Ọkọ mi kì í ṣe pidán-pidán, àmọ́ Nàìjíríà ṣì máa dára - Oluremi Tinubu

Aworan Bola ati Oluremi Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Aya aarẹ orilẹ ede Najiria Sẹnẹtọ Olurẹmi Tinubu sọ pe ọkọ oun Aarẹ Bọla Tinubu ki ṣe pidan-pidan, ṣugbon o n ṣe iṣẹ rẹ bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ lati jẹ ki orilẹede Naijiria pada bọ sipo.

Nigba ti o n sọrọ ni ile ijosin kan nibi ti wọn ti n ṣe ayẹyẹ ayajọ ọdun ominira ni ilu Abuja lanaa ọjọ Aiku, Olurẹmi sọ pe ọkọ oun ko ni dẹbi ohun to bajẹ ni Naijiria ru awọn to ti ṣe ijọba sẹyin.

Amọṣa, Oluremi ni ijọba Tinubu yoo tun gbogbo ohun to ti bajẹ ṣe, ati pe yoo mu irọrun ba awọn ọmọ orilẹ ede Najiria.

O fikun ọrọ rẹ pe oun ni igbagbọ ninu ọkọ oun pe o maa ṣiṣẹ lati ri pe alaafia yoo fi jọba ni Naijiria.

Sẹnẹtọ Oluremi tun sọ ninu ọrọ rẹ pe ọjọ ola si n bọ wa dara lorilẹ ede Naijiria.

Igba ọpọ ti de ni Naijiria, nitori naa, awọn ọmọ Naijiria gbọdọ ri ju ohun ti o n ṣẹlẹ lọwọ bayii lọ ti wọn be fẹ jẹ alabapin ninu igbega orilẹede wọn.

O si tun rọ awon ọmọ orilẹ ede Najiria lati ṣe ajọyọ ominira ni iṣọkan eyi to n gbe orilẹ ede leke.

''Ko si idojukọ ti a ko le bori ti a ba le tẹ le ọrọ ti Ọlọrun sọ ninu iwe mimọ pe ẹ wa si ọdọ mi ẹyin ti n ṣiṣẹ ti a di ẹru wuwo le lori emi o si fi isinmi fun ọkan yin.

Ni iru asiko bayii, gbogbo ohun ti a le ṣe ni lati di igbagbọ wa mu sinsin ninu Ọlọrun.

Aya aarẹ tun fi da awọn ọmọ orilẹ ede Najiria loju pe Tinubu ti ke si awon orilẹ ede lagbaye lati wa da ile iṣẹ silẹ fun irọrun gbogbo eeyan,'' Oluremi lo sọ bẹẹ.