Ọ̀pọ̀ èèyàn ké ìrora ìlú le bí Nàìjíríà ṣe pé ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta lónìí
Ọ̀pọ̀ èèyàn ké ìrora ìlú le bí Nàìjíríà ṣe pé ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta lónìí

Bi o ti pe ọdun mẹtalelọgọta ti orilẹede Naijiria gba ominira lonii ọjọ kinni oṣu kẹwaa ọdun 2023 yii, ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti ke irora pe ilu le.
Diẹ lara awọn to ba BBC Yoruba sọrọ fi aidunnu wọn han si bi gbogbo nkan ṣe gboro lori lọla ti ara si n ni awọn mẹkunnu.
Ọkunrin kan ninu awọn to ba BBC Yoruba sọrọ tiẹ sọ omi inira loun tawọn eeyan n pe ni ominira.
Ẹni naa woye pe afaimọ ki nkan kan ma ṣẹlẹ pẹlu bi gbogbo nkan ṣe ri bayii nitori ''awọn iran to n bọ lẹyin ko le faramọ gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii.





