Wo àwọn fídíò àti fọ́tò àtàwọn ǹkan míì tó ṣàpèjúwe ìbúgbàmù tó ṣẹlẹ̀ nílé ìwòsàn Gaza

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Paul Brown
- Role, BBC Verify
Ibugbamu to dun laaarin awọn ero to wa ni ọsibitu Al Ahli to wa niluu Gaza ti pa awọn eeyan to le ni ọgọrun-un.
Ohun ti awọn ijọba Palestine ti awọn Hamas n ṣakoso rẹ sọ ni pe Israel lo mọ-ọn mọ ṣe ikọlu naa lati inu afẹfẹ, ṣugbọn ti Israel ti pada sọ pe awọn ko mọ nnkankan nipa ẹ.
Bi awọn orileede mejeeji yii ṣe n tako ara wọn lori ikọlu naa, o ti wa a di pe lati f’idi okodoro awọn to ṣe ikọlu naa mulẹ ko rọrun rara.
Iwadii BBC lati f’idi otitọ mulẹ - nipa wiwo bi nnkan naa ṣe ṣẹlẹ ṣi n dabi ala ati awọn ẹri miran, paapaa julọ awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn.
Ni afikun, akọroyin BBC ti lọ si agbegbe ti ikọlu yii ti waye, nibi ti wọn ko ti gba eeyan pupọ laye.
Gbogbo igba ni iwadii tuntun n jẹyọ, eyi ti yoo jẹ ka maa gbe e jade loore-koore bi a ba ṣe n ba awọn ọjọgbọn ati onimọ sọrọ nipa okodoro.
O tun ṣe pataki lati mọ pe bi ijakadi ṣe n waye, rogbodiyan yii n gbe oriṣiriṣiri iroyin jade.
Kii ṣe igba kọkọ ree ti ijọba Israel ati Gaza yoo ṣo ọrọ lori awọn ikọlu ibugbamu to ti waye.
Bẹẹ la si n ṣagbeyẹwo ohun ti onikaluku wọn sọ.
Ibugbamu naa
Ikọlu ibugbamu yii lo waye ni nnkan bi aago meje irọlẹ ọjọ Iṣẹgun.
Ninu fọnran oni ogun iṣẹju to lọ kaakiri ori ikanni ayelujara ṣe afihan bi ikọlu ọhun ṣe waye.
Ninu rẹ, ẹ maa gbọ iro bi ọfa ina ọhun ṣe n bọ, ko to di pe o balẹ, to si gbina nla.
Fọnran ti ileeṣẹ iroyin Al-Jazeera gbe jade ni deedee aago meje ku iṣẹju kan irọlẹ ṣafihan bi ina nla ṣe n bọ lati oju ofurufu ni oke Gaza.
O ṣee ṣe ko jẹ ina naa waye lati inu rọkẹẹti, ko too tuka. Ninu fọnrann naa, itanṣan kan la ri lati ọna to jinna, lẹyin ibugbamu to ṣẹlẹ nitosi ayaworan ti a ti mọ ibi to ti wa.
Ninu awọn fọnran miiran to jẹyọ lori ikanni ayelujara kaakiri ni a ti ri nnan to dabi ibugbamu loriṣirṣi ọna lati awọn ọna to jinna rere.

Oríṣun àwòrán, Reuters
A ti fọrọ wa awọn ọjọgbọn ati onimọ lẹnu wo bo ya awọn ẹri to wa larọwọto – paapaa odiwọn ibugbamu ati iro ti a gọ le jẹ ohun to fa a.
Ju gbobo rẹ lọ, iwadii ko tii pari.
Awọn ẹri to wa lọwọ BBC ko si ni ibamu ti a le sọ pe ikọlu naa waye lati ọdọ Israel.
Bi apẹẹrẹ, aisi ohun ti wọn pe ni ‘large bomb crater.’
Igbakeji ọjọgbọn ni fasiti Vanderbilt nile Amẹrika, J Andres Gannon, sọ pe ibugbamu naa ko tobi rara, eyi to tunmọ si pe ooru ti nnkan naa gbe wa fi han pe ajoku rọkẹẹti to waye lo tun pada jade.
Justin Bronk, to jẹ oniwadii agba ni Royal United Services Institute (Rusi) ni United Kingdom gba eyi gbọ. O ni “bo tilẹ ṣoro lati f’idi rẹ mulẹ, ẹri to wa nilẹ jẹ ko ye wa pe ibugbamu naa jẹ eyi to ṣẹlẹ lati inu rọkẹẹti ti wọn ti ta tipẹ, ti ko si dahun, ṣugbọn to wa pada gbe ina jade.
Ogbẹni Gannon ṣalaye pe ko ṣee ṣe lati sọ pe ibugbamu naa lọ sibi ti wọn ran an lọ.
Pupọ awọn ọjọgbọn ti a ba sọrọ ni wọn ko fẹẹ sọrọ lori erongba wọn nipa ohun to ṣẹlẹ.
Ẹri lati ibi ti igbugbamu ado oloro ti dun
BBC gbiyanju lati so ile ati ọsibitu Al Ahli pẹlu ikanni itagba satelite lati f’idi rẹ mulẹ boua ọsibitu naa ni ibi ti wọn ran ibugbamu naa si.
Nipasẹ awọn ẹri to wa ni arọwọto, o fi han wi pe agbala ọsibitu naa ni ibugbamu naa ti waye. Awọn aworan ilẹ lẹyin ibugbamu naa ko ṣafihan awọn agbegbe ọsibitu naa to bajẹ. Ohun ti a ri ni awọn ibi ti apa wa ati awọn ọkọ to jona.

Awọn ṣọọṣi Anglican lo ni ọsibitu naa, awọn naa si ni wọn n ṣakoso rẹ.
Canon Richard Sewell, alabojuto agba ni il-ẹkọ kọlẹẹji St George's to wa ni Jerusalem, sọ fun BBC pe awọn to to ẹgbẹrun kan ni wọn wa ni agbala ọsibitu naa, nigba ti awọn bii ẹgbẹta wa ninu ile ọsibitu naa lakoko iṣẹlẹ naa.

Abọ akọroyin BBC ree
Akọroyin BBC, Rushdi Abualouf ti lọ si ọsibitu naa laarọ oni.
O ti f’oju ri bi ikọlu naa ṣe ri, ati bi wọn ṣe n ṣe akọsilẹ awọn to ti ku.
Okunrin kan sọ pe awọn obinrin, awọn ọmọde ati awọn agbalagba ni wọn wa ni ọsibitu naa loko iṣẹlẹ ọhun.
A ṣi n ṣagbeyẹwo awọn aworan ati fọnran awọn to kagbako ijamba yii, nipa ohun ti wọn le sọ nipa nnkan to ṣẹlẹ nipasẹ apa ti wọn ni lara.
Akọroyin BBC, Rushdi Abualouf wa ni ibi ti iṣẹlẹ ibugbamu ti waye ni ọsibitu Gaza, nibi to ti sọ pe "Awọn eeyan ṣi n ko awọn ara eeyan jọ"

Ohun ti a ko tii mọ ree
Okan lara awọn ẹri to tun wa nilẹ ni ajoku ibugbamu naa ti wọn pe ni crater.

Awọn ologun Israel, iyẹn Israel Defence Forces (IDF) sọ pe crater nla ti ko si nibẹ, ati ikọlu to waye nitosi ile ọsibitu naa, fi han pe ibugbamu naa kii ṣe lati inu irinṣẹ ija oloro wọn.
Afikun iroyin last ọwọ: Daniele Palumbo, Joshua Cheetham, Tom Spencer ati Shayan Sardarizadeh












