiri."

Sẹnétọ Kola Balogun tẹsiwaju pe oun ko le ṣe abosi tabi ṣe nnkan aburu tabi to lodi si ofin si Olubadan nitori wọn kii ṣe eeyan bẹẹ lọwọ oun.

O ṣalaye pe ko si dukia Kabiyesi kankan lọwọ oun ati pe oun kan n bawọn mojuto awọn dukia wọn ni nitori iha ti awọn mejeeji kọ si ara awọn.

"Gbogbo bi a ṣe gbe Kabiyesi lọ si oke okun fun itọju to n sọ kaakiri yẹn, Kabiyesi ti rinrin ajo lọ si oke okun, emi ni mo sanwo rẹ.

Idi niyi ti Kabiyesi ṣe fẹran mi gan an tori mi o le fi ọrọ wọn ṣere, awọn naa kii fi ọrọ temi naa sẹre."

O fi kun pe ti gbogbo nnkan ti Femi n sọ ba loju ko gba agọ awọn EFCC, ICPC ati ọlọpaa lọ lati lọ fẹjọ sun nibẹ.

O ni ohun ti oun gbero lati ṣe tẹlẹ ni pe òun fẹ pe Femi lẹjọ fun ẹsun ibanilorukọ jẹ ati dida omi alaafia ilu ru.

"Amọ, Kabiyesi pe mi, wọn si bẹ mi pe ki n ma binu.

Ọrọ ti wọn ba mi sọ lo bi atẹjade ti wọn fi sita yẹn.''

EFCC ati ọlọpaa maa gbọ si ọrọ yii - Aremo Olubadan

Nigba to n sọrọ lori awọn ẹsun to fi kan sẹnetọ Kola Balogun nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Arẹmọ Femi Balogun ni Sẹnẹtọ Kola Balogun jokoo le owo ati ukia Olubadan.

O ni Sẹnẹtọ Balogun ko jẹ ki awọn ọmọ Olubadan mọ nkankan nipa bi o ṣe n dari dukia baba awọn.

O ni ohun ti oun n fẹ ni kukuru ni pe ki Sẹnẹtọ Kola da akaunti Olubadan pada fun un ki o le ri owo lọ tọju ara rẹ ni oke okun.

''Ni akọkọ, Kabiyesi ni awọn kọ ni awọn kọ lẹta to gbode yẹn, ti ẹ ba si wo lẹta naa daadaa, kii ṣe ede Kabiyesi niyẹn.

Ohun ti a fẹ ni pe ki Kabiyesi lọ tọju ara wọn loke okun, koju bayẹn lọ.

Sẹnẹtọ Kola Balogun n lo ailera Kabiyesi ati owo wọn lati le maa dari wọn.

Gbogbo awọn oloye Ibadan lo mọ ohun to n lọ ṣugbọn wọn o kan le sọrọ ni,''

O ni igbesẹ to kan tawọn maa gbe bayii ni pe awọn maa kọ lẹta sawọn alaṣẹ lati ori gomina to fi de ọri ọga ọlọpaa ati ajọ EFCC pe ki Sẹnẹtọ Balogun da owo Kabiyesi pada fun wọn.

Arẹmọ Olubadan ni Sẹnẹtọ Kola Balogun n lo ailera Kabiyesi ki oun le maa ṣe bi Olubadan nita.