Kí ni ẹnubodè Rafah, kí ló fi ṣe pàtàkì fún Gaza?

Awọn ọmọ orilẹ ede Palestine ti n pejọ niwaju ẹnubode Rafah to jẹ aala rẹ pẹlu Egypt ni ẹkun gusuu Gaza ni ireti pe awọn yoo ti kọja si Egypt ṣaaju ki Israel to ṣe akọlu gba ti inu ilẹ to n gbero.
Ileeṣẹ iroyin Amẹrika kan ni Egypt ni ohun maa ṣi ọna naa fawọn orilẹ-ede meji lati jade kuro ati fun awọn to ba fẹ se iranwọ fun awọn eniyan lati wọle, ṣugbọn wọn ko mu ẹnu ba igba ti yoo jẹ.
Sibẹ, ẹnubode naa si wa ni titi pa titi di owurọ ọjọ Aje.
Ki ni ẹnubode Rafah?
Ohun ni ẹnubode to ṣe e gba kọja ni ẹkun guusu Gaza si aṣalẹ Sinai ni Egypt.
Awọn ẹnubode meji miiran lo tun wa lati wọle jade si Gaza - Erez, to so Gaza pọ mọ Israeli ni ariwa Gaza, ati Kerem Shalom, orita to wa fun iṣowo laaarin Israeli ati Gaza. Awọn ọna mejeeji ti wa ni titi pa.
Ki ni idi ti ẹnubode Rafah ṣe pataki bayii?
Awọn ọmọ ogun Hamas kọlu awọn ẹnubode Erez ni ariwa Gasa ni ọjọ keje Oṣu Kẹwaa, ti wọn si ba a jẹ gidi gan. Lẹyin ọjọ diẹ, Israel kede titi Erez pa fun igba kan na, leyii to sọ ẹnubode Rafah di ọna kan ṣoṣo ti wọn le gba jade ati wọle si Gaza.
Rafah tun jẹ ọna ti awọn to n se iranlọwọ fawọn eniyan n gba kọja. Lọsẹ to kọja, ile-iṣẹ to n risi ọrọ ilẹ okere nilẹ Egypt sọ pe awọn n dari awọn ọkọ ofurufu ilẹ okere to fẹ ṣe iranwọ fawọn eniyan Gaza si papakọ ofurufu al-Arish ni ariwa Sinai, ti awọn ọkọ to gbe epo ati awọn ẹru iranwọ ti wa nitosi ẹnubode Rafah, ti wọn n duro lati gba wọn laaye lati kọja.
Ki ni o n ṣẹlẹ ni ẹnubode naa?
Lati igba ti Hamas ti bẹrẹ ikọlu si Israeli ni ọjọ keje Oṣu Kẹwaa, oniruuru iroyin ni wọn ti gbe nipa ẹnubode naa. Hamas ati Egypt lo n ṣakoso awọn to le gba ọna naa kọja, ṣugbọn Israel da eto naa ru nipasẹ bi o ṣe ju ado oloro si awọn agbegbe to yika.
Ile-iṣẹ iroyin Egypt kan sọ pe ẹnubode naa di titi pa latari awọn ikọlu mẹta Israel ti wọn ṣe si Rafah ni ọjọ kẹsan ati ọjọ kẹwaa Oṣu Kẹwaa, eyi ti o ṣe ipalara fun Egypt ati Palestine ti wọn wa ni agbegbe ẹnubode ọhun.
Ni ọjọ kejila Oṣu Kẹwaa, ijọba Egypt ni ki Israel da awọn ikọlu afẹfẹ to n ṣe nitosi ẹnubode Rafah duro ki o le ṣe atilẹyin fun awọn eniyan ni Gaza, to si ni oun ko ni ṣi ẹnubode naa ti awọn ko ba ri idaniloju pe aabo yoo wa fun awọn oṣiṣẹ rẹ.
Awọn orilẹ-ede Iwọ-Oorun tun n kopa lati ri daju pe Rafah jẹ ọna to ṣe e gba fun awọn ti o ni iwe irinna ilẹ okere lọwọ ni Gaza ati lati ran awọn eniyan lọwọ.
Akọwe orilẹ-ede Gẹẹsi, James Cleverly ati akẹgbẹ rẹ lati orilẹ-ede Amẹrika, Antony Blinken sọ pe wọn n ṣiṣẹ pẹlu Israel, Egypt ati “awọn alẹnulọrọ ninu oselu miiran ni ẹkun naa” lati ṣi ẹnubode naa.
Ni ọsẹ to kọja, agbẹnusọ ilẹ Amẹrika sọ pe awọn sọ fun awọn ọmọ orilẹ ede wọn lati lọ si Rafah nitori "o ṣeeṣe ki ipolongo ma wa ti wọn ba ṣi ẹnubode naa ati pe o ṣeeṣe ki akoko ti wọn fi maa ṣi kere”.
Ni ọjọ Aje, awọn eniyan pejọ siwaju ẹnubode Rafah lati wa wo bowa ẹnu ọna naa le jẹ ṣiṣi fun igba diẹ pe wọn ti gba lati dawọ ogun duro fun igba diẹ amọ Israel ati Hamas jiyan ọrọ naa.
Ki ni idi ti ẹnubode naa ṣe wa ni titi pa?
Israel fẹ dena ikọ ọmọ ogun Hamas lati ni anfani ati kuro ni Gaza, ti wọn si fẹ ṣayẹwo gbogbo awọn ọkọ to fẹ wọ Gaza lati rii daju pe wọn ko gbe awọn ohun ija ogun wọle.
Ẹwẹ, bi o tilẹ jẹ pe o jọ wi pe Egypt n fọwọsowọpọ pẹlu awọn orilẹ-ede miiran ni idunadura lati ṣi ẹnubode naa fun awọn ti o mu iwe irinna ilẹ okere lọwọ ati lati ṣe iranlọwọ fun awọn eniyan naa, ijọba Egypt n wa ọna lati dẹkun bi awọn ara Palestine ko ṣe ni yawọ Sinai.
Bakan naa lo n kọminu pe awọn alakatakiti ẹsin tun le wọ orilẹ ede naa.
Bawo ni wọn ṣe maa n lo ẹnubode naa tẹlẹ?
Rafah kii gba ki awọn Palestin gba ibẹ kuro ni Gasa ni irọrun.
Awọn ara ilu Palestine to ba fẹ gba ẹnu ibode naa jade gbọdọ forukọsilẹ pẹlu awọn alaṣẹ Palestine fun bi ọsẹ meji si mẹrin ṣiwaju irinajo wọn to si ṣeeṣe ki wọn kọ lati ma gba ki wọn gba ibẹ kọja latọwọ Palestine tabi Egypt pẹlu ikilọ.
Gẹgẹ bi ajọ UN, ni Oṣu Kẹjọ ọdun 2023, awọn alaṣẹ Egypt gba awọn eniyan to le ni 19,608 laaye lati jade ni Gaza to si ṣe idena fun awọn eniyan 314 lati wọle.














