Ṣé òótọ́ ni pé ayédèrú ìwé ẹjọ́ ni wọ́n fi rán ‘Tani Ọlọ́hun’ lọ s’áhámọ́ fún ẹ̀sùn bíba àwọn Alfa Ilorin lórúkọjẹ́

Aworan Tani Ọlọhun ati awọn eeyan kan ni ile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, facebook/bbc

Iroyin ti n kaakiri pe ayederu iwe ipẹjọ ni awọn agbofinro fi gbe gbajumọ sọrọsọrọ kan to n gbe lẹyin awọn oniṣẹṣe ni ipinlẹ Kwara, paapaa ilu Ilọrin, Ọgbẹni Adegbọla Abdulazeez ti ọpọ mọ si Tani Ọlọhun.

Tani Ọlọhun foju ba ile ẹjọ ni Ọjọbọ to kọja lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan an lori bi wọn ṣe ni o sọ awọn ọrọ kan to ta ẹrẹ ba aṣọ awọn alufaa kan ni ilu Ilọrin.

Lọjọbọ yii naa ni ile ẹjọ ran an lọ si ahamọ lọgba ẹwọn di oṣu kẹwaa fun igbẹjọ rẹ.

Láti bí ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn ni awuyewuye ti ń wáyé láàárín àwọn Alfa ìlú Ilorin àti àwọn Oníṣẹ̀ṣe lórí ọ̀rọ̀ ọdún Ìṣẹ̀ṣe tó wáyé ní ilẹ̀ Yorùbá ní ogúnjọ́ oṣù Kẹjọ.

Ṣáájú ayẹyẹ ọdún yìí ni ìfaǹfà ti ń wáyé àwọn láàárín àwọn Alfa àti àwọn Oníṣẹ̀ṣe, tí wọ́n sì ń sọ òkò ọ̀rọ̀ síra wọn.

Lára àwọn ìfaǹfà yìí ló ṣokùnfà bí ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ Ilorin kan ṣe dìde láti fi ṣìnkún òfin gbé àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó ń ba àwọn Alfa Ilorin lórúkọ jẹ́.

Ìgbésẹ̀ wọn yìí ló fá a bí wọ́n ṣe fi òfin gbé Oníṣẹ̀ṣe kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adegbola Abdulazeez tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí ‘Tani olohun.’

‘Ayederu iwe ipẹjọ ‘warrant of arrest’ ni wọn fi pe Tani Ọlọhun lẹjọ’

Amọṣa iroyin to n jade bayii ni pe ayederu ni iwe ipẹjọ ti wọn fi gbe e lọ si ile ẹjọ naa.

Láti ìgbà tí ‘Taniolohun’ sì ti wà ní àhámọ́ ni àwọn kan ti ń fẹ̀sùn kàn pé ọ̀nà àìtọ́ ni wọ́n fi mú Talolorun sí àhámọ́.

Lára àwọn tó n pariwo sita bayii pe ọna àìtọ́ ni wọ́n fi mú ‘Tani Ọlohun’ ni olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú African Action Congress, Omoyele Sowore.

Sowore ní àṣẹ irọ́ ni àwọn tó fi òfin gbé Talolorun gbà láti ilé ẹjọ́ àdúgbò kan, tí wọ́n sì tún fẹ́ máa ṣe ẹjọ́ rẹ̀ láì lo olùpẹjọ́ kankan.

Ohun ti Sowore ko oju opo Facebook re

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ninu atẹjade kan to fi si oju opo ayelujara rẹ, Ṣoworẹ sọ pe gbarọgbudu ni iwe ipẹjọ naa ati pe ile ẹjọ agbegbe kan ni wọn ti lọ gba a.

Bakan naa lo tun ṣalaye pe awọn ‘alagbara kan’lo wa ni idi igbesẹ ati ran an l si ẹwọn lọna ti ko ba ofin mu.

O ni awọn eeyan naa pẹlu tun ti n tẹ ijọba ninu lati fun awọn laṣẹ lati funra wọn ṣe ẹjọ rẹ lai lọwọ ileeṣẹ eto idajọ ninu.

Ọlọpaa ko mọ si ipẹjọ ‘Tani Ọlọhun’, awọn Alfa lo lọ mu u ti wọn si funrawọn gbe e lọ si ile ẹjọ - Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa

BBC kan si ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, gẹgẹ bi ileeṣẹ to laṣẹ lati pe eeyan lẹjọ tabi jofin lati lee mọ boya lootọ ni pe ayederu iwe ifinisun ‘Warrant of arrest’ ni wọn fi gbe ẹlẹsin iṣẹṣe naa.

Ohun ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi sọ ni pe, ileeṣẹ ọlọpaa ko mọ ohunkohun nipa bi wọn ṣe lọ mu arakunrin naa nile ati bi o ṣe di ero ile ẹjọ ti adajọ fi fi si ahamọ di ọjọ karun un oṣu kẹwaa.

