Àwòrán bí ìwọ́de ṣe ń wáyé káàkiri àgbáyé lórí ìkọlù sí ilé ìwòsàn Gaza

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, By Andrew Webb
- Role, BBC World Service
Káàkiri àgbàyé ni àwọn ènìyàn ti ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn lẹ́yìn tí àdó olóró kan ṣekúpa ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Palestine ní ilé ìwòsàn kan ní Gaza.
Àwọn aláṣẹ Palestine ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹ̀mí ló bá ìkọlù náà lọ.
Dókítà kan ní Israel mọ̀ọ́mọ̀ ṣekúpa àwọn ènìyàn tó ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn Al-Ahli Arab Hospital, tí dókítà mìíràn sì ní ìkọlù ọ̀hún banilọ́kàn jẹ́ púpọ̀.
Àwọn aláṣẹ Palestine ní àdó olóró tí Israel jù lati ojú òfurufú ló balẹ̀ sí ilé ìwòsán náà.
Àmọ́ iléeṣẹ́ ológun Israel ní àdó olóró tí àwọn ikọ̀ ogun alákakítí ẹ̀sìn Islam Palestine jù ló yíwọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́ tó sì fa ìkọlù náà - ṣùgbọ́n ikọ̀ náà ti jiyàn rẹ̀.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ológun Israel, Daniel Hagari ní àwọn ní ẹ̀rí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀, pé àwọn gbọ́ nípa bí ọmọ ikọ̀ Hamas ṣe sọ pé àdó olóró tí àwọn jù kan kò lọ bó ṣe yẹ.
Hagari ní fídíò wà láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Israel kọ́ ló ju àdó olóró náà sí ilé ìwòsàn ọ̀hún.
Agbẹnusọ ikọ̀ Hamas, Bassim Naim sọ fún BBC pé àwọn kò ní àdó olóró tó lágbára tó bẹ́ẹ̀ tó èyí tó balẹ̀ sí ilé ìwòsàn náà.
Lebanon: Beirut

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ẹgbẹ́ òṣèlú, ọmọ ogun àti àwùjọ Hezbollah ti bèèrè fún ọjọ́ kan láti fi ìbínú wọn lọ́jọ́rú.
Àwọn èrò tó pọ̀ ya sí gbogbo òpópónà.

Oríṣun àwòrán, AFP
Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò àtàwọn olùfẹ́hónúhàn ṣe ìkọlù síra ní ọ̀sán ọjọ́rú ní ẹ̀gbẹ́ iléeṣẹ́ Amẹ́ríkà tó wà ní Beirut.

Oríṣun àwòrán, EPA
Ṣaájú, nígbà tí ìwọ́de náà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ileeṣẹ́ Amẹ́ríkà lálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Hezbollah bu ẹnu àtẹ́ lu ohun tí wọ́n pè ní “ìkọlù Israel” sí ilé ìwòsàn Gaza.
Jordan: Amman

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ìwọ́de ń tẹ̀síwájú mí Jordan bí àwọn ènìyàn ṣe ń gbìyànjú láti ya wọ iléeṣẹ́ Amẹ́ríkà tó wà ní Jordan.
Ààrẹ Amẹ́ríkà, Joe Biden ṣẹ́wélé àbẹ̀wò tó fẹ́ ṣe lẹ́yìn ìkọlù náà.
Tunisia: Tunis

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn olùfẹ̀hónúhàn kún iwájú iléeṣẹ́ France, tí wọ́n sì ń fi ẹ̀sùn kan France pé ó wà lára àwọn orílẹ̀ èdè àgbàyé tó ń ti Israel lẹ́yìn láti ṣe ìkọlù sí Palestine.
Àwọn mìíràn ń pe àwọn ará orílẹ̀ èdè Áráàbù yòókù láti fọwọ́sowọ́pọ̀.
Colombia: Bogota

Oríṣun àwòrán, EPA
Àwọn èrò tún ti ń ṣe ìwọ́de ní Latin Amẹ́ríkà.
Ní òlú ìlú Colombia, Bogota, àwọn olùwọ́de gba gbogbo ọ̀nà kan láti fi ẹ̀hónú wọn hàn.
Israel ti dá kíkó àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò lọ sí Colombia dúró lẹ́yìn ọ̀rọ̀ tí ààrẹ Colombia sọ níbi tó fi ìkọlù tí Israel ń ṣe sí Gaza wé Nazi Germany.
West Bank: Ramallah

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun sí òwúrọ̀ ọjọ́rú ní ìlú Ramallah, àwọn olùwọ́de dáná sí ojú ọ̀nà, tí gbogbo ọ̀nà pa, tí wọ́n sì ń sọ òkò lu àwọn ọlọ́pàá.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn ọlọ́pàá Palestine kojú àwọn olùwọ́de.
West Bank: Nablus

Oríṣun àwòrán, EPA
Àwọn èrò péjọ sí Nablus.
Ìpéjọ àwọn ènìyàn ló ń ṣàfihàn ìbínú àwọn ènìyàn Palestine sí ààrẹ wọn, Mahmoud Abbas tí wọ́n ti ń bu ẹnu àtẹ́ lù pé ó ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lu Israel lórí ọ̀rọ̀ ààbò ní ẹkùn náà.
Turkey: Istanbul

Oríṣun àwòrán, EPA
Àwọn ìlú káàkiri Turkey ni ìfẹ̀hónúhàn ti ń wáyé.
Ààrẹ Tayyip Erdogan júwe ìkọlù sí ilé ìwòsàn Gaza bí èyí tó ń ṣàfihàn pé Israel kò ní àánú àwọn ènìyàn lórí àwọn ìkọlù rẹ̀ sí Gaza.

Oríṣun àwòrán, EPA
Àwọn ọlọ́pàá lo afẹ́fẹ́ tajútajú láti tú àwọn olùfẹ̀hónúhàn tó fẹ́ ya wọ ilé iṣẹ́ Israel tó wà ní Istanbul.
Iléeṣẹ́ gómìnà Istanbul ní ènìyàn márùn-ún ló ti wà ní àhàmọ́ àwọn.
USA: Boston

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn olùwọ́de péjọ sí ilé ìkàwé Boston láti bá àwọn ènìyàn Palestine tó pàdánù ẹbí wọn sínú ìkọlù Gaza kẹ́dùn.
Ní iwájú iléeṣẹ́ Israel orílẹ̀ èdè náà ni wọ́n ti dúró níbi tí wọ́n ti ń kọrin, tí wọ́n sì ń jó.
Morocco: Rabat

Oríṣun àwòrán, EPA
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùfẹ̀hónúhàn wọ́de káàkiri ìlú Rabat.
Àwọn olùwọ́de náà pè fún títi iléeṣẹ́ Israel tó wà níbẹ̀ pa.












