Kò sí ohun tó burú nínú kí èèyàn ṣe ògùn owó, ṣùgbọ́n...

Aworan aṣọ pupa kan pẹlu owo, ati aworan miran to jẹ aworan baba Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn

Oríṣun àwòrán, Baba Elelbuibon/ others

Eekan oniṣẹṣe to tun jẹ oodu lawujọ awọn to n gbe aṣa Yoruba ga kaakiri agbaye, Oloye Ifayẹmi ẹlẹbuibọn, araba awo ilu Oṣogbo ti ṣalaye pe ko si ohun to buru ninu ki eeyan ṣe ogun owo.

Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin kan sọ ni ile rẹ nilu Osogbo ni Oloye Ẹlẹbuibọn ti sọ ọrọ yii.

Baba Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn ṣalaye pe ohun to buru ni ki eeyan wa maa pa eniyan, yọ ọkan eeyan, ge ọwọ eeyan tabi ẹya ara miran fun ajo owo.

Ko si ẹni ti yoo ṣe gbogbo awọn nnkan ti a n sọ wọnyii ti ibi rẹ ko ni pada wa baa, nitori pe isinku ẹni ti wọn lo fi wa nnkan yoo maa da onitọun laamu.

Oloye Ẹlẹbuibọn tun sọ pe pọ igba lo jẹ wi pe atunbọtan awọn eeyan ti wọn fi iku gbigbona pa lati lee ṣe ogun owo naa lo n ṣe okunfa bi ọwọ ṣe n tẹ awọn to ṣiṣẹ ibi naa.

Ikanju lo n da awọn ọdọ ode oni laamu -Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn

Aworan Baba Ẹlẹbuibọn

Oríṣun àwòrán, Ifayemi Elebuibon

O ni awọn iwa ko tọ ti awọn dọ nhu lọna ati lee ni owo biribiri lo n fa iku aitọjọ ba wọn.

“Iṣekuṣe, ijẹkujẹ, imukumu lo n ge ẹmi awọn ọdọ kuru.”

Araba Awo ilu Oṣogbo naa ṣalaye pe apọju ọti mumu a maa ba agọ ara jẹ.

Oloye Elebubọn rọ awọn ọdọ lati ye gbe igbe aye ọkanjuwa ati waduwadu.

O ni o ṣeni laanu pe awọn ọdọ iwoyi kii fẹ ṣiṣẹ taratara mọ eleyi to ni o n mu ki wọn maa wa owo gbigbona kaakiri.

Agba oye ilẹ Yoruba naa tun ṣalaye pe pupọ awọn ti ko fẹ ṣe iṣẹ doju ami lo n wa owo gbọi lode oni

O ni awọn ọdọ ko fẹ lati bẹrẹ ni isalẹ pẹpẹ mọ, ṣugbọn ere asadiju ni wọn n sa kaakiri eleyi to ni o n fa wahala iku ọwọọwọ fun wọn.