O ni awọn alfa kan lo tọ ile ẹjọ lọ lati gba iwe ifisun ijọba ‘Warrant of arrest’ ti wọn fi lọ mu u funra wọn ti wọn si fa a le ile ẹjọ lọwọ lẹsẹkẹsẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni bi ẹnikẹni ba ni ariwisi kankan nipa iwe ifisun naa, kiiṣe ọdọ ọlọpaa lo yẹ ki wọn wa, bikoṣe ile ẹjọ gan an.

Igba ti ọlọpaa ko da wa lohun la fi tọ ile ẹjọ Majisiereeti lọ fun aṣẹ lati funra wa lọ fofin gbe ‘Tani Ọlọhun’- Ẹgbẹ ogo Ilọrin

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nígbà tí BBC Yoruba kàn sí ẹgbẹ́ Ògo Ilorin tí wọ́n fi òfin gbé Talolorun, ààrẹ ẹgbẹ́ náà Alhaji Muritala Abdulkareem tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Baba'n'Bariga ní gbogbo ìgbésẹ̀ òfin tó yẹ láti gbé ni àwọn gbà láti fi mú Talolorun.

Alhaji Abdulkareem ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ti lọ fi ẹjọ́ Talolorun sùn ni àgọ́ ọlọ́pàá pé ó ń ba àwọn Alfa lórúkọ jẹ́.

Ó ṣàlàyé pé nígbà tí àwọn kò rí kí àwọn ọlọ́pàá rí Talolorun mú lásìkò, tí kò sì dẹ́kun láti máa ba awon lórúkọ jẹ́ ni àwọn tún fi tẹ̀síwájú láti wá ọ̀nà òfin mìíràn láti fi mú u.

Ó ní ìdí nìyí tí àwọn fi kọ̀wé ẹ̀sùn ránṣẹ́ sí ilé ẹjọ́ Májísíréètì ti ìlú Ilorin láti fún àwọn ní ìwé àṣẹ láti fòfin gbé Talolorun.

Ó fi kun pé ilé ẹjọ́ náà ló ṣe gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ láti lọ fòfin gbé Talolorun ní ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo.

"Lẹ́yìn tí wọ́n mú Talolorun tán ni wọ́n pè wá láti ilé ẹjọ́ pé ọwọ́ òfin ti tẹ̀ ẹ́."

Nígbà tó ń tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ Ààrẹ Ògo Ilorin náà ni ẹ̀sùn ìbanilórúkọ jẹ́ ni àwọn fi kan Talolorun.

Ó ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ fídíò ni Talolorun gbé jáde lórí ayélujára níbi tó ti ń tàbùkù àwọn Alfa ní Ilorin àti Ọba ìlú Ilorin.

Ó fi kun pé kìí ṣe nítorí ọdún Ìṣẹ̀ṣe tí wọ́n ti ṣáájú sọ pé àwọn fẹ́ ṣe ní Ilorin ni àwọn fi gbé bíkòṣe pé nítorí àwọn irọ́ tó ń pa mọ́ àwọn Alfa Ilorin.

Bi ẹnikẹni ba gbe eeyan lọ si ile ẹjọ laisi aṣẹ amofin agb ati imọsi awọn agbofinro, iwa to lodi si ofin patapata ni - Amofin

Lati lee tan imọlẹ si ọrọ naa daradara, BBC tun kan si agbẹjọro ajafẹtọ araalu kan, Amofin Oluwatoyin Ndidi Taiwo Ojo lati mọ ohun ti ofin sọ nipa ẹni gan an to laṣẹ lati fi ofin mu eniyan, tabi gbe eniyan lọ si ile ẹjọ paapaa lori ẹsun to jẹ mọ iwa ọdaran.

Amofin Taiwo Ojo ṣalaye pe nnakn eewọ labẹ ofin patapata ni igbesẹ ti awọn ẹgbẹ naa gbe nitori labẹ ofin ileeṣẹ ọlọpaa atawọn ileeṣẹ agbofinro nikan lo laṣẹ lati gbe eniyan lọ si ile ẹjọ.

O ni ki eeyan tabi ẹgbẹ lọ funrarẹ fi panpaẹ ofin gbe eeyan lọ si ile ẹjọ jẹ eyi to ṣe ajeji si ofin ati pe bi eeyan tabi ẹgbẹ ba tilẹ gbe igbesẹ yii, ileeṣẹ ọlọpaa to ba sun mọ wọn julọ lo yẹ ki wọn gbe e lọ, kii ṣe ile ẹjọ rara.

“Bi o tilẹ jẹ wi pe eeyan le fi panpẹ ofin gbe eeyan ṣugbọn ko si ẹtọ rẹ labẹ ofin fun ẹnikẹni lati funrarẹ gba iwe ofin ifisun ‘warrant of arrest’.

“Ko si ibi to wa labẹ ofin pe eeyan kan tabi ẹgbẹ le da gbe eeyan lọ si ile ẹjọ. Iru ẹni bẹẹ gbọdọ kọwe gba aṣẹ lati ọdọ amofin agba ipinlẹ naa.’

Amofin Taiwo Ojo ni, bi ọlọpaa ba wa n sọ pe awọn alfa lo gbe arakunrin naa lọ si ile ẹjọ, o jẹ ohun ti ko ba ofin mu rara.