Kí ni Uba Sani àti Isa Ashiru ń sọ nípa ìdájọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbẹ́jọ́ awuyewuye èsì ìdìbò Gómìnà ní Kaduna

Lọjọbọ yi ni igbimọ to n gbẹjọ lori awuyewuye to jẹyọ ninu esi idibo Gomina ipinlẹ Kaduna gbe idajọ kalẹ.
Wọn wọgile atako ti oludije ẹgbẹ oṣelu PDP gbe wa pe oun ko faramọ ijaweolubori Uba Sani oludije ẹgbẹ oṣelu APC/
Amọ nibi ọrọ de bayii, awọn igun mejeeji lo n sọ pe awọn ni idajọ naa gbe lẹyin.
Awọn aṣoju ẹgbẹ mejeeji lo wa ni ile ẹjọ lỌjọbọ nibi tawọn adajọ ko ti yọju lati gbe idajọ kalẹ.
Yala, niṣe ni wọn kede idajọ wọn loju opo ayelujara Zoom fawọn to peju si ile ẹjọ.
Ko si alaye kan pato lori idi ti wọn fi ka idajọ wọn loju opo Zoom amọ awọn eeyan sọ pe o ni ohun ṣe pẹlu aabo nitori bara awọn eeyan ko ṣe balẹ ṣaaju ikede yi.
Ko fẹ ẹ si eyi ti ko lawọn jaweloboiri ninu igun ti ọrọ yi kan amọ bi Uba Sani ṣe n kesi awọn to tako ijaweolubori rẹ lati pawọpọ pẹlu ijọba rẹ, bẹẹ ni Isa Ashiru ọun ṣe n sọ pe o n jiroro pẹlu awọn agbẹjọro rẹ lori igbesẹ to kan bayii.
Nkan tokan bayii ku sọwọ Isa Ashiru-Gomina Uba Sani
Ninu ọrọ tirẹ, Gomina Uba Sani sọ pe idajọ igbimọ lori esi idibo tunbọ fidi ododo mulẹ pe oun loun jaweolubori nitori lọkan toun, ko si magomago kankan nidi idibo to waye.
''Ki Allah gbe aṣeyọri fun wa.Fawọn alatako ẹgbẹ PDP to fidirẹmi, mo fẹ ki wọn gba pe ẹni to ba wu ni Ọlọrun maa n gbe agbara fun.Mo fẹ fi da awọn eeyan Kaduna loju pe a ko ni ṣe jamba fẹnikankan''
''Ko buru bi Isa Ashiru ṣe gba ile ẹjọ lọ nitori ile ẹjọ naa leeyan ti le beere fun ẹtọ rẹ labẹ ofin''
O tẹsiwaju pe awọn eeyan kan gbe iroyin ẹlẹjẹ kaakiri loju opo ayelujara pe Isa Ashiru lo jaweolubori.
O ni ''awa kii tẹle ahesọ ọrọ nitori gbogbo eeyan naa lo ti gbọ idajọ igbimọ. O ku sọwọ Ashiru lati fi igbagbọ rẹ sọdọ Ọlọrun.''
Gomina Uba Sani sọ pe awọn ko foya koda ki oludije PDP gba ile ẹjọ lọ lọjọ iwaju.
O ni ohun to jẹ awọn logunbayii ni kawọn tẹsiwaju mimu awọn adehun tawọn ṣe pẹlu araalu ṣẹ nipinlẹ Kaduna.
Esi ree lati ẹnu Isa Ashiru
Didakẹ ko tunmọ si pe a ko ni ku.
Bẹẹ ni oludije ẹgbẹ oṣelu PDP ninu ibo Gomina Kaduna ṣe fesi lẹyin idajọ igbimọ to n gbẹjọ gbe ọrọ wọn kalẹ.
O sọ pe 'igbimọ sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC kuna lati faaye gba Uba Sani lati dije du ipo ninu idibo to waye.
"Meji ninu awọn adajọ to gbe idajọ kalẹ sọ pe ki wọn gba iwe ẹri moyege ti Inec fun Uba Sani padda lọwọ rẹ ki wọn si tun idibo ṣe lawọn ibudo idibo kan ni ipinlẹ Kaduna''
Lafiku o ni ''a ti sọ fun agbẹjọro wa wi pe ko wo idajọ yi daada ki a baa le mọ nkan to kan ti a o ṣe bayii''
Ashiru sọ pe oun ko tori ara oun tako idajọ igbimọ bi kii ṣe tori awọn eeyan ipinlẹ Kaduna.
O lawọn yoo wo idajọ igbimọ ti ko ba si tẹ awọn lọrun awọn yoo tẹsiwaju lọ ile ẹjọ to tun kan lati tako ọrọ yi.
O ni igbesẹ akọkọ ree tawọn yoo gbe.
Ki gaan ni igbimọ sọ ninu idajọ wọn?
Igbimọ ẹlẹni mẹta to gbọ igbẹjọ awuyewuye labẹ idari adajọ Victor Oviawe sọ pe awọn olupẹjọ kọ lati tete gbe ẹjọ wọn wa laarin ọsẹ kan ti iwe ofin Naijiria la kalẹ.
Bẹẹ naa ni wọn sọ pe Uba Sani jare lori idahun rẹ pe ọrọ ti Isa Ahiru gbe wa siwaju igbimọ ko fẹsẹ mulẹ rara.
Wọn tun sọ pe kani awọn ko fọwọ rọ ẹsun ti Ashiru gbe wa danu ni, awọn ki ba sọ pe ki wọn ṣe atundi ibo lawọn aaye idibo mejlelogun kan ni Kaduna laarin aadọrin ọjọ ninu idajọ ipilẹ awọn.












