Àwọn olùgbé Gaza kan kọ̀ láti f'ìlú sílẹ̀ bí Isreal ṣe ń gbáradì láti bẹ̀rẹ̀ ikọlù abẹ̀ ilẹ̀

Awọn mọlẹbi kan taku, wọn ni awọn ko ni i kuro ni Ariwa Gaza bi Isreali ṣe n pete ati ko wọn kuro lalaafia.
Gbedeke akoko ti orilẹ ede Israel fun awọn olugbe ariwa Gazalati kuro ni agbegbe naa ti kọja, ṣugbọn awọn kan ninu awọn eniyan naa sọ pe ko si ibi ti awọn n lọ.
Gbedeke akoko ti Israel fun awọn eniyan ariwa Gaza ti kọja, ṣugbọn awọn olugbe agbegbe naa kan bii Mohamed Ibrahim, ni awọn ko ni lọ si ibi kankan.
Mohamed, ẹni ọdún mejilelogoji, sọ pe oun ko ni fi ilu oun silẹ, ati pe ko si ibi ti oun n lọ.
O jokoo sinu yara kan pẹlu awọn ẹbi ati ibatan ti wọn wa a wa lati agbegbe miiran wa, awọn kan ninu wọn n rojọ, ti awọn miiran si n woju awọn ẹrọ ibaraẹni ṣọrọ wọn lati mọ nipa awọn iroyin to n lọ lori ikọlu to n waye laaarin orilẹ ede wọn ati Israel.
“Emi ko le sa lọ si ilu miiran koda ti wọn ba fẹ run ile mọ wa lori, ibi yii ni maa wa.”
Mohamed atawọn ẹbi rẹ o ti rin yika gbogbo agbegbe ti o yi Ilu Gaza ka.
“Nigba ti ado oloro n dun lakọlakọ ni nnkan bii aago meji oru lọjọ Aiku, emi, iyawo àtawọn ọmọ mi mẹrin fẹsẹ fẹ.”
Wọn fi ile wọn silẹ ni Jabalia lọ si agbegbe Sheikh Radwan, ṣugbọn wọn gbọ pe agbegbe naa yoo ni idojukọ ikọlu lorisirisi, ti wọn si tun gbabọ lọ si eti Ilu Gaza kan.
O ni oun ko ro pe o jẹ ohun to tọna fun wọn lati kuro ni ariwa Gaza, gẹgẹ bi ikilọ Israeli pe ki awọn eniyan ko kuro.
“Wọn ni ka lọ si guusu Gaza, nibo ni emi ati ẹbi mi yoo lọ?" Mohamed beere.
Awọn ọmọ rẹ n safẹku ọgba wọn. Ọmọ rẹ Ahmad ti o fẹran lati ma wa kẹkẹ ni ayika adugbo wọn pẹlu ọrẹ rẹ. O n beere lọwọ baba rẹ boya ọrẹ oun si wa laaye bii, ṣugbọn ko si ọna lati de ọdọ rẹ.
Ko si aye

Ni agbegbe kan ni ẹgbẹ ọdọ rẹ, Abo Jameel, ẹni ọdun medinlogoji n wa bi o ṣe maa ri omi ninu opa omi kan to wa nilẹ.
“Fun ọjọ mẹjọ bayii ko si ounjẹ tabi omi,” o sọ pe Israel ti ge ina mọnamọna ati omi ni Gaza, ti wọn si faaye gba epo rọbi ati awọn ohun amayedẹrun miiran lati wọ ibẹ.
Jameel fi kun pe “Ko si omi, ko si ina, ko si igbesi aye to rọnu ati pe ninu ibanujẹ oun pẹlu awọn ọmọ rẹ marun-un ti wọn pinnu lati duro wa. O ni ọmọkunrin meji ati ọmọbirin mẹta.
"O fi kun pe ki si ilu to dabi ilu o un ti awọn ko si ni kuro ninu ilu naa koda ki wọn fẹ gba ẹmi awọn.
Awọn ọmọ ogun n gbaradi
Hamas sọ pe eeyan to le ni 400,000 ninu awọn eniyan 1.1 milionu ti wọn n gbe ni ariwa Gaza ni wọn ti kuro ninu ilu naa latari aṣẹ ti ilẹ Israeli pa fun wọn.
O ṣeeṣe ki Isreal ṣe ikọlu si wọn lati ilẹ laipẹ.
Awọn ile-isẹ iroyin ni agbegbe naa ọkan lara awọn ikọ ọmọ ogun Hamas ti o farapamọ ni agbegbe naa ni wọn pa.
Ilu Sderot ni Israel ni ko si awọn eniyan kan nibẹ mọ lẹyin ti awọn alaṣẹ ti ni ki gbogbo wọn fi agbegbe naa silẹ.
Kaakiri gbogbo agbegbe naa ni awọn ọmọ ogun wa ti eyi ko si le ṣẹyin bi olootu ijọba Israel, Bejamin Netanyahu ti jẹjẹẹ lati fopin si ikọ ọmọ ogun Hamas léyin ti wọn ṣe ikọlu si wọn.
Gbogbo ilero ti owọ inu ilu naa ni wọn ti n gbo ariwo bi iho ibon se n dun lakọlakọ ti gbogbo awọn oju opopona si kun fun awọn ọmọ ologun ti wọn di ra wamuwamu
Eeyan to le ni 1,300 lọ ti wọn ti jade laye ni ilẹ Israeli latari ikọlu aala to waye ni ilẹ naa, ti wọn si fi 126 si ahamọ.
Bakan naa ni awọn to ti padanu ẹmi wọn ni Palestine ti wọ 2,383 ti awọn to si farapa ti wọ 10,184 gẹgẹ bi iroyin ti ileeṣẹ eto ilera Palestine fi lede.
Awọn ti ogun yika

Awọn ọmọde Ilu Gaza si n ṣere ni oju opopona titi di asiko yii bi wọn ṣe n lo asiko ti gbogbo nnkan fi lọ silẹ yii lati ṣere.
Bi idaji awọn olugbe Gaza ni ọjọ ori wọn ko i tii pe ọdun mejidinlogun ti awọn ọmọde too si ti ba ogun lọ ti le ni 700.
Awọn alaṣẹ Hamas ti ni ki awọn eniyan ma kuro ni ariwa Gaza lati maa lo wọn gẹgẹ bi ohun idaabobo lọwọ ikọlu amọ ikọ Hamas jiyan eyi.
Ti Israel ba tẹsiwaju lati ṣe ikọlu si ariwa Gaza lati inu ilẹ, o ṣeeṣe ki ija tẹsiwaju fun ọpọ oṣu to si le pa agbegbe naa run patapata.
Ẹgbẹẹgbẹrun awọn ara ilu lo ṣeeṣe ki wọn ba ikọlu naa lọ.












