Fásitì Chicago ti gbé ìwé ẹ̀rí Tinubu tí Atiku béèrè jáde síta, wo ohun tó wà níbẹ̀

Awuyewuye lori ọrọ iwe ẹrí aarẹ Naijiria Bola Tinubu tun ti gba ọnà mii yọ lẹyin ti fasiti Chicago to loun ti kawe gboye gbe awọn iwe ẹrí rẹ ti Atiku Abubakar beere sita.
Atiku Abubakar jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo aarẹ Naijiria ti Tinubu tí jaweolubori.
Iwe ẹrí to beere fún yi wa lara ẹrí to fẹ fi tako Tinubu niwaju ileẹjọ ki wọn bàá le kede pe ko tọ sipo aarẹ to wa.
Lopin ọsẹ ni ile ẹjọ agbegbe Northern Illinois ni Amẹrika pàṣẹ ki fasiti Chicago jọwọ awọn iwe ẹrí ti Atiku kọwe beere.
Ninu esi ti fasiti da padà, wọn sọ pé àwọn jọwọ iwe ẹrí ọdun 1977 ti o jẹri sí pé Tinubu kawe gboye ni ile ẹkọ wọn eyi ti wọn kò ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣù Kẹfa ọdún 1977 sí orí rẹ.
" Lẹyìn ọpọ iwadii fasiti CSU ti ṣe idanimọ nípa ibeere yin taa sí ti fi awọn ìwé ẹri ṣòwò nípa rẹ.Nọmba idanimọ awọn iwe ti ẹ beere fún ree CSUO008 titi de CSU0010"
Bẹẹ náà ni fásítì fi awọn ìwé ẹri mi yatọ si tí Tinubu amọ to jẹ tàwọn akẹkọọ mí to kawe parí lọdọ wọn. ""A pa orúkọ awọn akẹkọọ yi rẹ lori ìwé ẹri wọn láti fi ma ṣàfihàn orúkọ wọn fáráyé" Aworan awọn iwe ẹrí náà ree.

Oríṣun àwòrán, BBC
Fásítì náà tẹsiwaju pe awọn iwe ẹrí tàwọn gbe sita ti Atiku sí beere nípa rẹ wà ní ibamu pẹlu eyi tàwọn gbe jáde lorukọ Tinubu to parí ẹkọ rẹ lọdọ awọn.
"Ṣaaju ni Tinubu tí sọ pé oun sọ iwe ẹrí òun ni ti eyi su mú kí o fi iwe ẹrí mii silẹ niwaju INEC ṣaaju idibo ọdún 2023.
Kaakiri oju ọpọ ayelujara láwọn aworan oríṣi tí gbòde tó jẹ ẹrí pé o kẹkọọ jáde ní fasiti Chicago State.
Àmì idanimọ ti o wa lori aworan iwe ẹrí 1977 ti fasiti náà fí ṣọwọ sí Atiku ṣe dede pẹlu eyi ti Tinubu fí ṣọwọ sí INEC.
Iyatọ to wà níbẹ ni ọjọ tí wọn kọ sori iwe ẹrí yi ti ko papọ mọ ará wọn. Amọ fasiti naa gba ẹbi aṣiṣe yi ti wọn sì ni lati ọdọ awọn lo ti waye.
Báwo lọrọ ṣe dé ibi to de duro yii
Lọjọ Kokandinlogun oṣù Kẹsán ni adajọ Jeffrey Gilbert ti ile ẹjọ majisreeti Amẹrika gba iyọnda fún Atiku pé ki fasiti náà jọwọ iwe ẹrí ti o beere laarin wakati merinlelogun.
Kí eleyi bàá ma waye Tinubu gba ile ẹjọ lọ pe ki adajọ mii wọgile igbalaye yi.
Amọ Adajọ Nancy Maldonado ni bibeere fún iwe ẹrí yi wa ni ibamu to sì f'ẹsẹ idajọ majisreeti àkọkọ rinlẹ pé ki wọn yọnda iwe ẹrí yi fun Atiku.
Eyi lo mú ki fasiti CSU gbé iwe ẹrí jade amọ wọn láwọn kò ri iwe ẹrí ti wọn fún Tinubu lọdun 1977 gangan.
Ẹda iwe ẹrí náà ni wọn fi ṣọwọ.
Lati lè jẹri sí eyi ti wọn fí sita fasiti gbé iwe ẹrí awọn akẹkọọ mii jáde ki wọn bàá le fi we ti Tinubu lọna ati jẹ o di mímọ̀ pe irú kannáà ni iwe tàwọn fún ati tàwọn ẹlòmíràn.
Èròngbà Atiku ni lati lo iwe ẹrí yi gẹgẹ bi ẹrí niwaju ile ẹjọ to ga julọ ni Nàìjíríà láti fí kun ẹrí atako rẹ si ijaweolubori Tinubu ninu ibo 2023.












