Iléẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ Tani Olorun síwájú sí ọjọ́ kọkànlá oṣù yìí; Ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé

Ileẹjọ Upper Area Court to n joko niluu Ilorin ti sun igbẹjọ lori Gbajugbaja oniṣẹṣe, Abdulazeez Adegbọla ti ọpọ mọ si Tani Ọlọhun ati Oloye Ademọla Ọlawoore tii ṣe Oluwo ilu Tende siwaju si ọjọ kọkanla, oṣu yii.
Awon onisẹse wọnyi lo n jẹjọ fun ẹsun igbimopọ, itabuku, ibanilorukọ jẹ ati dida rogbodiyan silẹ, eyi ti o lodi si ofin orilẹede Naijiria ti Alfa Okutagidi fi kan wọn.
Igbẹjọ toni jẹ ẹkẹẹta ti Tani Olọhun yoo jẹ lati igba ti won ti bẹrẹ ẹjọ rẹ ni ọjọ kẹtadinlogun osu kẹjọ ọdun yii.
Agbẹjọro to n ṣoju fun Tani Ọlọhun ati Oluwo ti Tende, ti fi iwe atako fun ẹjọ sita fun Ileejo.
M.P Ogele ti o jẹ adari agbarijọ amofin fun Tani Ọlọhun ati Oluwo ti Tende sọ pe igbẹjọ ni ileẹjọ naa jẹ makaruru nitori ko ba ofin mu ki olugbẹjọ akọkọ tii se Tani Ọlọhun maa jẹjọ ni ile ẹjọ meji ọtọọtọ lori ẹsun kan naa.
O rọ ile ẹjọ ki wọn da ejọ naa nu ki won si pa ọkan pọ si igbẹjọ ti ile ẹjọ Majisireeti.
Agbẹjọro fun olupẹjọ sọ wipe, ko ba ofin mu ki wọn da ẹjọ naa nu nitori pe esun le jọ arawon lootọ sugbon awon eniyan ọtọọtọ lo fi ẹsun kan wọn.
O tẹ siwaju pe Tani Olọhun nikan lo wa fun igbẹjọ Majisireti ṣugbon oun ati Oluwo ti Tende ni won pe lẹjọ ni ti eleyi, to tumo si wipe ọtọọtọ ni ẹjọ mejeeji.
O wa gba ile ẹjọ ni iyanju pe ki o pase ki won san owo itanran fun fifi akoko ile ẹjọ sofo.
Lẹyin ti adajo Sunday Adeniyi ti kọkọ kede isinmi isẹju mewa fun asọyepọ laarin awon agbẹjọro mejeeji, o sun igbẹjọ naa si ọjọ Aje, ọjọ kọkanla osu kẹẹsan ọdun yii fun idajọ.















