Atiku àti Obi gbé Tinubu lọ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ pé kò wọlé ìbò ààrẹ

Aworan Tinubu, Atiku ati Obi

Oríṣun àwòrán, Tinubu, Atiku, Obi/Facebook

Oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ati akẹgbẹ rẹ ti ẹgbẹ oṣelu LP, Peter ti gbe aarẹ Bola Tinubu lọ si ile ẹjọ to ga julọ pe ko wọle ibo aarẹ.

Laipẹ yii ni ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Abuja dajọ wi pe awijare Atiku ati Obi lẹsẹ nlẹ ti ile ẹjọ naa si fi ontẹ lu Tinubu gẹgẹ bi oludije to wọle ibo aarẹ Naijiria.

Ẹsun onikoko marundinlogoji ni Atiku fi kan Tinubu ninu ipẹjọ rẹ tuntun.

Atiku ni awọn adajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to da Tinubu lare ṣe aṣiṣe nla pẹlu idajọ wọn eleyii ti adajọ Haruna Tsammani jẹ oludari wọn.

Adari awọn agbẹjọro Atiku, agbẹjọro agba, Chris Uche, SAN n beere lọwọ ile ẹjọ to ga julọ pe ko yi idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun danu nitori ile ẹjọ kuna lati lo awọn ẹri tawọn mu wa sile ẹjọ.

Olori awọn agbẹjọro Obi ni tiẹ, agbẹjọro agba, Ọmọwe Livy Uzoukwu, SAN ti ṣe agbekalẹ ẹsun onikoko aadọta eleyii to n gbe lọ si iwaju ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria.

Oun naa ni idajọ ti ile ẹjọ kotẹmilọrun da ko tẹ onibara oun lọrun rara.

Oun naa n bẹbẹ niwaju ile ẹjọ to ga julọ lati yi idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun danu.

Obi ṣalaye pe ile ẹjọ kotẹmilọrun kuna lati fidi awọn ibo ti wọn ṣe magomago lori rẹ lati le ṣegbe lẹyin Tinubu.

Bakan naa ni Obi sọ pe ile ẹjọ kotẹmilọrun yi awọn ẹlẹri oun danu lọna aitọ.

Oludije ibvo aarẹ fun ẹgbẹ LP tun wi awijare pe ile ẹjọ kotẹmilọrun kuna lati ṣe agbeyẹwo bii ajọ INEC ṣe gba esi ibo ti ko han daadaa sori ẹrọ IreV.

Ni ọkọ kẹfa oṣu Kẹsan an ni ile ẹjọ kotẹmilọrun gbe idajọ rẹ kalẹ elyii to fi fontẹ Tinubu gẹgẹ bi oludije to wọle ibo aarẹ Naijiria ni ọjó kẹẹdọgbọn oṣu keji ọdun 2023 yii.