Tani-Olorun wọ wàhálà tuntun n‘Ilorin, Alfa míì pè é lẹ́jọ́ síléẹjọ́ kẹta

Tani Olorun ati osisẹ ọgba ẹwọn

Wahala tuntun ti bẹrẹ fun Abdulazeez Adegbọla ti ọpọ mo si Tani-Ọlọhun, Alfa miran lo sẹsẹ pè é lẹjọ ni Majisireeti fun ẹsun ibanilorukọ jẹ.

Iyalẹnu nla lo jẹ lati ba Tani-Ọlọhun ni ile ẹjọ loni ọjọ Isẹgun Tusidee, lọtẹ yii, iwaju Magistrate Muhammed Adam ni wọn wọ wa fun ẹsun ibanilorukọjẹ

Agbẹjọro Taofiq Ọlatẹju ti o fi iwe igbẹjọ toni lede lorukọ onibara rẹ, Alfa Labeeb Lagbaji fẹsun kan Tani Ọlọhun wi pe, o fi awon akanti facebook ati Twitter rẹ ba onibara oun lorukọ jẹ.

Awọn ẹsun onigba mẹta ti wọn fi kan an ni, ibanilorukọjẹ, dida omi alaafia ru ati ẹsun iwa ọdaran piparọmọni lọna aitọ.

Tani Olorun ati osisẹ ọgba ẹwọn

Tani Ọlọhun fi ọrọ rẹ ninu fidio to gbe sori ayelujara ba ohun gbogbo ti mo fi ọjọ aye mi ko jọ jẹ tori ọpọ eniyan lo n wo fidio naa lojojumọ - Alfa Lagbaji

Iwe ipẹjọ naa tun ka wi pe, Alfa Labeeb Lagbaji jẹ onimọ ẹṣin Islam, ti o si lokiki kaakiri agbaye.

Gẹgẹ bi ìwé ipẹjọ naa ti sọ, Tani Ọlọhun sọ ọ lori ayelujara pe Alfa Labeeb Lagbaji mu arabinrin alarun ọpọlọ kan ti wọn mu wa fun itọju lọdọ rẹ, lọ si inu ile akọku lati ba a ni ajọsepọ.

Amọ agbẹjọro Taofiq Ọlatẹju ninu ọrọ rẹ sọ fun ile ẹjọ pe, onibara oun jẹ eeyan to ni orukọ rere lati ile rere.

Sugbọn o ni Tani Ọlọhun fi ọrọ rẹ ninu fidio naa ba ohun gbogbo ti oun fi ọjọ aye oun ko jọ jẹ nitori pe ọpọlọpọ eniyan lo n wo fidio naa lojojumọ.

Tani-Ọlọhun ko ni agbẹjọro fun ẹjọ yii nitori pe ẹjọ naa ba a lojiji, ko si mura de e rara, sugbon o fi ẹnu ara rẹ sọrọ wi pe oun ko jẹbi ẹsun naa.

Lẹyin to ti gbọ ọrọ lẹnu awọn mejeji, Magistrate Muhammed Adam wa sun igbẹjọ sii oṣu kọkanla ọdun yii.

Ikọ̀ olùpẹ̀jọ́ àti olùjẹ́jọ́ lórí ìgbẹ́jọ́ Tani-Olorun, Oluwo Tede fẹ́ jókòó ṣèpàdé àlááfìà

Ikọ agbẹjọro nile ẹjọ

Ni Iléẹjọ́ Upper Area to wa nilu Ilorin, isẹlẹ nla lo waye nibẹ lori igbẹjọ ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan onisẹse kan, Abdulazeez Adegbọla, ti ọpọ mọ si Tani-Olorun.

Idi ni pe agbẹjọro Ademola Banks, ti o jẹ olori ikọ agbẹjọro fún Tani-Ọlọhun ati KS Adegoke, to n soju fun Oluwo Nla Ilu Tede, Oloye Ademola Olawoore, ti fi iwe alafia sita fun ile ẹjọ.

Eyi waye lonii ọjọ Aje ni ile ẹjọ Upper Area ti o kalẹ si ilu Ilọrin, nibi ti awon onisẹse mejeeji ti n jẹjọ ẹsun ibanilorukọ jẹ ti Alfa Okutagidi fi kan wọn.

Adajọ ile ẹjọ ọhun, Honourable Sunday Adeniyi si sun igbẹjọ lori ẹbẹ alafia naa si ọjọ kẹtala osu kọkanla, Belu ọdun 2023.

"Ileẹjọ, ẹ gba wa laaye lati lọ se ipade alaafia, ka le yanju ẹjọ wa nitunbi n nubi"

Agbẹjọro olupẹjọ, US Imam lo sọ fun ilé ẹjọ pe, ohun gba ipe latọdọ agbẹjọro olujẹjọ akọkọ, Ademola Banks ni ana.

O ni koko ipe naa lo da lori ẹbẹ onibara rẹ, Tani-Olorun pe ki wọn ṣe ọrọ naa ni tubi n nubi.

US Imam sọ wi pe gẹgẹ bi Musulumi, awọn ko lee tako ẹbẹ idoola aawọ naa nitoripe ẹṣin awon faye gba a.

