Àwọn ọmọ Nàìjíríà fi èrò wọn hàn lórí ipò tí Nàìjíríà wà lẹ́yìn ọdún 63 ta gba òmìnira

Buhari, Jonathan, Atiku, Primate Ayodele, Daniel Okoh

Oríṣun àwòrán, SCREENGRAB

Bí àwọn ọmọ Nàíjíríà ṣe n ṣayẹyẹ àyájọ́ ọ̀dun òmìnira, Ààrẹ tẹ́lẹ̀rì l’orílẹ́-ẹ̀dẹ̀ Nàíjíríà, Goodluck Ebele Jonathan gba àwọn ọmọ Nàíjíríà lámọ̀ràn láti máa fi ìfẹ́ bá ara wọn lo lójúnà láti lè mú Nàíjíríà dé ilẹ̀ ìlérí.

Jonathan ninu atẹjade kan loju opo X (twitter tẹlẹ) rẹ laaarọ ọjọ Aiku, ni gẹgẹ bi Naijiria ṣe n ṣami ayẹyẹ ayajọ ọdun ominira miran, a ni lati gbajumọ inifura, idajọ ododo, alaafia ati iṣọkan lojuna ati jẹ ki eso afojusun Naijiria farahan fun idagbasoke.

O gba awọn ọmọ Naijiria lamọran lati tun ipinu ireti wọn ṣe lati le ni ọjọ iwaju rere, lai wo ti awọn ipenija to wa nita lakoko yii.

O da mi loju pe eto iṣẹjọba awaarawa yoo tunbọ maa gbooro si - Buhari

Buhari

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Ṣaaju asiko yii ni Aarẹ ana, Muhammadu Buhari ti ba Aarẹ Tinubu yọ fun ti ayajọ ọdun ominira, ẹlẹẹkẹtalelọgọta iru ẹ, to si loun nigbagbgọ pe Naijiria yoo ṣi ni idagbasoke táwọn eeyan n fẹ.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Buhari, Garba Shehu fi sita lo ti jẹ ko di mimọ pe ọdun kẹtalelọgọta ti Naijiria ti gba ominira yoo tunbọ maa jẹ ohun iwuri fun awọn orilẹ ede to jẹ akẹgbẹ rẹ lagbaye wu pẹlu ilakaka to ti dojukọ.

“O da mi loju pe eto iṣẹjọba awa-ara-wa yoo tubọ maa ni irolagbara lọdọọdun lorilẹede wa yii.”

Ọmo Naijiria, ẹ ku ifarada o – Atiku

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Instagram

Igbakeji aarẹ tẹlẹ ri ni orileede Naijiria to tun oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ninu eto idibo to kọja, Atiku Abubakar ti gbe oṣuba kare fun awọn ọdọ orileede Naijiria fun ọkan akikanju wọn lati duro ti Naijiria lakoko ipenija fun ọjọ iwaju rere.

Atiku ni oun gbe oriyin fun awọn ọdọ bi wọn ṣe n lo ọgbọn ati imọ wọn lati mu ilọsiwaju ba Naijiria pẹlu gbogbo ipenija ti wọn n koju.

Bakan naa lo sọ pe oun ki wọn fun ifarada ti wọn n ni si awọn ohun to n ṣẹlẹ, ti wọn ko si ni irẹwẹsi ọkan ni eyi to ni o fi han pe awọn kaju oṣuwọn lati figagbaga pẹlu akẹgbẹ wọn lagbaye.

A ṣi n gbe ninu igbekun, awọn olori wa ti kuna – Primate Ayọdele

Primate Ayodele

Oríṣun àwòrán, Others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alakoso ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele ti sọ pe inu igbekun ni awọn ọmọ ati olugbe orileede Naijiria wa, nitori ti awọn adari ti kuna lọpọ ọna.

Wolii Ayọdele lo sọrọ yii ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Oluwatosin Osho gbe jade lati fi ṣami ayajọ ọjọ ominira to n ṣẹlẹ lonii, to si l’awọn adari gbọdọ tọrọ aforiji lọwọ Ọlọrun.

“Awọn adari wa gbọdọ lọ ba Ọlọrun, didari lai ni olori jẹ eyi ti yoo mu Naijiria lọ soko iparun. Ijọba gbọdọ mu Naijiria tẹsiwaju nipa idaṣẹsilẹ, ki wọn si jẹ ki eto ọrọ aje tẹsiwaju nitori pe iya nla wa nita.

“Koko ohun mẹrin ni ijọba da le lori, awọn naa si ni eto aabo, ọrọ aje, ibaṣepọ agbaye ati awọn ohun alumọọni.

“Bi iọba yii ko ba ṣọra lori awọn nnkan wọnyi, wọn yoo kuna. Fun wọn lati ma ṣe kuna, wọn ni lati gbe igbesẹ to yẹ.”

“Ijọba yii ko nilo ariwo, awọn ọmọ Naijiria si ni lati ni imọlara nipa iṣejọba awa-ara-wa ati ominira. Ni okodoro, a ko tii gba ominira rara, igbominira wa ko fun wa ni ominira, a ṣi n gbe ninu igbekun.

Ipo ti owo naira wa ti sakoba fun awọn ọmọ Naijiria - CAN

Aarẹ CAN, Daniel Okoh

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ́ ọmọlẹyin Kristi ti a mọ si Christain Association of Nigeria ti parọwa si ijọba Naijiria lati tete wa nnkan ṣe si ọrọ owo Naijiria to tun ti ja lọ silẹ si awọn owo agbaye bii dọla ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ninu atẹjade ti aarẹ ẹgbẹ naa, Archbishop Daniel Okoh gbe jade ni ayayọ ọjọ ominira lo ti sọ pe ipo ti owo naira wa lakoko yii ti ṣakoba nla fun ọmọ Naijiria, to si nilo amojuto gidi.

Archbishop Daniel Okoh ni irinajo ibi ti Niajiria de lonii ti ran awọn ọmọ orilẹ ede yii leti nipa ilọsiwaju ti a ti ṣe ati awọn ipenija to ṣi wa niwaju.

O ni ki ijọba ṣagbeyẹwo irinajo Naijiria lati ibẹrẹ pẹpẹ ki wọn le mọ ọna ti wọn yoo gba lati ṣe atunṣe to yẹ lori ipenija to n koju araalu, paapaa lori ọrọ eto aabo ati ọrọ aje.

O fi kun pe bi owo naira ṣe ja lọ silẹ lojiji si awọn owo agbaye, paapaa owo dọla jẹ eyi to kọni lominu pupọ, to si ni ipa to ko nigbesi aye araalu kọọkan.

Bẹẹ lo rọ ijọba lati gbe igbesẹ ti yoo f’opin si gbogbo ipenija naa.