Wọ́n fi ẹ̀sùn ìjówókó lọ sókè òkun kan ìyàwó ààrẹ Ali Bongo Gabon táwọn ológun gbàjọba rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn ti ẹsun ijowoko lọ soke okun, gbigba ẹru ole ati ṣiṣe ayederu kan Sylvia Bongo ti i ṣe iyawo aarẹ Ali Bongo tawọn ologun gba ijọba rẹ.
Olupẹjọ, Andre Patrick Roponat kede lọjọ Ẹti pe awọn ẹsun naa ti de iwaju adajọ bayii.
Bakan naa ni Roponat sọ pe ofin si de Arabinrin Sylvia sibẹ lati ma jade kuro nile.
Ọrọ jẹ jade lẹyin ọpọlọpa awuyewuye lori ibi ti iyawo aarẹ ana orilẹ ede Gabon wa.
Ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ tawọn ologun gba ijọba ọkọ rẹ ni wọn fofin de e wi pe ko gbodọ jade kuro nile.
Gbesẹ lati fẹsun kan arabinrin Sylvia waye lẹyin ti wọn ti fẹsun iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ kan ọmọkunrin rẹ, Noureddin Bongo Valentin tan.
Amọ, ijọba ologun orilẹede Gabon ti fun aarẹ naa Ali Bongo lominira lati rinrin ajo lọ soke okun fun itọju ara rẹ ti o ba fẹ.
Oniruuru ẹsun iwa ibajẹ, ṣiṣe owo ilu kumọkumọ ati iwa ajẹbanu ni wọn fi kan aarẹ Bongo ki wọn to doju ijọba rẹ bolẹ.