Ninu ọrọ rẹ, Ademola Banks sọ fun ile ẹjọ wi pe igun mejeeji ti pinu lati pari ẹjọ naa sibi ipade alaafia gẹgẹ bi US Imam ti sọ.

O wa rọ ile ẹjọ lati fun wọn ni ọjọ tuntun lati pada wa jabọ fun ile ẹjọ lori ibi ti eto alaafia naa de duro.

Adajọ sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹtala osu Kọkanla ki igun mejeeji le joko ipade alaafia

Ẹwẹ, Agbẹjọro fun olujẹjọ keji, KS Adegoke naa sọ fun ile ẹjọ wi pe ohun ati onibara ohun naa ti pinu ki ọrọ naa yanju ni ọna alaafia.

O ni koda, onibara ohun ti wa ni ilu Ilọrin lati ana lori eto alaafia naa.

Adajọ to n gbọ ẹjọ naa, Sunday Adeniyi gba si wọn lẹnu, to si sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹtala osu kọkanla ọdun 2023 lati gbọ abọ lori ipade alafia ọhun.

Àkọlé fídíò, Loan Apps: Ọ̀pọ̀ oníbàráà iléeṣẹ́ ayánilówó lórí ayélujára kú torí fọ́tò ìhòhò wọn níta

Ǹ jẹ́ àwọn agbẹjọ́rò Tani-Olohun yóò tún tako ara wọn nílé ẹjọ́ lónìí?

Aworan Tani Olohun ati awọn agbẹjọro

Abdulazeez Adegbọla ti wọn n pe ni Tani Ọlọhun yoo tun foju ba ile ẹjọ Upper Area lonii ọjọ Aje fun ẹsun ibanilorukọ jẹ ti wọn fi kan an.

Awọn agbẹjọro to n soju Tani-Olorun ni wọn n se atako rẹ ṣe si ara wọn ni ile ẹjọ Majisireeti lasiko igbẹjọ naa to kọja.

Lasiko iigbẹjọ to kọja yii nile ẹjọ ti fun eekan onisẹse naa ni beeli, to si gba oniduro rẹ.

Sugbọn sibẹ, ko tii gbominira nitoripe ẹjọ rẹ ni Majisireeti ko tii lojuutu titi di asiko yii.

Amọ loni nile ẹjọ Upper Area to wa nilu Ilorin, a o mọ boya iwe ẹbẹ ti awon agbẹjọro naa fi sita nile ẹjọ Majisireeti, ni wọn yoo tun gbe silẹ nile ẹjọ tabi wọn yoo tun gba ọna miran yọ.

Olujẹjọ naa loti fẹ ẹ lo aadọrin ọjọ ni ahamọ ijọba bayii, a o si mọ ọjọ ti yoo to dominira.

Ki lo waye nibi igbẹjọ Tani Olorun lọsẹ to kọja?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Koko ohun to waye nibi igbẹjọ ọsẹ to kọja lo wa lati mọ boya ile ẹjọ naa ni aṣẹ lati joko gbọ ẹsun yii ati ọrọ bi wọn yoo ṣe gba beeli ilumọọka oniṣẹṣe naa.

Sugbọn iṣẹlẹ to waye laarin awọn agbẹjọro rẹ mu ki adajọ majisireeti to n gbọ ẹjọ naa, Ibrahim Muhammed, binu dide, to si sun igbẹjọ siwaju.

Amọṣa, aigbọraẹniye tun waye laarin awọn agbẹjọro meji to n soju Tani-Olorun nile ẹjọ.

Awon amofin mejeeji naa ni Amofin Muftau Olobi ati Ademola Banks.

Agbẹjọro Olobi si lo kọkọ dide nibi igbẹjọ to kọja lati fi ara rẹ han, o si tun fi Ademola Banks han fun ile ẹjọ.

O ni iwe méjì ni awon ti gbe siwaju ile ẹjọ, ọkan fun gbigba beeli olujẹjọ naa, iwe ekeji si jẹ atako pe ile ẹjọ ko ni asẹ lati gbọ ẹjọ naa.

Amofin Olobi tẹsiwaju pe awon ti fi ẹnu ko lati fa iwe ti awọn pe tako boya ile ẹjọ naa ni aṣẹ lati tẹsiwaju lori igbẹjọ naa,

O ni ohun ti awọn fẹ gbaju mọ bayii ni ti titẹsiwaju pẹlu igbesẹ beeli ati gbigba oniduro fun olujẹjọ naa.

Bi o se n sọ ọrọ iyi ni Amofin Ademola Bank dide, o ni oun lo yẹ ko sọrọ nipa jijọwọ iwe atako ti oun pe fun, niwon igba ti oun wa ni ile ẹjọ.

O fi kun un pe, oun lo ti n ba ẹjọ naa bọ, ti o si yẹ ki Amofin Olobi to sẹsẹ de sinu ẹjọ fara balẹ lati gbọ agbọye lori rẹ.

Eleyi lo di awuyewuye laarin awọn mejeji, ti adajọ fi binu dide, ni wọn ba so igbẹjọ naa rọ si oni ọjọ Aje.